'Èrò wa ni pé ògùn abẹnugọ̀ǹgọ̀ ni wọ́n lò fún ọmọ wa', Bàbá Yetunde tí Ààfáà pa, gé òkú rẹ̀ sí wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ ní Ilorin sọ̀rọ̀
Laipẹ yii ni iroyin jade pe wọn n wa Hafsah Yetunde Lawal, ọ̀dọmọbinrin to ṣẹṣẹ kẹkọjade kan ni ilu Ilọrin, ki o to di wi pe wọn ba oku rẹ lẹyin ọjọ diẹ ni ile Aafaa kan ti orukọ rẹ n jẹ Abdurahman Muhamadu Bello nibi ti o kun un wẹlẹwẹlẹ si ninu ile rẹ.
Nigba ti BBC kan si ile awọn obi Yetunde, inu ibanujẹ ni wọn wa, ti wọn si n ke gbajare pe, ohun to ṣẹlẹ ti ṣẹlẹ, amọṣa ohun iranwọ ti ijọba le ṣe ni ki wọn rii daju pe oloogbe naa gba idajọ ododo.
Baba Oloogbe naa, Ibrahim Adefalu ṣalaye pe awọn ọlọpaa lo sọ fun awọn nigba ti awọn de agọ ọlọpaa pẹlu ero pe aye rẹ lawọn fẹ wa gbe, pe "Aafaa yẹn naa lo paa".
Ni tirẹ, iya oloogbe naa, Arabinrin taibat Lawal ṣalaye pe Yetunde ti pari eto ẹkọ rẹ ati pe kii ṣe ọmọ to n jade lai dagbere ibi to n lọ nile.
Iya oloogbe naa ṣalaye pe ọsẹ to kọja yii lo ṣẹṣẹ lọ gba iwe ẹri olukọ agba NCE rẹ lati fi wa iṣẹ
Baba Oloogbe naa ni imọ ẹrọ igbalode ni wọn fi waa ri.












