NAHCON àti Saudi fẹnukò lórí iye èèyàn tí yóò wá láti Naijiria fún Hajj 2025

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ajọ to n risi irinajo lọ si ilẹ mimọ, Mecca, NAHCON, ti kede pe igbaradi ti bẹrẹ bayii lori Hajj fun ọdun 2025, ti wọn si ti fẹnu ko lori iye eeyan ti yoo rin irinajo naa lọ si Saudi ati ọkọ baalu ti yoo ko awọn eeyan.

NAHCON ni awọn ti tọwọbọ iwe adehun pẹlu ileeṣẹ kan ni Saudi lẹyin ti awọn alaṣẹ ileeṣẹ naa ṣabẹwo si orilẹede Naijiria.

Ọjọgbọn Abdullahi Saleh Usman, alaga ajọ NAHCON sọ fun BBC pe gbogbo nnkan to yẹ ni awọn ti ṣe bayii.

"A ti se ayẹwo gbogbo awọn ọkọ baalu ti yoo rin irinajo naa, ati bi igbayegbadun awọn eeyan ni Medina ati Makeh yoo se rọnu.

"Gbogbo nnkan to yẹ ki a se ni a le sọ pe ati se bayii."

Saaju ni ede-aiyede kan bẹ silẹ laarin ajọ NAHCON ati ajọ Hajj.

Ọjọgbọn Usman sọ pe ṣugbọn wiwa awọn alaṣẹ Hajj si orilẹede Naijiria ti pese ojutu si ede-aiyede naa.

NAHCON ni aarẹ ileeṣẹ naa ati awọn alaṣẹ mii wa si Naijiria lati wa ojutu si ọrọ to fa ede ayede naa.

"Ni Naijiria, wọn fun wa ni ijoko fun ẹgbẹrun marundinlọgọrun eeyan, ṣugbọn a ri pe a ko le ko eeyan ẹgbẹrun marundinlọgọrun wa si Hajj.

Usman ni awọn ti sọ fun awọn alaṣẹ naa pe awọn yoo ko eeyan to le ni ẹgbẹrun lọna ogogi tabi aadọta wa .

"A si n gba ifọrukọsilẹ bayii ṣugbọn gbogbo eto ti n to bayii."