Agbébọn yìnbọn pa alága Miyetti Allah Kwara níwájú ilé rẹ̀, ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí

Alhaji Idris Abubakar Sakaina táwọn agbébọn pa

Oríṣun àwòrán, Kwara Miyetti Allah

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kwara ní àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ikú alága ẹgbẹ́ Miyetti Allah Cattle Breeders Association of Nigeria, Alhaji Idris Abubakar Sakaina.

Ìròyìn ní nǹkan bíi aago mẹ́wàá alẹ́ ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kẹjọ, oṣù Kẹta, ọdún 2025 ni àwọn agbébọn kan lọ ka Abubakar, ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n mọ́ ilé rẹ̀ tó wà ní agbègbè, Oke Ose, Oke Oyi, ìpínlẹ̀ Kwara.

Wọ́n ní iwájú ilé Abubakar ni àwọn agbébọn náà tib a tí wọ́n sì yìnbọn pa lójú ẹsẹ̀ láì gba ohunkóhun lọ́wọ́ rẹ̀.

Àtẹ̀jáde tí agbẹnusọ ọlọ́pàá Kwara, Adetoun Ejire-Adeyemi fi léde lọ́jọ́ Àìkú fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀, tó sì sọ pé àwọn ọlọ́pàá bá ọta ìbọn márùn-ún níwájú ilé náà.

Ejire-Adeyemi fi kun pé àwọn ti gbé òkú Abubakar lọ sí ilé ìgbókùúpamọ́ sí ní ilé ìwòsàn olùkọ́ni UITH tó wà ní Oke Ose.

Ó ṣàlàyé pé ẹ̀ka tó máa ń ṣe ìwádìí ìwà ọ̀daràn, State Criminal Investigation Department, SCID ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Ó sọ àrídájú rẹ̀ pé iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ń ṣiṣẹ́ takuntakun láti nawọ́ gán àwọn afurasí tó ṣiṣẹ́ láabi náà.

Bákan náà ló rọ àwọn ará ìlú láti fi ara balẹ̀, kí wọ́n máa bá iṣẹ́ ojòjọ́ wọn, ẹnikẹ́ni tó bá sì ní ìmọ̀ nípa bí ọwọ́ ṣe lè tẹ àwọn afurasí náà láti lọ fi tó àwọn ọlọ́pàá létí.

Ṣáájú ni agbẹnusọ ẹgbẹ́ Miyetti Allah tẹ̀ka ìpínlẹ̀ Kwara, Abubakar Muhammad Kangodabe nínú àtẹ̀jáde kan tó buwọ́lu ní pẹ̀lú ìbànújẹ́ ọkàn ni àwọn fi kéde ikú Abubakar.

Ó ní ìyàwó méjì àti ọmọ mẹ́fà ni olóògbé náà fi sáyé, tó sì gbàdúrà kí Ọlọ́run tẹ sí afẹ́fẹ́ rere.

Ó sọ pé aago mẹ́wàá òwúrọ̀ ọjọ́ Àìkú ni ètò ìsìnkú rẹ̀ wáyé ní agbègbè Zango, ìlú Ilorin, olú ìlú ìpínlẹ̀ Kwara.

Muhammad gbàdúrà kí Ọlọ́run fún àwọn ẹbí ní ọkàn láti gba àdánù náà.