'3,907 ìbọn AK-47 di àwátì láwọn olú iléeṣẹ́ ọlọ́pàá káàkiri Naijiria'

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹka ile igbimọ aṣofin Naijiria to n mojuto ọrọ to n lọ nileeṣẹ ọba ti kede pe ọgọrọ ibọn AK-47 lo ti sọnu bayii ni awọn olu ileeṣẹ ọlọpaa kaakiri orilẹede yii.
Ibọn AK-47 to din diẹ lẹgbẹrun mẹrin (3,907) ni ẹka 'Public Account Committee', sọ pe wọn ti sọnu bayii kaakiri olu ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, aṣiri yii tu lẹyin ti ọfiisi Ayẹ̀wé owó-wò àgbà lorilẹede yii, (Auditor-General of the Federation), yẹ iwe ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria wo.
Bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ni ẹka to n wadii to si maa n ri si eto wọn, ṣugbọn ko jọ pe wọn ri aṣiri ti ile igbimọ tu yii.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀

Oríṣun àwòrán, @NPF
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, ACP Olumuyiwa Adejobi, nigba to n tako ohun ti ile igbimọ aṣofin sọ yii, sọ pe iroyin to le ṣi eeyan lọna ati irọ gbuu ni.
Adejobi ṣalaye ninu atẹjade kan to fi si oju opo X rẹ lọjọ kẹtala, oṣu Keji ọdun 2025, pe ibọn 3,907 kankan ko sọnu nileeṣẹ ọlọpaa kaakiri Naijiria lasiko yii.
O ni ikede naa le wa lati lati ọfiisi ayẹwo-wo agba lorilẹde yii, ṣugbọn ki i ṣe fun asiko yii, bi ko ṣe fun ọdun 2019 ti wọn ṣe ayẹwo, ṣaaju ki ọga ọlọpaa to wa lori aleefa bayii too gba ipo rara.
''O ṣe pataki lati mọ ohun ti oju awọn ọlọpaa n ri nigba yẹn, asiko ti ifọkanbalẹ ko si, ti wọn n pa ọlọpaa ti wọn si n gbe nnkan ija wọn lọ, eyi lo ṣokunfa awọn nnkan ija to sọnu nigba yẹn.
''Ṣugbọn sibẹ naa, gbogbo ipa la sa lati mọ awọn nnkan ija ti wọn ko lọ nigba naa, pupọ rẹ la si ti gba pada pẹlu.
''Ohun kan tun ni pe nigba ti wọn ba waa yẹ ileeṣẹ wa wo, wọn le ma ba gbogbo ohun ti ani, nitori a ti maa ko ninu ẹ fun awọn to wa loju iṣe lati lo, awọn nnkan wọnyi maa n fa aiṣe-dede nigba ti wọn ba maa gbe iroyin rẹ jade''
Adejobi lo ṣalaye bẹẹ.
O fi kun un pe awọn ohun ti ki i ṣe ododo lo n jade nipa ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ju lẹnu ọjọ mẹta yii.
Bẹẹ o ni ileeṣẹ ọlọpaa n sa ipa rẹ lati jẹ ki eto aabo duro wamu, o kan jẹ pe awọn eeyan kan fẹran lati maa ba orukọ rere ati iṣẹ ti ọlọpaa n ṣe jẹ ni.
Eyi ko ni i di iṣẹ ti ọlọpaa n ṣe ku, gẹgẹ bo ṣe wi, bo tilẹ jẹ pe awọn nnkan bẹẹ maa n da omi tutu si ọkan eeyan, to si le di alaafia ilu lọwọ.
Adejobi sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ti ṣalaye tẹlẹ lori ohun ti ile igbimọ gbe jade yii, ki wọn le tọka awọn ohun ti ko ri bẹẹ fun wọn.
Bakan naa lo ni ijokoo ipade ile igbimọ aṣofin mi-in yoo tun waye lati tan imọlẹ si ọrọ naa.
Mọnde, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Keji ọdun 2025 ni ipade naa yoo waye, gẹgẹ bi ACP Adejobi ṣe sọ.















