Bí o ṣe lè mọ àsìkò Sààrì àti ìṣínu nínú ààwẹ̀ Ramadan

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Asiko saari ni idaji ati iṣinu nigba ti oorun ba rọ ṣe pataki ninu awẹ Ramadan.
Idi ni pe ko ni si jijẹ mimu lati asiko saari ni idaji titi di irọlẹ to jẹ asiko iṣinu awẹ.
Amọ, ọpọ eeyan lo n maa n nira fun lati mọ asiko to tọ lati jẹ saari lati ṣinu awẹ.
Eyi lo jẹ ka beere lọwọ awọn oninmọ nipa ẹsin musulumi lati ṣalaye ohun ti ẹsin sọ nipa awọn akoko yii.
Bi o ṣe le mọ asiko saari

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Salihu Muhammad Yakub, olukọni ni ile ẹjọ giga Fasiti ABU ni Zaria to tun jẹ ọkan alara ọmọ ẹgbẹ igbimọ to n maa wa oṣupa ni Naijiria eyi ti Sultan Sokoto n dari rẹ sọ pe o ṣoro diẹ lati mọ akoko saari papaa julọ fawọn olugbe ilu nla nitori awọn ile giga to pọ kaakiri.
Onimọ nipa ẹṣin Islam, Sheikh Salihu Yakub, ṣalaye pe ohun ti igbimọ to maa n wa oṣupa maa n ṣe ni pe wọn maa n lọ sawọn ilu ti ko si ile giga ti igi ko si pọ nibẹ lati mọ akoko saari ni idaji.
O sọ pe idaji ni ila tẹẹrẹ to maa n wa loju sanmọ nigba ti oorun ba sẹsẹ yọ.
Sheikh ni eeyan ti maa ri ila naa to han lati ariwa lọ si guusu.
Bi o ṣe le mọ asiko iṣinu awẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Sheikh Yakub to jẹ Ọjọgbọn ni ile ẹkọ giga fasiti sọ pe o rọrun lati mọ asiko iṣinu ju asiko saari lọ.
"Eeyan maa n ri ami loju ọrun ti oorun ba ti wọ ayafi to ba jẹ asiko ojo nikan loku.
Ti eeyan ko ba ti ri oorun mọ, ọjọ ti rọ nìyẹn, idi niyii ti kii saba fi nira fawọn to ba n gba awẹ lati mọ igba ti wọn ba fẹ ṣinu.
Ẹnikẹni to n gba awẹ gan an ko nilo ki wọn ṣẹṣẹ sọ fun ki o to mọ pe asiko iṣinu ti to.















