Ìwádìí BBC tú àṣírí bí iléeṣẹ́ apòògùn India kan ṣe ń kó òògùn olóró Opioid wọ Nàìjíríà, Ghana àti Ivory Coast

Aworan Vinod Sharma pẹlu fila lori rẹ
    • Author, BBC Eye Investigations
    • Role, BBC World Service
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Iṣẹ iwadii BBC ti tu aṣiri bi ileeṣẹ apoogun orilẹede India kan ṣe n ko oogun oloro Opioid wọ ẹkun iwọ oorun ilẹ Afirika eleyii to m ṣakoba eto ilera araa;u.

Ileeṣẹ apoogun Aveo to wa niluu Mumbai n ṣe oogun yii pẹlu oniruuru orukọ eyi to jẹ ko dabi oogun gidi.

Ṣugbọn oriṣiiriṣii eroja oloro bii ''tapentadol, opioid to lagbara ati carisoprodol ni wọn dapọ to wa ninu oogun yii.

Ko si orilẹede ti wọn ti faye gba tita oogun yii fun araalu, koda, o maa n ṣokunfa ki eeyan ma lee mi daadaa ati giri.

Koda, apọju oogun naa ninu ara le ṣeku pa eeyan.

Bo tilẹ jẹ pe ewu pọ ninu oogun yii, o wa kaakiri ori igba lawọn orilẹede iwọ oorun ilẹ Afirika tori owo rẹ ko gani lara.

Ninu iṣẹ iwadii ti BBC ṣe ni wọn ti ri paali oogun naa pẹlu ami ileeṣẹ apoogun Aveo fun tita ni Naijiria, Ghana ati Cote D'Ivoire.

Ẹwẹ, akọroyin BBC kan lọ si ileeṣẹ ipoogun Aveo lorilẹede India ti o si ṣe bii oniṣowo to fẹ ko oogun Opioid lọ si Naijiria.

Bayii ni akọroyin naa ti ẹrọ kamẹra wa lara rẹ ba awọn ọga agba ileeṣẹ apoogun Aveo pade ti o si ṣafihan oogun oloro yii kan naa to n ṣakoba fun ilera araalu ni iwọ oorun ilẹ Afirika.

Ninu fidio ti BBC fi ọgbọn ka silẹ ni wọn ti sọ fun Sharma pe erongba awọn ni lati ta oogun fawọn ọdọ ni Naijiria tori wọn fẹran oogun naa.

Ni ipari ipade yii ni Sharma sọ pe oogun yii le ṣakoba fun ilera araalu, amọ, o ni okowo gidi ni.

Àkọlé fídíò, Vinod Sharma sọ ninu fidio wi pe oogun opioid lewu debi pe o le ṣakoba fun ilera eeyan

Okowo to n ṣakoba fun ilera ni oogun yii, o si tun ṣakoba fun ọjọ ọla ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu awọn ọdọ kaakiri iwọ oorun Afirika.

Fun apẹẹrẹ, ọpọ niluu Tamale ni Ghana lo n lo oogun oloro yii debi wi pe Oloye kan, Alhassan Maham ni lati da awọn ẹṣọ kan silẹ ti wọn n mu awọn to n ta oogun yii.

Oloye Maham ni ''oogun yii maa n 'sakoba fun ọpọlọ awọn to n lo o, ni ṣe lo dabi ẹni pe eeyan n da epo karosin si ina.''

Ẹnikan ti oogun naa ti di baraku fun niluu Tamale sọ pe ''oogun yii ti faye wa ṣofo.''

BBC tẹle awọn ẹsọ to n mawọn to n ta oogun yi, a si ri ọdọkunrin kan to ṣubu soju ọna lẹyin to ti loogun yii.

Aworan ọdọkunrin kan ni Tamale ti igbagbọ wa pe o ti lo oogun oloro tafrodol
Àkọlé àwòrán, Ọdọkunrin kan ni Tamale ti igbagbọ wa pe o ti lo oogun oloro tafrodol

Nigba ti ọwọ tẹ ẹnikan to n ta oogun naa, a ri wi pe awọn paali oogun naa ni ami ileeṣẹ apoogun Aveo lara.

