Kìí ṣe nítorí ẹ̀sùn ìbálòpọ̀ ni a ṣe ní kí Natasha lọ rọ́kún nílé, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ márùn-ún tó ṣẹ̀ nìyí - Ilé aṣòfin

Oríṣun àwòrán, @Natasha H Akpoti/Facebook
Ilé aṣòfin àgbà Nàìjíríà ti ṣàlàyé ìdí tí wọ́n fi ní kí aṣòfin Natasha Akpoti-Uduaghan lọ rọ́kún nílé fún oṣù mẹ́fà láì ní gba owó oṣù.
Àtẹ̀jáde kan tí Sẹ́nétọ̀ Opeyemi Bamidele fi léde lọ́jọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kẹjọ, oṣù Kẹta, ọdún 2025 sọ pé, lòdì sí ìròyìn táwọn iléeṣẹ́ ìròyìn kan ń gbé pé nítorí ẹ̀sùn ìbálòpọ̀ tí Natasha fi kan ààrẹ ilé aṣòfin náà, ní bẹ́ẹ̀ kọ́ ni ọ̀rọ̀ rí.
Bamidele nínú àtẹ̀jáde náà sọ pé àwọn ìwà àìtọ́ tí Natasha hù sílé aṣòfin ló fa ìjìyà tí ilé aṣòfin fún un.
Ó ní àpapọ̀ ilé aṣòfin ló fẹnukò lórí àwọn ìjìyà náà lẹ́yìn tí ìgbìmọ̀ tó ń rí sí ìwà gbé àwọn àbá wọn kalẹ̀ lórí ìwádìí tí wọ́n ṣe.
Ó sọ pé ìgbìmọ̀ náà ṣàwárí rẹ̀ pé Natasha jẹ̀bi títàpá sí òfin ilé aṣòfin èyí tí ìjìyà wà fún lábẹ́ òfin.
Àwọn ẹ̀sùn márùn-ún tí ilé aṣòfin ní Natasha jẹ̀bi rẹ̀ tí wọ́n fi ní kó ló rọ́kún nílé nìyí:
- Natasha kọ̀ láti jòkòó sí ààyè tí ilé pèsè fún-un: Níbi ìjòkòó ilé tó wáyé lọ́jọ́ Karùndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kejì, ọdún 2025, ilé aṣòfin ní Natasha kọ̀ láti jòkòó sí ààyè tí ilé pèsè fun kódà lẹ́yìn olórí ọmọ ilé tó kéré jùlọ bẹ̀ ẹ́ láti jòkòó síbẹ̀.
- Ó sọ̀rọ̀ nígbà tí wọn kò ì tíì fun láṣẹ: Ilé aṣòfin fẹ̀sùn kan Natasha pé ó dìde láti sọ̀rọ̀ nígbà tí ẹni tó ń darí ilé kò ì tíì fun láṣẹ láti ṣe bẹ́ẹ̀ èyí tí wọ́n ní ó lòdì sí òfin ilé aṣòfin.
- Ó da ètò ìjòkòó ilé rù: Ilé aṣòfin tún fẹ̀sùn kan Natasha pé ó fa wàhálà lásìkò tí ìjíròrò ilé ń lọ lọ́wọ́, tí kò sí jẹ́ kí ìjíròrò lọ ní ìrówọ́rọsẹ̀.
- Ó bu ẹnu àtẹ́ lu àwọn olórí ilé aṣòfin: Ẹ̀sùn mìíràn tí ilé aṣòfin fi ní àwọn ní kí Natasha lọ rọ́kún nílé kò ṣẹ̀yìn bí ó ṣe hùwà àìlójútì sáwọn olórí ilé aṣòfin.
- Ó kọ̀ láti jẹ́ ìpè ìgbìmọ̀ tó ń rí ìwà ọmọlúàbí: Ilé aṣòfin sọ pé àwọn ránṣẹ́ pe Natasha láti wá wí tẹnu rẹ̀ lórí àwọn ẹ̀sùn yìí àmọ́ ó kọ̀ láti yọjú sí ìgbìmọ̀ náà.
