Wọ́n ti lé akẹ́kọ̀ọ́ tó gé olùkọ́ rẹ̀ jẹ tó tún lù ú kúrò ní Yunifásítì

Aworan Precious Goddy ti wọn lo ge olukọ rẹ jẹ

Oríṣun àwòrán, Nnamdi Azikiw/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ọmọbinrin akẹkọọ to wa nipele kẹta ni Yunifasiti Nnamdi Azikiwe, Goddy Mbakwe Precious, ti wọn fẹsun kan pe o ge olùkọ́ rẹ, Chukwudi Okoye, jẹ ni wọn ti le danu nileewe naa bayii.

Atẹjade kan lati ọfiisi alukoro yunifasiti naa, Njelita Louis, fidi ẹ mulẹ, pe ọga agba ileewe yii, Joseph Ikechebelu, ti fi aṣẹ si ipinnu igbimọ to jokoo lori ọrọ naa, o si ti ni ki wọn le Precious kuro nileewe yii lẹyẹ-o-sọka.

Ninu atẹjade naa ni wọn ti ṣalaye pe gbogbo igun ti ọrọ naa kan ni wọn fun laaye lati ṣalaye ohun to ṣẹlẹ ṣiwaju.

Ṣugbọn gbogbo ẹri lo fi han pe iwa ti akẹkọọ naa hu tako iwa ijẹọmọluabi.

'' Iwa ti Goddy-Mbakwe Chiamaka Precious, akẹkọọ ipele kẹta lati ẹka imọ nipa itan ati iṣe ilẹ okeere, hu tako iwa ọmọluabi to de awọn akẹkọọ Nnamdi Azkiwe Yunifasiti

''Ẹsẹkẹsẹ ni aṣẹ yii ti bẹrẹ, a fẹ ko kuro ninu ọgba ileewe kia, ko si ko gbogbo ohun to jẹ ti yunifasiti wa to wa lọwọ rẹ silẹ''

Bẹẹ ni apa kan atẹjade naa ka.

Aworan iwe atẹjade ti wọn fi kede lile Precious Goddy kuro nileewe naa.

Oríṣun àwòrán, Nnamdi Azikiwe University.

'Ó yẹ kí wọ́n ṣe àyẹ̀wò ọpọlọ fún akẹ́kọ̀ọ́ tó gé olùkọ́ jẹ'

Chukwudi Okoye àti Goddy Precious

Oríṣun àwòrán, Chukwudi Okoye

Àwọn aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Nnamdi Azikwe University, Unizik ní ìwádìí ti bẹ̀rẹ̀ lórí ìfaǹfà tó wáyé láàárín akẹ́kọ̀ọ́bìnrin, Goddy Mbakwe Precious àti olùkọ́ Chukwudi Okoye.

Agbẹnusọ ilé ẹ̀kọ́ náà, Njelita Louis nínú àtẹ̀jáde kan tó fi léde ní àwọn aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́ náà kò fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú ìṣẹ̀lẹ̀ náà rárá.

Louis nínú àtẹ̀jáde náà rọ àwọn èèyàn láti ṣe sùúrù pẹ̀lú ilé ẹ̀kọ́ náà láti fi ṣe ìwádìí wọn.

Unizik ní àwọn máa gbé ìgbésẹ̀ tó bá yẹ lẹ́yìn tí àwọn bá parí ìwádìí àwọn tán.

Wọ́n ní ó pọn dandan fún àwọn láti ṣe ìwádìí ìṣẹ̀lẹ̀ náà dáradára láti fi ìdí òótọ́ múlẹ̀ àti láti ri pé àwọn gbọ́ ti tọ̀tún àti tòsì kí àwọn tó gbé ìdájọ́ àwọn kalẹ̀.

Àtẹ̀jáde náà fi kun pé gẹ́gẹ́ bí ilé ẹ̀kọ́ tó mú ìwà ọmọlúàbí ní òkúnkúndùn, àwọn kò ní fi ààyè gba kí ìwà àìtọ́, ìwà ìbàjẹ́ rídìí jókòó ní ilé ẹ̀kọ́ náà.

Gẹ́gẹ́ bí ilé ẹ̀kọ́ náà ṣe sọ, ipele kẹta ni akẹ́kọ̀ọ́ Precious wà, tó sì ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ 'History and International Studies'.

Àmọ́ wọn kò sọ àsìkò tí ìwádìí náà fi máa wáyé.

Ìwà búburú gbáà ni Precious hù - Dr Ikenna

Adarí ẹ̀ka ìmọ̀ ẹ̀kọ́ History and International Studies, Ọ̀mọ̀wé Ikenna Odife nígbà tó ń fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ojúlówó akẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀ka àwọn ni Precious, bu ẹnu àtẹ́ lu ìwà ìbàjẹ́ tó wù sí olùkọ́.