Kii ṣe ilu Tamale nikan ni oogun yi wa, BBC ri oogun yii lawọn apa ibomiran lorilẹede Ghana.

A tun ri ẹri to daju pe oogun yii ti ileeṣẹ ipoogun Aveo n ṣe wa kaakiri ni Naijiriaati Cote D'Ivoire fun tita nibi tawọn ọdọ ti po o pọ mọ ọti ti wọn n mu ki o le pa wọn daadaa.

Akọsilẹ nipa bi ọja ṣe n lọ ilẹ okeere fihan pe ileeṣẹ apoogun Aveo ati ẹka rẹ Westfin n ko ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu oogun oloro lọ si Ghana atawọn orilẹede mii ni ẹkun iwọ oorun Afirika.

Orilẹede Naijiria tawọn eeyan rẹ to ojilelugba miliọnu ati marun un (225m) ni ọja oogun yii ti ta julọ.

Ajo oluṣiro ni Naijiria, NBS, sọ pe ọmọ Naijiria bii miliọnu mẹrin lo n lo oogun opioid ni ilokulo.

Alaga ajọ NDLEA, Ọgagun fẹyinti Mohammed Buba Marwa, sọ fun BBC pe ''oogun opioid n baye awọn ọdọ wa jẹ, o n ṣakoba fun ẹbi ati awujọ wa ni Naijiria.''


Aworan oogun oloro ti ẹnikan ko dani niluu Tamale ni Ghana
Àkọlé àwòrán, Oogun oloro ti ẹnikan ko dani niluu Tamale ni Ghana
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lọdun 2018, lẹyin ti BBC Africa Eye gbe iṣẹ iwadii kan jade lori bi oogun opioid ṣe n ṣakoba fawọn ọdọ, ijọba gbiyanju lati gbe igbesẹ lori bawọn eeyan ṣe n lo oogun tramadol lilo kulo.

Ijọba fofin de tita oogun tramadol lai jẹ pe dokita paṣẹ lilo rẹ.

Ijọba tun kede ofin iye ti eeyan le lo, bakan naa ni ijọba tun bogun ti awọn to n ko oogun naa wọle lọna aitọ.

Ko pe lẹyin ti ijọba gbe awọn igbesẹ yii ni ileeṣẹ apoogun Aveo bẹrẹ si ni ko oogun oloro mii to ni ṣe pẹlu tapentadol lọ si ilẹ okeere.

Awọn onwoye kan ni ẹku iwọ oorun Afirika sọ pe awọn to n ṣe oogun yii n ko o ranṣẹ silẹ okeere lẹyin ti ijọba ti fofin de tramadol.

Ni paali paali ni wọn to oogun oloro yii lera wọn nileeṣẹ apoogun Aveo.

Koda, Vinod Sharma ṣefihan oniruuru paali oogun tapentadol-carisoprodol ti ileeṣẹ naa n ta pẹlu oriṣiiriṣii orukọ bii Tafrodol, TimaKing tabi Super Royal-225.

Dokita Lekhansh Shukla ti ipo rẹ kangun si ipo Ọjọgbọn ni ile ẹkọ to n ri ọrọ awọn alarun ọpọlọ ni Bengaluru lorilẹede India sọ pe oogun tapentadol le jẹ ki eeyan sun lọ fọnfọn.

O ni oorun le lagbara debi wi pe eeyan le ma mi daadaa mọ.

Bakan naa ni Dokita Shukla tun ṣalaye pe oogun carisprodol naa le jẹ ki eeyan sun lọ fọnfọn.

Dokita naa sọ pe adapọ oogun mejeeji yii lagbara gan an, o si le ṣakoba to pọ fun agọ ara.

