Bó ṣe yẹ́ kí o máa kírun òru nínú Ramadan àti pàtàkì rẹ̀

Obinrin to n kirun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Bo tilẹ jẹ pe jiji kirun laarin oru wa lara ohun to yẹ ki Musulumi maa ṣe tẹlẹ ki Ramadan to o de, sibẹ, ẹkọ ẹsin Islam ni pe o tun ṣe pataki pupọ ninu oṣu Ramadan lati ji dide kirun laaarin oru.

Koda, ọrọ ẹnu Anabi Muhammed ti a mọ si Hadith, gba awọn Musulumi niyanju lati maa ji loru kirun, ki wọn beere ohun ti wọn ba n fẹ lọdọ Allah.

Irun oru naa pe oriṣiriṣi gẹgẹ bi ẹkọ ẹsin Islam ṣe la a kalẹ, o si bẹrẹ lati ori Tarawih ti a mọ si Aṣaamu ledee Yoruba, eyi ti wọn sabaa maa n ki lọwọ alẹ ni mọṣalaaṣi.

Oríṣi ìrun òru

Sheikh Murtadha Muhammad Gusau, Imaamu agba fun mọṣalaaṣi apapọ Okene, nipinlẹ Kogi, ṣalaye pe oriṣiriṣi irun oru lo wa tawọn eeyan n ki lasiko aawẹ Ramadan ati lẹyin aawẹ pẹlu.

Awọn irun naa ki i ṣe dandan bii irun wakati marun-un ti awọn Musulumi maa n ki lojumọ bi Imaamu Gusau ṣe wi.

O ni ṣugbọn wọn dara pupọ nitori adipele ẹsan oore to kun inu rẹ fọfọ.

Akọkọ ninu awọn irun oru naa ni:

Tarawih – (Áṣáámu) Imaamu Gusau ṣalaye pe irun Tarawih ti wọn n ki lalẹ ni mọṣalaaṣi ko yatọ si eyi ti wọn n ji ki laaarin oru lasiko aawẹ Ramadan.

"Orukọ ti a n pe awọn irun yii ni 'Qiyamullaili', to tumọ si pe ki eeyan dide kirun loru.

''Tahajjud tabi Tarawih abi Qiyam Ramadan, irun kan naa ni gbogbo wọn, wọn ko yatọ rara."

O ni orukọ awọn irun naa lo yatọ ati asiko ti eeyan ba ki wọn

Oore tó ń bẹ nínú jíjí kírun lóru

Aworan awọn ọkunrin to n kirun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọrọ Anabi Muhammad ni pe: "Bi ẹnikẹni ba ji kirun loru ninu oṣu Ramadan, pẹlu igbagbọ ati ireti aanu lati ọdọ Allah, gbogbo ẹṣẹ to ti ṣẹ tẹlẹ yoo di idariji. [Bukhari]

'' Ẹnikẹni to ba kirun oru pẹlu gbigba Ọlọun ni ọkan ṣoṣo titi to fi kirun naa tan, o da bii ẹni to fi gbogbo oru naa kirun lai sun rara ni''

Imam Tirmidhi ni wọn lo ni oun gbọ ọrọ yii lati ẹnu Abu Dharr, ẹni to ni Ojiṣẹ Allah.

Imaamu Gusau sọ pe ki eeyan ji kirun, ṣe adua nigba ti awọn eeyan mi-in n sun loru Ramadan ṣe pataki pupọ, o looore nla fun Musulumi .

" Irun oru jẹ ijọsin ti awọn onigbagbọ ododo ninu ẹsin Islam maa n ṣe lati fi wa aanu, iyọnu ati isunmọ Allah. Ki i ṣe irun ọ̀ranyàn, to ba wu eeyan ni, ṣugbọn o daa ju nitori o maa n muni sun mọ Allah."

Imaamu Gusau lo ṣalaye bẹẹ .

Báwo ni wọ́n ṣe ń kírun òru?

Aworan awọn ọkunrin to tẹwọ adua

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Nigba to n ṣalaye nipa ilana irun kiki laaarin oru, Sheikh Murtadha Gusau, sọ pe, "Anọbi maa n ki irun ti a mọ si raka mọkanla, lasiko aawẹ Ramadan ati lẹyin rẹ"

Ṣugbọn bi eeyan ba le ki ju bẹẹ lọ, ko buru. Bi eeyan ko ba si le ki to bẹẹ, ki i ṣe ẹṣẹ.

Imaamu ṣalaye pe ẹnikan beere lọwọ Anabi nipa irun oru yii, o si da a lohun pe:

" Meji ni opo irun oru (rakah), ṣugbọn bi eeyan ba ri i pe irun aarọ ti i ṣe Asubah ti n wọle bọ, ki eeyan ki raka kan, a o si ka a si irun olopo kan, (witr) fun un, ni afikun pẹlu awọn irun to ti ki tẹlẹ." [Bukhari]

"Fun idi eyi, ko ruju rara pe eeyan ki mọkanla tabi meji, tabi pe eeyan ki ju bẹẹ lọ." Sheikh Gusau lo ṣalaye bẹẹ.

Asiko wo leeyan n ki irun oru?

Sheikh Murtadha Muhammad Gusau, ṣalaye pe awọn irun oru ti bẹrẹ latigba ti wọn ba ti kirun ọranyan ti i ṣe Ishai tan lalẹ.

O ni eeyan le yan Nafila yii latigba naa titi di ìdájí aarọ ọjọ keji.

"Ohun to ṣe pataki fun ẹru Ọlọun to fẹẹ kirun oru ni otitọ inu, ko kirun naa nitori Ọba Allah, ko yago fun ka-ri-mi ati abosi, ko si yago fun ṣiṣe nnkan nitori eeyan, ko tori Ọlọun ṣe e.''

Bakan naa ni Ọjọgbọn Mansur Isa Yelwa, ṣalaye pe eeyan le kirun naa ninu ile rẹ, o si le lọ si mọṣalaṣi lati ki i.

O ni ṣugbọn eyi ti eeyan ki ni mọṣalaṣi lo daa ju, to si ni laada julọ.