Hamas tú méjì nínú mẹ́fà ọmọ Ísírẹ́lì tó wà ní àhámọ́ sílẹ̀ lónìí

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ileeṣẹ ologun Hamas ni erongba wa pe wọn yoo tu gbogbo awọn ọmọ orilẹede Israeli to wa ni ahamọ wọn silẹ lonii.
Meji ninu awọn eeyan naa ni wọn a gbọ pe wọn ti gba ominira bayii, ti igbagbọ si wa pe awọn mẹrin yooku naa yoo gba ominira laipẹ lonii.
Iroyin to tẹ wa lọwọ ni awọn mọlẹbi awọn eeyan naa ti wọn gbe ọkan soke ti wọn si n reti lati tẹwọgba awọn eeyan wọn.
Mẹrin ninu wọn ni o ko sọwọ Hamas ni ọjọ keje oṣu kẹwaa, ọdun 2023, ti awọn meji yoo si ko sọwọ wọn niluu Gaza.
Orilẹede Israel ni awọn eeyan meji naa ti balẹ si orilẹede naa, ti wọn si ti n gbe wọn lọ sibi ti wọn yoo ti darapọ mọ awọn mọlẹbi wọn
Bakan naa ni ireti wa pe Israel yoo tu o le ni eeyan 600 ọmọ Palestine silẹ lati le tẹwọgba awọn eeyan mẹfa naa.
Lọsẹ to kọja ni Aarẹ Donald Trump orilẹede Amẹrika sọ pe orilẹede Israel ni lati fagile adehun idawọ ogun duro to buwọlu ti ẹgbẹ Hamas ba kọ lati tu awọn ọmọ Israel ti wọn ko ni igbekun silẹ.
Aarẹ Trump ni Hamas gbọdọ tu awọn ọmọ Israel to jigbe ni Gaza silẹ titi ago mejila ọsan ọjọ Abamẹta to n bọ, bi bẹẹ kọọ, Israel gbọdọ ṣina bolẹ.
Trump sọrọ yii lẹyin ti Hamas sọ pe idi tawon ko fi tii tu awọn ọmọ Israel to wa ni akata awọn silẹ ni pe Israel si tapa si adehun jógun-ó-mí t'awọn jọ tọwọ bọ.















