'Ìyàwó mi ń bẹ̀rù ìbálòpọ̀, èmi ń bẹ̀rù ikú, ó sì ṣeéṣe kí ilé mi dàrú'

Tọkọ-taya to joko papọ

Oríṣun àwòrán, MudiOdibo

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ayipada ti ba igbe-aye Mike ElvisTusubira, ẹni to ni aarun HIV lorilẹede Uganda, lati igba ti Aarẹ Donald Trump ti kede idaduro iranwọ fawọn to larun naa nipasẹ ajọ USAID.

Kii ṣe nitori ara rẹ nikan lẹru fi n ba Mike, ẹni ọdun marundinlogoji to n ṣiṣẹ ọkada wiwa, bi ko ṣe pe o ni lati yapa pẹlu iyawo rẹ nitori wọn ko ni le jọ ni ibalopọ mọ ti iyawo rẹ ko fi ni ko aarun HIV.

Iyawo Mike ko larun HIV, ṣugbọn o maa n loogun kan ti wọn n pe orukọ rẹ PrEP ti ko ni jẹ ki aarun naa ran an.

Aworan Mike Elvis Tusubira

Oríṣun àwòrán, Mike Elvis Tusubvira

Mike sọ fun BBC pe igbeyawo oun yoo tuka nitori pe iyawo oun ko ni duro mọ lai ri oogun to n daabo bo lọwọ aarun HIV.

"Eyi tumọ si pe igbeyawo mi yoo tuka nitori ko si rọba idaabobo mọ, ko si oogun PrEP ti iyawo mi le lo ti ko ni jẹ ko ko aarun HIV.

Ko si ṣee ṣe ki a wa papọ gẹgẹ bii lọkọ-laya lai ni ibalopọ, mo maa di apọn pada ni bayii," Mike lo sọ bẹẹ.

Gbogbo oogun ti Mike ati iyawo rẹ n lo ni ajọ USAID ti ijọba Amẹrika n ṣe onigbọwọ rẹ maa n pese lọfẹẹ tẹlẹ ki Trump to paṣẹ idaduro iranwọ naa l'oṣu to kọja.

Lati igba naa l'awọn mejeeji ko tii ri oogun ti wọn n lo mọ, ẹru si n bawọn lati maa lo rọba idaabobo lasan fun ibalopọ nitori pe, o le ja.

Trump paṣẹ idaduro gbogbo iranwọ ti Amerika n ṣe silẹ okeere fun oṣu mẹta

Kete ti Trump bẹrẹ iṣejọba rẹ fun saa keji, lo paṣẹ idaduro gbogbo iranwọ ti orilẹede Amẹrika n ṣe silẹ okeere fún oṣu mẹta na.

Ogbeni Mike to ti bi ọmọ kan pẹlu iyawo rẹ ko tii l'anfaani lati ṣe ayẹwo lati mọ bi kokoro HIV ṣe ti gbilẹ si ninu ara rẹ.

O ni ṣe lo dabi eni pe oun n rin ninu okunkun nitori pe oun ko mọ iru akoba ti aarun naa ti ṣe ninu agọ ara oun.

Mike ko ni igbagbọ pe isẹ ọkada wiwa ti wọn n pe ni "boda-boda" to lati fi maa ra awọn oogun ti ẹbi rẹ nilo.

Idaduro iranwọ fun ajo USAID tun ti ṣakoba fawọn ajọ ti kii ṣe ti ijọba naa.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Idaduro iranwọ orilẹede Amẹrika fun ajo USAID tun ti ṣakoba fawọn ajọ ti kii ṣe ti ijọba naa.

Iyawo Mike n ri oogun PrEP gba nipasẹ ajọ ti kii ṣe ti ijọba kan tẹlẹ ni Marpi, nigba ti ọmọkunrin rẹ naa n jẹ anfaani ẹkọ ọfẹ ati ounjẹ nipasẹ ajọ naa.

Ni bayii, ọmọ wọn ko le lọ ile-ẹkọ mọ.

Irufẹ owo iranwọ yii ni ẹka eto ilera orilẹede Uganda fi n gbera.

Uganda wa lara awọn orilẹede mẹwaa to janfaani owo iranwọ nipasẹ ajọ USAID julọ ni Afirika.

Akọsilẹ ijọba Amẹrika fi han pe, Uganda ri $295m iranwọ owo gba lati ọdọ ajọ USAID ni ẹka eto ilera lọdun 2023.

Uganda lo se ipo kẹta lẹyin Tanzania to ṣe ipo keji pẹlu $337m nigba ti Naijiria jẹ orilẹede Afirika to gbowo iranwọ to pọ julọ lọdun naa pẹlu $368m.

Eeyan to to 630,000 ni aarun AIDS ṣokunfa iku wọn lọdun 2023, nigba ti miliọnu meji abọ eeyan mii ṣẹṣẹ ko aarun naa.

Bo tilẹ jẹ pe adinku ti ba bawọn eeyan ṣe n ko arun HIV, o ṣee ṣe ki ọwọja aarun naa tun lọ soke pẹlu idaduro owo iranwọ ajọ USAID ti ọpọ eeyan to larun yii fi n ri oogun ti wọn n lo gba.