Ẹja gbé arákùnrin kan mì, ló bá tún pọ̀ ọ́ sílẹ̀

Àkọlé fídíò, Ẹja gbá arákùnrin kan mì, ló bá tún pọ̀ ọ́ sílẹ̀
Ẹja gbé arákùnrin kan mì, ló bá tún pọ̀ ọ́ sílẹ̀

Ṣe wọn ni iku to ba fẹ pa ẹda, to ba ṣi i ni fila, ko yara dupẹ fun ori rẹ ni.

Eyi ni ọrọ to ṣapejuwe iṣẹlẹ kan to ṣẹ si arakunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Andrian Simancas lasiko to lọ si odo nla kan.

Ere idaraya ọkọ oju omi wiwa, eyi ti oyinbo n pe ni 'Kayak' loun atawọn eeyan rẹ kan lọ ṣe ni ojo nigba ti ẹja nla Whale kan ba gbe e mi.

Leti okun Chilean Patagonia ni oun ati baba rẹ lọ nigba ti iṣẹlẹ naa ṣẹ.