Ọwọ́ iléeṣẹ ọlọ́pàá tẹ bàbá tó gbá ọmọ rẹ̀ ní ìpá ni Ogun

Aworan lati ibi iṣẹlẹ naa

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ọwọ Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti tẹ Odukaye Kunle, ọkunrin kan ti wọn fẹsun kan pe o gba ọmọ rẹ, Boluwatife ni gbakugba ni agbegbe Otta nipinlẹ Ogun.

Kunle ni ọwọ tẹ lẹyin ti fonran kan lu sita lori ayelujara bi Kunle se n lu ọmọ rẹ, to si tun gba ni ipa, eyi to mu ki ọpọ eeyan lori ayelujara kesi ileeṣẹ ọlọpaa.

Ikede yii lo jade loju opo ayelujara agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa, Olumuyiwa Adejobi lọjọ Ṣatide.

Gẹgẹ bii ileeṣẹ ọlọpaa se sọ, Kunle ti wa ni ahamọ ọlọpaa bayii, ti yoo si foju ba ile ẹjọ lọjọ Aje.

Ẹwẹ, iya ọmọ ati ọmọ ni wọn ti gbe lọ si ile iwosan ileeṣẹ ọlọpaa niluu Ota fun itọju.

"Lori ọmọ ti baba rẹ gba ni igbakugba nipinlẹ Ogun, Odukaye Kunle, baba ọmọ to lu ọmọ rẹ, Boluwatife ni Otta ni ọwọ ọlọpaa ti tẹ.

"Iya ọmọ ati ọmọ dekunrin naa ti wa ni ile iwosan wa ni Otta fun itọju.

"Kunle yoo foju ba ile ẹjọ lọjọ Aje. A kan sanra si ọga agba fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, CP Lanre Ogunlowo ati awọn ikọ rẹ fun iṣẹ takuntakun ti wọn lati ri pe ọmọ naa ri idajọ ododo gba ."

Nibi ọjọ melo diẹ sẹyin ni Adelere Rasaki, eeyan kan lori ayelujara Facebook gbe fọnran bi Baba naa se n gba ọmọ ni gbakugba sita loju opo Facebook.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post