Ilé aṣòfin tẹmpẹlẹmọ pé nítorí àwọn ìwà àìtọ́ Natasha yìí ni ilé ṣe ní kó lọ rọ́kún nílé àti pé kò ní nǹkan ṣe pẹ̀lú ẹ̀sùn tó fi kan ààrẹ ilé aṣòfin.
Wọ́n ní ó pọn dandan láti gbé ìgbésẹ̀ fífi ìjìyà tó tọ́ jẹ ẹ́ nítorí àti rip é àwọn mìíràn kò ma tẹ ẹ̀tọ́ ilé aṣòfin lójú mọ́lẹ́ lọ́jọ́ iwájú.
"Àwọn ìwà Natasha lòdì sí òfin ilé aṣòfin tọdún 2023 èyí tó ń ṣe atọ́nà ìlànà àti ìṣe ilé aṣòfin àgbà àtàwọn aṣòfin àti òṣìṣẹ́ ibẹ̀."
Sẹ́nétọ̀ Bamidele wá ṣèkìlọ̀ fáwọn iléeṣẹ́ ìròyìn láti yé gbé ìròyìn òfégè pé nítorí ẹ̀sùn ìbálòpọ̀ ni ilé aṣòfin fi ní kí Natasha lọ rọ́kún nílé.
Wo ìjìyà mẹ́fà tí ilé aṣòfin àgbà wé mọ́ Natasha lọ́rùn, tí wọn fi ní kó lọ rọ́kún nílé fún oṣù mẹ́fà

Oríṣun àwòrán, Natasha Akpoti-Uduaghan/Facebook
Ṣáájú ni Ilé aṣòfin àgbà ìlú Abuja ti ní kí aṣòfin Natasha Akpoti-Uduaghan, tó fẹ̀sùn kan ààrẹ ilé aṣòfin, Godswill Akpabio fáwọn ẹ̀sùn aṣemáṣe tó fi mọ́ nínawọ́ ìbálòpọ̀ sí òun lọ́nà àìtọ́, láti rọ́kún nílé fún oṣù mẹ́fà.
Ní ọjọ́rú, ọjọ́ Karùn-ún, oṣù Kẹta, ọdún 2025 ni ìgbìmọ̀ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ìwà ní ilé aṣòfin àgbà ṣàgbéyẹ̀wò ìwé ẹ̀sùn tí Natasha tẹ́ pẹpẹ síwájú ilé náà lórí àwọn ẹ̀sùn tó fi kan Akpabio.
Níbi ìgbẹ́jọ́ náà láwọn aṣòfin náà ti da ẹ̀sùn tí Natasha pè nù bí wọ́n ṣe ní ó kọ̀ láti tẹ̀lé àti òfin ilé aṣòfin tó rọ̀ mọ́ gbígbé ìwé ẹ̀sùn kalẹ̀.
Ní ọjọ́bọ̀ ni ìgbìmọ̀ náà wá gbé àbọ̀ ìwádìí wọn kalẹ̀ níbi ìjókòó ilé tí wọ́n sì ka gbogbo ìjábọ̀ àti ìpinnu ìgbìmọ̀ náà lórí àwọn ẹ̀sùn tí Natasha gbé síwájú wọn.
Alága ìgbìmọ̀ náà, Sẹ́nétọ̀ Neda Imasuen nígbà tó ń ka ìjábọ̀ ìgbìmọ̀ náà sí etígbọ̀ọ́ ilé sọ pé àwọn pinnu láti ní kí Natasha lọ rọ́kún nílé fún oṣù mẹ́fà.
Imasuen ní Natasha kọ̀ láti tẹ̀lé òfin ilé aṣòfin "Senate Standing Rules" ọdún 2023 èyí tó fi dójú ti ààrẹ ilé aṣòfin àti ilé aṣòfin lápapọ̀.
