Àwọn nǹkan mẹ́wàá tó yẹ kí o mọ̀ nípa àgbà ẹgbẹ́ Afenifere, Pa Ayo Adebanjo tó jáde láyé

Pa Ayo Adebanjo

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Èèkàn ẹgbẹ́ Afenifere ilẹ̀ Yoruba, Pa Ayo Adebanjo ti jáde láyé.

Ní òwúrọ̀ ọjọ́, Ẹtì, ọjọ́ Kẹrìnlá, ọdún 2024 ni Adebanjo dágbére fáyé lẹ́ni ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún (96).

Agbẹnusọ ẹgbẹ́ Afenifere, Jare Ajayi ló fìdí ìròyìn náà múlẹ̀ fún BBC News Yorùbá.

Ilé rẹ̀ tó wà ní agbègbè Lekki, ìpínlẹ̀ Eko ni Adebanjo dákẹ́ sí.

Pa Adebanjo bẹ̀rẹ̀ sí ní darí ẹgbẹ́ Afenifere nígbà tí ààrẹ ẹgbẹ́ náà, Bàbá Fasoranti ní kí ó máa delé fún òun látàrí ọjọ́ orí òun.

Ta ni Pa Ayo Adebanjo?

Ní ọjọ́ Kẹwàá, oṣù Kẹrin, ọdún 1928 ni wọ́n bí Pa Ayo Adebanjo.

Ayo Adebanjo lògbà láyé ìgbà tí àwọn òyìnbó amúnisìn wà ní Nàìjíríà, lógbà lẹ́yìn tí Nàìjíríà gba òmìnira, láyé ológun àti lẹ́yìn tí ìjọba padà sọ́wọ́ ìjọba alágbádá.

Ọdún 1943 ló bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò òṣèlú gẹ́gẹ́ bí ọmọlẹ́yìn ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí ní Nàìjíríà, Nnamdi Azikwe kó tó darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Action Group lọ́dún 1951 lábẹ́ ìdarí Olóyè Obafemi Awolowo.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Adebanjo ní ìfarajìn sí àwọn ìwòye Awolowo nídìí èyí tó ń pè fún ètò ẹ̀kọ́ ẹ̀fọ́, fífi àyà gba ìṣèjọba tòótọ́ àti mímú ìgbé ayé àwọn èèyàn rọrùn.

Ọdún 1962, nígbà tí wàhálà bẹ́ sílẹ̀ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú Action Group, wọ́n fẹ̀sùn ìdìtẹ̀ mọ́ ìjọba kan Adebanjo tó sì sálọ sí orílẹ̀ èdè Ghana.

Bàbá rẹ̀ ni wọ́n fi òfin gbé, tí wọ́n sì fi sí àhámọ́ dipò rẹ̀.

Ó kó ipa tó lágbára nínú NADECO lẹ́yìn tí ìjọba ológun da ètò ìdìbò June 12, 1993 nù, ó dúró tako ìṣèjọba ológun, tó sì ń pè fún dídá ìjọba padà sọ́wọ́ àwọn alágbádá.

Adebanjo jẹ́ ẹni tó máa ń pè fún àtúntò Nàìjíríà ní gbogbo ìgbà, tó ṣe máa ń sọ pé ṣíṣe ètò ìjọba àpapọ̀ lọ́nà tó yẹ ló le mú Nàìjíríà dúró lẹ́yọ̀kan.

Akọ̀ròyìn ni Pa Adebanjo kó tó lọ kẹ́kọ̀ọ́ nípa òfin ní orílẹ̀ èdè England, tí kìí sì kùnà láti lo àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn láti fi fi èrò rẹ̀ hàn.

Pa Ayo Adebanjo kìí kùnà láti tako ìjọba tí kò bá ti fi ìlọsíwájú ilẹ̀ Yorùbá sínú ètò rẹ̀, tó sì jẹ́ ẹni tí kìí fi ọ̀rọ̀ jíjẹ́ ọmọlúàbí ṣeré rárá.

Ìyàwó rẹ̀, ẹni ọdún mẹ́rìnléláàádọ́rùn-ún, àwọn ọmọ àti ọmọọmọ ló gbẹ̀yìn Bàbá Adebanjo.