Ikenna ní ìwà tí akẹ́kọ̀ọ́ náà wù kìí ṣe ohun tó yẹ kí wọ́n máa bá lọ́wọ́ ọmọlúàbí àti pé nǹkan tí kò bójúmu tí kò yẹ kó wáyé nílé ẹ̀kọ́ gíga kankan.

Ó ní ó yẹ kí wọ́n lọ ṣe àyẹ̀wò ààrùn ọpọlọ fún akẹ́kọ̀ọ́ náà láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ bóyá ọpọlọ rẹ̀ ń ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ.

Ó wòye pé ṣíṣe ìwádìí ìgbà èwe akẹ́kọ̀ọ́ náà yóò tan ìmọ́lẹ̀ sí irú àwọn nǹkan tó bá ti là kọjá rí.

"Ìwà tó wù kìí ṣe ohun tí èèyàn gbọ́dọ̀ máa sọ rárá, ohun tó ṣeni láàánú ni, tí kò sí bójúmu rárá."

Akẹ́kọ̀ọ́ gé olùkọ́ jẹ, fà á láṣọ ya nítorí fídíò Tiktok

Aworan lati ibi fọnran ija to waye laarin olukọ ati akẹkọọo

Oríṣun àwòrán, Others

Ile ẹkọ fasiti Nnamdi Azikiwe niluu Akwa nipinlẹ Anambra ni iṣẹlẹ kayefi kan ti waye nibi ti akẹkọọ obinrin kan ti bu olukọ rẹ leyin, to si tun fa laṣọ ya pẹlu.

Dr Chukwudi Okoye ni o ṣalabapade isẹlẹ manigbagbe yii nigba to fẹ kọja lasiko ti akẹkọọbinrin naa n ka fọnran bi o se n jo silẹ lori ẹrọ ibaraẹnisọrọ rẹ fun opo ayelujara Tiktok.

Chiamaka Precious Mbakwe ni wọn ni o lu olukọ rẹ ni alubami, koda o kọja oye ọpọ eeyan nigba to tun fa laṣọ ya pẹlu.

Bo ti lẹ jẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Anambra ni awọn ko ti gbọ ohunkohun nipa iṣẹlẹ naa.

Ninu fọnran kan to lu sita lori ayelujara, o ṣafihan bi ariyanjiyan se bẹ silẹ laarin Okoye, ẹni to jẹ olukọ ni ẹka ile ẹkọ nipa iṣẹ tiata ati Chiamaka, to jẹ akẹkọọ imọ itan ati ajọsepọ agbaye ni fasiti naa.

Awọn oṣojumikoro to wa nibi iṣẹlẹ naa ni Chiamaka n jo, to si n ka fọnran fidio ara rẹ silẹ lori foonu rẹ lọjọ Aje.

Olukọ naa si ni ko duro pe ki oun kọja sugbọn akẹkọọ naa binu, to si kọlu olukọ rẹ.

Eyi lo mu ki olukọ naa pada, to si palaṣẹ fun akẹkọọ naa pe ko mu ẹrọ ibaraẹnisọrọ rẹ fun oun, ṣugbọn akẹkọọ naa kọ jalẹ, to si kọ lati fi foonu naa silẹ.

Dr Okoye ba BBC sọrọ, ṣalaye ohun to waye

Nigba ti Ileeṣẹ BBC kan si olukọ naa nipinlẹ Anambra ṣalaye pe oun ko ri akẹkọọ naa ri, ti oun si fọwọ tọ pe pe ko duro lasiko to n ka ijo rẹ, ko si fun oun laaye lati kọja.

"Bi o se bẹrẹ niyẹn. Mo n wa pe pe ko yọ mi kuro nibi fọnran to ka sori foonu rẹ.

"O kọ, to si lọ sinu baaluwẹ , to si bẹrẹ si ni ma sọrọ si mi, lẹ okuta mọ mi, to si ya aṣọ mi.

Okoye ni ọrọ naa ti de ọdọ awọn alaṣẹ ile ẹkọ fasiti, ti oun naa si ti lọ si ile iwosan fun itọju ara rẹ.

Nigba ti BBC pe Precious, ẹni to jẹ ọmọ olukọ mii ni fasiti naa, o kọ lati gbe ipe rẹ.

Nigba to ya, o pa ẹrọ ibaraẹnisọrọ rẹ.

Ṣugbọn o gbe sori opo ayelujara, to si fẹsun kan olukọ naa pe o fi ọwọ tẹ ọyan rẹ, to si jẹ ko di mimọ pe, oun gbiyanju lati da bobo ara oun ni lasiko ikọlu naa.

Gbogbo igbiyanju wa lati kan si awọn alaṣẹ ile ẹkọ fasiti naa lo jasi pabo.