Kí ni ètò ààbò táwọn gómìnà ilẹ̀ Yorùbá kéde pé àwọn fẹ́ dá sílẹ̀?

Oríṣun àwòrán, Babajide Sanwo-Olu/X
Àwọn gómìnà ilẹ̀ Yoruba ti fẹnukò láti ṣe ìdásílẹ̀ ikọ̀ kan tí yóò máa mójútó ètò ní ẹkùn náà.
Ìdásílẹ̀ ikọ̀ náà ló ń wáyé lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan tí àwọn àlùfáà ìjọ Aguda tí a mọ̀ sí 'Catholic Bishops' ní ìpínlẹ̀ Oyo pàrọwà sáwọn gómìnà náà láti fọwọ́sowọ́pọ̀, láti gbógunti bí àwọn agbébọn ṣe ń wọ ilẹ̀ Yorùbá.
Àwọn àlùfáà náà, níbi ìpàdé ọlọ́jọ́ méjì kan tí wọ́n ṣe ní ìlú Ibadan, sọ pé ìkọlù àwọn darandaran, ìjínigbé, ìdigunjalè àti àwọn ìwà ọ̀daràn míì tún ti ń wáyé ní ìpínlẹ̀ Oyo àti Ogun látàrí bí àwọn àjòjì ṣe ń wọ ẹkùn náà.
Ṣáájú ni Aare Ona Kakanfo ilẹ̀ Yorùbá, Iba Gani Adams náà ti ké sí àwọn gómìnà ilẹ̀ Yorùbá láti tètè wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣàdá lórí ètò ààbò ilẹ̀ Yorùbá.
Gani Adams sọ fún BBC News Yorùbá pé àwọn afurasí ọ̀daràn ń wọ ilẹ̀ Yorùbá láti òkè ọya tó sì jẹ́ pé iṣẹ́ ìwàkusà ni wọ́n fi ń bojú pé àwọn ń ṣe.
Ó ní ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀daràn yìí ló ti kún inú igbó tó wà ní ìlú Ilesha ní ìpínlẹ̀ Osun fọ́fọ́, tó sì jẹ́ pé àwọn tí wọ́n ń wa kùsà lọ́nà àìtọ́ ló ń fi wọ́n pamọ́ lágbègbè náà.
Aare Ona Kakanfo ṣàlàyé gbogbo àwọn gómìnà ilẹ̀ Yorùbá ni òun ti kọ̀wé ránṣẹ́ sí pé kí wọ́n jẹ́ kí àwọn jọ ṣiṣẹ́ papọ̀ láti lè lé àwọn afurasí ọ̀daràn náà kúrò nílẹ̀ Yorùbá pátápátá.
Báwo ni ikọ̀ náà yóò ṣe máa ṣiṣẹ́?
Ẹ̀wẹ̀, ìgbìmọ̀ àwọn gómìnà ilẹ̀ Yorùbá níbi ìpàdé tí wọ́n ṣe ní ọjọ́bọ̀ ní ìpínlẹ̀ Eko ti fẹnukò báyìí láti gbé ìgbìmọ̀ tí yóò máa mójútó ètò ààbò ní ẹkùn náà dìde.
Àtẹ̀jáde kan tí gómìnà ìpínlẹ̀ Eko, tó tún jẹ́ alága ìgbìmọ̀ àwọn gómìnà ilẹ̀ Yorùbá, Babajide Sanwo-Olu sọ pé ṣíṣe ìdásílẹ̀ ìgbìmọ̀ náà jẹ́ ìfarajìn àwọn gómìnà láti ri dájú pé ààbò tó gbópọn wà nílẹ̀ Yorùbá.
Ó ní àwọn ti ṣàwárí rẹ̀ pé ètò ààbò ilẹ̀ Yorùbá ti ń ní kọ́nú n kọ́họ nínú ni àwọn ṣe pinnu láti dá ìgbìmọ̀ 'Joint Surveillance and Monitoring Team' láti tètè kojú ìdúnkokò náà.
Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde náà ṣe sọ, wọ́n yóò ra àwọn ohun èlò ààbò ìgbàlódé sí gbogbo àwọn ìpínlẹ̀ ilẹ̀ Yorùbá láti fi máa mójútó ààbò wọn.
Ó ní àwọn irinṣẹ́ yóò máa ṣe àwárí bi tí àwọn afurasí ọ̀daràn bá wà, tí àwọn yóò sì ri dájú pé ikọ̀ yìí ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò tó ti wà nílẹ̀ tẹ́lẹ̀, tó fi mọ́ àwọn ti ìjọba àpapọ̀ àtàwọn ìbílẹ̀.
Afenifere kan sáárá sí ìgbésẹ̀ àwọn gómìnà náà
Ẹgbẹ́ Afenifere ilẹ̀ Yorùbá ti gbé òṣùbà kááre fáwọn gómìnà ilẹ̀ Yorùbá fún ìpinnu wọn láti ṣe ìdásílẹ̀ ìgbìmọ̀ tí yóò máa mójútó ààbò ní ẹkùn náà.
Agbẹnusọ Afenifere, Jare Ajayi nínú àtẹ̀jáde kan tó fi ránṣẹ́ sí BBC News Yoruba sọ ipinnu àwọn gómìnà náà láti ṣàmúlò ìmọ̀ ẹ̀rọ ìgbàlódé láti ṣàmójútó ètò ààbò jẹ́ ohun tó dára gidi pàápàá pẹ̀lú bí ètò ṣe mẹ́hẹ ní orílẹ̀ èdè lápapọ̀ lásìkò yìí.
Ajayi ní iṣẹ́ náà kò ní ṣòro fún wọn láti ṣe nítorí gbogbo àwọn ilẹ̀ Yorùbá yìí yàtọ̀ sí ìpínlẹ̀ Eko ni wọ́n ti ní ẹ̀ṣọ́ ààbò Amotekun tẹ́lẹ̀.
Ó ní ohun tí wọ́n nílò báyìí ni láti dá Amotekun sílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Eko, kí wọ́n sì ri dájú pé wọ́n ro wọn lágbára pẹ̀lú àwọn irinṣẹ́ tó yẹ, kí wọ́n le ṣe iṣẹ́ wọn bó ṣe yẹ.
Bákan náà ló rọ àwọn gómìnà ọ̀hún láti ṣe àmúṣẹ àwọn ìlérí wọn ní kíákíá nítorí bí iṣẹ́ kò bá pẹ́ni ẹnìkan kìí pẹ́ iṣẹ́.