Wọn ti fofin de oogun carisoprodol ni Yuroopu, wọn le lo o l'Amẹrika ṣugbọn fun ọsẹ mẹta pere ni.

Ai ri oorun sun ati ipaya wa lara awọn ami ti eeyan yoo maa ri kete to ba ti dawọ lilo oogun naa duro.

Aworan awọn paali oogun oloro

Dokita Shukla ni apopọ oogun oloro tapentadol ati carisoprodol lewu ju fun agọ ara eeyan.

O ni eeyan si le lo tramadol ti dokita ba sọ pe ki eeyan lo, amọ, apopọ tapentadol ati carisoprodol buru jai.

Lorilẹede India, awọn ileeṣẹ apoogun ko le ṣe oogun ki wọn si ko ranṣẹ si ilẹ okeere labẹ ofin lai jẹ pe wọn tẹle gbogbo ofin to de iru nnkan bayii.

Amọ, ileeṣẹ apoogun Aveo n ko Tafrodol atawọn oogun oloro mii ranṣẹ si Ghana nibi ti ijọba ti fofin de awọn oogun yii.

A beere ọrọ yii lọwọ Vinod Sharma ati ileeṣẹ ipoogun Aveo, wọn o fun wa lesi kankan.

Ajọ CDSCO to n ri si ọrọ oogun lilo ni India sọ pe awọn mọ ojuṣe awọn lori ipa tawọn ni lati ko lori eto ilera lagbaaye.

Ajọ CDSCO ni oun ti n ṣiṣẹ pọ pẹlu ọpọlọpọ orilẹede lati to fi mọ ẹku iwọ oorun Afirika lati wa ojutuu si i'soro oogun oloro ti n ti India jade.

Ajọ naa ni oun ko ni bẹsu bẹgba lati fiya jẹ ileeṣẹ apoogun ti aje iwa ibajẹ yii ba ṣi mọ lori.

Aworan ẹyin paali oogun Tafrodol
Àkọlé àwòrán, Ẹyin paali oogun Tafrodol

Kii ṣe Aveo nikan ni ileeṣẹ apoogun to n ko oogun oloro opioid ranṣẹ silẹ okeere.

Akọsilẹ fi han pe oniruuru ileeṣẹ apoogun lo n ṣe irufẹ oogun oloro yii to si wa kaakiri ẹkun iwọ oorun Afirika.

Awọn ileeṣẹ apoogun yii n ba orukọ ẹka ileeṣẹ apoogun India jẹ, eyi to n dagba daadaa ti oogun to n ṣe si ti doola ẹgbẹlegbẹ miliọnu awọn eeayn.

Awọn oogun tawọn ileeṣẹ apoogun India n fi ranṣẹ silẹ okeere lọdun kan to $28bn niye.

Nigba to n sọrọ lori ipade rẹ pẹlu Sharma, akọroyin BBC ti a ko le jẹ kawọn eeyan da mọ fun aabo rẹ ni ''awọn akọroyin ọmọ Naijiria ti n sọ nipa oogun oloro fun bii ogun ọdun, ṣugbọn mi wa pẹlu ọkan lara awọn to n ko oogun yii lọ si ẹkun iwọ oorun Afirika.

O mọ ipa ti nnkan to n ṣe ni, amọ, ko bikita rara, o ni okowo ni.''

Niluu Tamale lorilẹede Ghana, ikọ BBC tẹle awọn ẹṣo to n wa awọn to n ta oogun oloro yii.

A ri wọn nibi ti wọn ti fẹ dana sun awọn oogun oloro ti wọn ri gba lọwọ awọn to n ta a.

Zickay to jẹ ọkan lara awọn ẹṣọ naa pe awọn maa n dana sun oogun oloro tawọn gba ki gbogbo eeyan le ri.

Bo tilẹ jẹ pe wọn dana sun awọn oogun oloro yii, awọn to n pese rẹ ti wọn n ko o ranṣẹ lati India si n ri ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu nibi kiko oogun naa ranṣẹ si iwọ oorun ilẹ Afirika.