Alága náà sọ pé ohun tó lè mú àwọn mú àdínkù bá ìjìyà rírọ́kún nílé fún oṣù mẹ́fà tí wọ́n fún Natasha ni tí Natasha bá tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ilé aṣòfin fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó ṣẹ̀ nípa kíkọ ìwé sílé láti tọrọ àforíjì.
Bákan náà ni wọ́n ní kí wọ́n ti ọ́fíìsì rẹ̀ pa fún gbogbo oṣù mẹ́fà tí yóò fi wà nílé náà.
Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n sọ pé kò ní owó àti àwọn àjẹmọ́nú tó wà fún òun àti àwọn òṣìṣẹ́ tó wà lábẹ́ rẹ̀ fún oṣù mẹ́fà náà.
Ilé aṣòfin àgbà náà sọ pé ó ṣeéṣe kí ilé aṣòfin bu ojú àánu wo Natasha tó bá kọ ìwé àforíjì sí ilé kí oṣù mẹ́fà náà tó pé.
Lẹ́yìn ìjíròrò lọ́kan-ò-jọ̀kan, Ààrẹ ilé aṣòfin àgbà, Godswill Akpabio kéde pé kí Natasha lọ rọ́kún nílé fún oṣù mẹ́fà lẹ́yìn tí ọ̀pọ̀ àwọn aṣòfin faramọ́ ìpinnu náà.
Àwọn ìjìyà tí ilé aṣòfin fún Natasha
- Kó wà ní ìgbélé oṣù mẹ́fà
- Kí ọ́fíìsì rẹ̀ wà ní títipà fún oṣù mẹ́fà
- Wọ́n kò ní san owó oṣù fún Natasha fún oṣù mẹ́fà tó fi máa wà ní ìgbélé
- Kí wọ́n kó àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò kúrò lẹ́yìn rẹ̀ fún oṣù mẹ́fà
- Kò gbọdọ̀ súnmọ́ ilé aṣòfin fún oṣù mẹ́fà tó fi máa wà ní ìgbélé
- Ó gbọdọ̀ kọ̀wé láti fi tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ilé aṣòfin kó tó wọlé.
Kí ló fa gbas gbos láàárín Natasha àti Akpabio?
Ní ogúnjọ́ oṣù Kejì, ọdún 2025 ni gbas gbos láàárín Natasha Akpoti-Uduaghan àti ààrẹ ilé aṣòfin àgbà, Godswill Akpabio nígbà tí Natasha fa ìbínú yọ pé wọ́n mú àyípadà bá ibi tí òun ń jókòó sí láì sọ fún òun.
Ó fi ìbínú sọ̀rọ̀ débi wí pé, Akpabio sọ fún àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò láti sin Natasha jade kúrò ní ilé aṣòfin lọ́jọ́ náà àmọ́ táwọn aṣ]ofin mìíràn dá sí ọ̀rọ̀ náà.
Lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni Natasha kópa níbi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ kan pẹ̀lú iléeṣẹ́ ìròyìn Arise TV níbi tó ti fẹ̀sùn kàn pé Akpabio fẹ́ ṣe aṣemáṣe pẹ̀lú òun.
Ó ní nítorí òun kò gbà láti bá Akpabio ṣe aṣemáṣe náà ló ṣe ń dúnkokò mọ́ òun tó sì ń kọdí gbogbo nǹkan tí òun bá fẹ́ ṣe nílé aṣòfin.
Akpabio jiyàn àwọn ẹ̀sùn Natasha yìí, tí ìyàwó rẹ̀, Ekaette Akpabio náà sì wọ́ Natasha lọ sílé ẹjọ́ pé ó fẹ́ ba òun lórúkọ jẹ́.
Ẹ̀wẹ̀, ọkọ Natasha náà, Emmanuel Uduaghan náà ní òun wà lẹ́yìn ìyàwó òun lórí àwọn ẹ̀sùn tó fi kan Akpabio.















