Lẹ́yìn ìwádìí BBC, NAFDAC fòfin de àwọn òògùn iléeṣẹ̀ Aveo tí wọ́n ń tà ní Naijiria

Aworan oogun oloro

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ajọ to n mojuto lilo ati tita oogun ati ounjẹ ni NAFDAC ti fofin de ileese kan to n pese oogun lorilẹede India, Aveo Pharmaceuticals, ti Vinod Sharma lọwọ ninu sise,tita ati gbigbe ọpọ oogun oloro to ni eroja Tapentadol ati Carisoprodol wọ orilẹede Naijiria, Ghana ati Cote D'Ivorie.

Laipẹ yii iwadii BBC ṣafihan bi ileeṣẹ yii se n ko awọn oogun wọn ilẹ Afrika, ti wọn si n ta ọpọ wọn ni oju titi ni orilẹede Naijiria, Ghana ati Cote D'Ivoire .

Ileeṣẹ yii kan naa lo lọwọ ninu sise oogun oloro Tramdol ti wọn n kọ ilẹ Afrika, eyi ti NAFDAC ni o ṣe akoba fun ọpọ awọn ọdọ lawujọ paapa ni Naijiria

Ninu atẹjade kan ti alaga Ajọ NAFDAC, Ọjọgbọn Mojisola Adeyeye ni NAFDAC ko fi igba kankan se akọsilẹ tabi ifọrọkọsilẹ fun oogun Tafrodol tabi Royal 225 tabi Tramadol gan .

Bakan naa ni NAFDAC ni awọn ti n gbe igbesẹ lati ma jẹ ki eyikeyi oogun to ba wa lati ileeṣẹ naa wọ orilẹede Naijiria fun lilo

"A rọ awọn araalu lati fọwọsowọpọ pẹlu wa lati gbe ogun ti awọn ayederu oogun to n tọwọ awọn ileeṣẹ ayederu yii wa.

"Bakan naa ni a tun rọ awọn araalu pe ki wọn yago fun awọn oogun ti ko ni nọmba danimọ NAFDAC ko wa fun lilo.

"Eyi ni lati fi da gbogbo araalu loju pe NAFDAC yoo tunbọ tẹsiwaju lati ma lo gbogbo ọna lati ri pe oogun ti a n lo jẹ ohun to dara fun lilo ilera wa.

Apapọ awọn oogun ni ko si ibikibi lagbaye ti wọn ti fọwọ si, ti ajọ NAFDAC si pẹlu, oogun yii le mu fa ai le mi ti aloju si le ṣekupa eeyan.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Ki lo wa ninu iwadii BBC?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Iṣẹ iwadii BBC ti tu aṣiri bi ileeṣẹ apoogun orilẹede India kan ṣe n ko oogun oloro Opioid wọ ẹkun iwọ oorun ilẹ Afirika eleyii to m ṣakoba eto ilera araa;u.

Ileeṣẹ apoogun Aveo to wa niluu Mumbai n ṣe oogun yii pẹlu oniruuru orukọ eyi to jẹ ko dabi oogun gidi.

Ṣugbọn oriṣiiriṣii eroja oloro bii ''tapentadol, opioid to lagbara ati carisoprodol ni wọn dapọ to wa ninu oogun yii.

Ko si orilẹede ti wọn ti faye gba tita oogun yii fun araalu, koda, o maa n ṣokunfa ki eeyan ma lee mi daadaa ati giri.

Koda, apọju oogun naa ninu ara le ṣeku pa eeyan.

Bo tilẹ jẹ pe ewu pọ ninu oogun yii, o wa kaakiri ori igba lawọn orilẹede iwọ oorun ilẹ Afirika tori owo rẹ ko gani lara.

Ninu iṣẹ iwadii ti BBC ṣe ni wọn ti ri paali oogun naa pẹlu ami ileeṣẹ apoogun Aveo fun tita ni Naijiria, Ghana ati Cote D'Ivoire.

Ẹwẹ, akọroyin BBC kan lọ si ileeṣẹ ipoogun Aveo lorilẹede India ti o si ṣe bii oniṣowo to fẹ ko oogun Opioid lọ si Naijiria.

Bayii ni akọroyin naa ti ẹrọ kamẹra wa lara rẹ ba awọn ọga agba ileeṣẹ apoogun Aveo pade ti o si ṣafihan oogun oloro yii kan naa to n ṣakoba fun ilera araalu ni iwọ oorun ilẹ Afirika.

Ninu fidio ti BBC fi ọgbọn ka silẹ ni wọn ti sọ fun Sharma pe erongba awọn ni lati ta oogun fawọn ọdọ ni Naijiria tori wọn fẹran oogun naa.