Mo jẹ́rìí aya mi lórí ẹ̀sùn tó fi kan Akpabio, mo ti rọ̀ ọ́ tẹ́lẹ̀ pé kó fi aya mi lọ́rún silẹ̀ - ọkọ Natasha

Oríṣun àwòrán, Others
Ọkọ Sẹnẹtọ Natasha Akpoti-Uduaghan to n soju ẹkun idibo aarin gbungbun ipinlẹ Kogi, Emmanuel Uduaghan, ti sọrọ lori ẹsun iyọlẹnu fun ibalopọ ti iyawo rẹ fi kan aarẹ ile igbimọ aṣofin agba l'Abuja, Godswill Akpabio.
Ninu atẹjade kan ti Uduaghan, to jẹ gbajumọ Oloye niluu Warri fi sita lo ti sọ pe oun ko fẹ da si ọrọ naa tẹlẹ ṣugbọn awọn nnkan to n jade lori rẹ, lo jẹ ki oun tẹnu bọ ọrọ.
Uduaghan ni iyawo oun ti n sọ fun oun tẹlẹ nipa aarẹ ile igbimọ aṣofin, ẹni to ni oun ri gẹgẹ bii ọrẹ si idile oun, ti oun si ṣepade pẹlu rẹ lori ọrọ naa.
O ni oun wa lẹyin iyawo oun digbi lori ẹsun to fi kan Akpabio.
"Pẹlu apọnle ni mo fi lọ ba aarẹ ile igbimọ aṣofin, ti mo si ni ko fun iyawo mi ni apọnle to tọ si i bakan naa.
Bayii a ṣe fẹnu ko gẹgẹ bi ọrẹ si ọrẹ, ti a si yanju ọrọ naa.
"Amọ, pẹlu bi a ṣe ti fẹnu ko yii, iyawo mi si n sọ fun mi pe Akpabio ko dawọ iwa yiyọ oun lẹnu fun ibalopọ duro,'' Uduaghan lo sọ bẹẹ.
Uduaghan wa rọ ile igbimọ aṣofin agba l'Abuja ati Sẹnẹtọ Akpabio lati fun Natasha ni ọwọ ati apọnle to tọ si i.

Oríṣun àwòrán, Natasha Akpoti-Uduaghan
Kí gan-an ló fa gbas-gbos láàárín Akpabio àti Natasha?
Ibeere kan ti ọpọ ọmọ Naijiria n bere ree lọwọ awọn aṣofin orilẹede Naijiria.
Ni ọsẹ to kọja ni wahala sẹlẹ laarin Aarẹ ile igbimọ aṣofin, Godswill Akpabio ati amofin to n ṣoju ẹku idibo aarin gbogbo ipinlẹ Kogi, Natasha Uduaghan.
Lasiko ti ile n jokoo ni Akpabio paṣẹ pe ki awọn agbofinro mu Natasha jade kuro ijokoo aṣofin.
Gẹgẹ bii ileeṣẹ iroyin abẹle AIT se ti salaye, wahala naa bẹ silẹ nigba ti akapo ile, Mohammed Monguno ṣo fun ile pe Aṣofin Natasha Uduaghan kọ lati lọ jokoo si aye tuntun ti wọn yan fun.
Sẹnetọ Natasha kọ jalẹ pe oun ko le kuro ni aye to wa tẹlẹ, to si fẹsun kan aarẹ ile igbimọ aṣofin ati ile igbimọ pe wọn tẹ ẹtọ mọlẹ. Eyi lo fa ti Akpabio fi ni ki wọn gbe Natasha kuro ni ile aṣofin.
"N ko bẹru ẹ." Natasha sọ fun Akpabio. "Se ohun to ba fẹ ṣugbọn n ki kuro ni aye mi rara. O le pa ohun mi mọ."
Lẹyin ọjọ naa ni Sẹnetọ Natasha gbe olori ile, Godswill Akpabio ati Mfon Patrick lọ ile ẹjọ fun ẹsun ibanilorukọ jẹ.
Agbẹjọro rẹ, Victor Giwa sọ pe Patrick kọ nnkan soju opo Facebook rẹ to tabuku si Sẹnetọ Natasha.
Ni ọjọ kejidinlọgbọn oṣu keji, ọrọ naa ba ibo miiran yọ nigba ti Amofin Natasha bọ sori tẹlifisan Arise, to si fẹsun kan Akpabio pe o fẹ ba oun ni ajọsepọ, ti oun ko si gba lati se bẹ
O ni eyi lo fa ti olori ile fi fẹ fi aye su ni ile igbimọ aṣofin.
Ẹsun yii lo fa gbas gbos bayii.
Iyawo Akpabio wọ Natasha lọ ile ẹjọ

Oríṣun àwòrán, Natasha Akpoti Uduaghan/Instagram, Godswill Akpabio/Facebook
Unoma Akpabio, iyawo aarẹ olori ile igbimọ aṣofin ni ẹsun ti Natasha fi kan ọkọ ni bojumu rara, to si jẹ ibanilorukọ jẹ.
Iwe ẹjọ naa ni ki Ṣenetọ Natasha san owo toto N250 bilọnu naira owo ibanilorukọ ati bilọnu kan naira mii fun ẹsun naa.
Iwe ẹjọ naa lo ti wa niwaju ile ẹjọ giga to n jokoo niluu Abuja.
Nigba ti iyawo Akpabio n ba awọn akọroyin sọrọ, o ni irọ ni Natasha n pa mọ ọkọ oun, to si n gbe awọn igbesẹ yii nitori ifẹ inu ọkan.
Ile ẹjọ ko ti mu ọjọ fun igbejọ naa.















