Odò yípadà di odò ẹ̀jẹ̀, wo ìdí abájọ

Àkọlé fídíò, Odò yípadà di pupa
Odò yípadà di odò ẹ̀jẹ̀, wo ìdí abájọ
Àwòrán odò tó di pupa bí ẹ̀jẹ̀
Àkọlé àwòrán, Aworan odo to di pupa bi ẹjẹ

Kayeefi gbaa lo ṣi n jẹ fun awọn eeyan agbegbe kan lorilẹede Argentina, nibi ti odò ti yipada lojiji to si di pupa bi ẹjẹ.

Gẹgẹ bi araalu naa to wa ninu fidio yii ṣe ṣalaye fun BBC, o ni awọn kan ni wọn n dana sun ilẹ ni kutukutu owurọ.

Bi wọn ṣe n sun ilẹ naa ni nnkan bii aago marun-aabọ idaji ni kurukuru ati idọti gba oju ọrun.

Eefin to n ti ara ina ọhun wa n lọ soke pẹlu bo ṣe wi.

Nigba ti ilẹ yoo si fi mọ, ti wọn jade sita lo di pe odo ti wọn n mu ti paarọ awọ, o ti di odo ẹjẹ patapata.

Idi kayeefi ọhun ni wọn ṣi wa, ibanujẹ si dori agba wọn kodo pẹlu.