"Ẹbí fi mí yáwó nítorí àìsàn, ni mo ṣe di ẹrú lóko igbó''

Aworan Nam
Àkọlé àwòrán, Aworan Nam ti a jẹ ko dudu nitori aabo rẹ.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ko daju pe ọkunrin kan, Nam ( orukọ rẹ gan-an kọ niyẹn), ọmọ orilẹede Vietnam yoo le pada sile mọ loko ẹru to ti n singba l'orilẹede United Kingdom, nibi to ti n ṣe akọ iṣẹ loko igbo kan.

Nam funra rẹ ṣalaye pe, niṣe ni wọn dọgbọn gbe oun wọ UK ninu ọkọ akẹru, wọn si n fipa mu oun ṣiṣẹ loko ti wọn gbin igbo mimu si.

O ni oun ko ro pe oun le bọ loko isingba naa rara, bo tilẹ jẹ pe awọn pọ tawọn wa niru ipo yii loko igbo naa.

Njẹ ki lo de to fi dẹni to n singba loko igbo, to si tun ni ko daju pe oun yoo le pada sorilẹede abinibi oun mọ?

Nam sọ pe gbese ti ẹbi oun jẹ nipa owo yiya ti wọn ko le da pada lo fa a.

O fi kun un pe wakati mọkandinlogun ni oun n fi n ṣiṣẹ lojumọ loko igbo, wọn si maa n lu oun bii ẹni lu aṣọ ofi ni, oun ko si le sa lọ.

Kí ni ẹbí Nam torí ẹ yawo?

Ewe igbo

Ni Vietnam, ko fi bẹẹ si ileeṣẹ tabi awọn eeyan to jẹ olootọ to le ya ẹlomiran lowo, afi awọn ayani-lowo-èlé to gọbọi.

Awọn ayani-lowo-ele naa tun waa n ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ti wọn n gba ọna eru ko awọn eeyan wọ UK lati lọọ fi wọn ṣiṣẹ lile bi wọn ko ba ti ri owo ti wọn ya san.

Ohun to ṣẹlẹ si Nam ati aburo rẹ obinrin ree.

Gẹgẹ bi alaye , nigba ti baba Nam ni aarun jẹjẹrẹ ẹdọforo, awọn ẹbi rẹ ya owo tiye rẹ jẹ £186,564 lọwọ olowo-ele kan.

Owo naa ni wọn ko ri da pada to fi dohun ti Nam ati aburo rẹ di ẹni ti wọn sọ lókò si UK lati ṣiṣẹ ti wọn yoo fi san gbese pada.

Wọn kọkọ gbe Nam lọ si Russia pẹlu ayederu iwe irinna, wọn gbe e gba Europe.

Ni France, Nam ṣalaye pe awọn to gbe wọle fipa mu oun wọnu ọkọ kan ti inu rẹ jẹ firiiji, o ni o tutu buruku.

O ni wọn lawọn yoo pa oun ti oun ba kọ lati wọnu ọkọ naa.

Nam gunlẹ si UK lati Dover, wọn si fipa mu un lati maa ba awọn kan tun inu ile wọn ṣe lọfẹẹ, wọn ko sanwo fun un.

Ibi iṣẹ ile titunṣe naa lo wa ki wọn too taari ẹ si oko igbo mimu.

'Bí mo bá kú síbí, kò sẹ́ni tí yóò mọ̀'

Van
Àkọlé àwòrán, Aworan Van to kọ ẹyin sita
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ninu alaye Nam lo ti ni: "Mo le ku sibi ti ẹnikẹni ko ni i mọ."

" Mi o mọgba ti mo le bọ ninu ẹ rara ni."

Bo tilẹ jẹ pe awọn ọlọpaa pada ri Nam ti wọn si gbiyanju lati yọ ọ loko ẹru, idaamu to koju loko naa ati iriri buruku to ni nibẹ ti ṣakoba fun irisi rẹ, kinni naa ti sọ ọ di alarun ọpọlọ.

O fẹrẹ to ida kan ninu mẹta awọn eeyan 3, 602 to n gbe ni Vietnam ti wọn gunlẹ si UK pẹlu ọkọ oju omi kekere lọdun to kọja.

Ẹrú igbalode ni wọn n pe wọn pẹlu bi wọn ṣe n fi wọn kowo, ti wọn si tun n pọ si i.

Ijọba Vienam sọ pe oun ti n ṣapa gidi lati koju awọn to n gba ọna eru ko awọn eeyan lọ si UK lati fi singba naa.

Ẹlomii ti ọrọ rẹ tun fi ara jọ ti Nam ni ọkunrin kan ti a mọ si Van.

Van wọ UK lọna ẹtọ ni tiẹ gẹgẹ bii akẹkọọ ni, ṣugbọn o pada ba ara rẹ loko igbo, nibi to ti ṣiṣẹ aṣekara.

Nigba ti ọjọ to wa lori iwe irinna rẹ ti n sunmọ to si yẹ ko pada sile, awọn mọlẹbi rẹ sọ fun un pe ko ma wale rara o.

Wọn ni awọn ti jẹ gbese silẹ, Van si gbọdọ fi ọdun meji ṣiṣẹ ti gbese naa yoo fi jẹ sisan to ba wale.

"Awọn ti wọn jẹ lowo bẹrẹ si I halẹ mọ mi lati ile, wọn ni awọn ẹbi mi ko ni i ni alaafia ni Vietnam''

Awọn ọlọpaa ẹnu ibode lo pada mọ ohun to n ṣẹlẹ si Van, ti wọn si ri i pe awọn kan ti n ṣeto bi wọn yoo ṣe dọgbọn gbee wọ Ireland.

Ẹgbẹ ti a mọ si Salvation Army lo ṣaanu fun Nam ati Van, wọn darii wọn si eto ti wọn n pe ni "National Referral Mechanism", nibi ti wọn ti n ran awọn eeyan to ba ti ha siluu kan lọwọ ti wọn si n ṣiṣẹ bii ẹrú.

Awọn ajọ alaanu lo n ran wọn lọwọ bayii ni UK.

Ijọba gbọ́dọ̀ wá nǹkan ṣe sí ìṣoro yìí'

Dame Angela Eagle, onwoye lori owo ẹru igbalode yii, ṣalaye fun BBC pe ohun to n ṣẹlẹ naa ko ṣee dakẹ si.

O ni ijọba gbọdọ wa ojutuu si ọrọ awọn to n fipa ta awọn ẹni ẹlẹni si oko ẹru, ti wọn n fi wọn ṣe iṣẹẹ bọra.

Bakan naa ni awọn Salvation Army ṣalaye pe awujọ wa ni lati maa ṣakiyesi awọn apẹẹrẹ kan lara awọn arinrinajo ti wọn n wọnu ilu kan, to ṣee ṣe ko jẹ ẹru ni wọn waa fi wọn ṣe.

Awọn apẹẹrẹ bii kawọn oṣiṣẹ maa wo bii ẹni ti ẹru n ba, ki irisi wọn ma wu eeyan lati ri rara, ki wọn jọ ẹni ti ebi n pa ti ko si ni alaafia, tabi bi wọn ba ni ọgbẹ lara to yẹ ki wọn tọju.

Awọn apẹerẹ wọnyi wọpọ lara awọn to ba ko si isọro yii gẹgẹ bi wọn ṣe sọ.

Awọn apẹẹrẹ miran ko fi gbogbo ara han bi wọn ṣe wi, ṣugbọn o wa nibẹ.

Bii ki ẹnikan loun fẹẹ sanwo irinajo ẹni to fẹẹ lọọ ṣiṣẹ nilẹ okeere, bi ki wọn maa gba ẹnu rẹ sọrọ lai jẹ ki arinrinajo naa wi nnkan kan.

Bii ki wọn maa gbe wọn lọ sibi iṣẹ tabi lọọ gbe wọn pada sile lasiko ti ko yẹ, ati bii ki oṣiṣẹ ma mọ adirẹsi ile to n gbe.