'Ìdí tí a fi ń bèèrè ìdásílẹ̀ kóòtù Sharia nílẹ̀ Yorùbá rèé'

Aworan Sultan Sokoto, Alaaji Abubakar Sa'ad ati obinrin meji to boju .

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Agbarijọpọ igbimọ to ga julọ fun ofin Sharia lorilẹede Naijria (Supreme Council for Sharia In Nigeria)ati ẹgbẹ awọn musulumi ti wọn jẹ Yoruba ti ọrọ yii kan, (Concerned Yoruba Muslim Scholars in Nigeria), ti ṣalaye idi ti wọn fi n beere fun kootu Sharia nilẹ yii lati bii ọsẹ meloo sẹyin.

Ẹ o ranti pe ọpọ awuyewuye lo ti n jẹ jade lori ofin Sharia ti wọn n pe fun yii, pẹlu bi ọpọ eeyan ṣe n sọ pe ilẹ Yoruba ki i ṣe ilẹ Larubawa tabi ilẹ Hausa ti wọn ti n lo ofin Sharia.

Nigba ti wọn n ṣalaye awọn idi to fi yẹ ki kootu Sharia maa ṣiṣẹ ni awọn ipinlẹ Yoruba, igbimọ to ga julọ fun ofin naa lorilẹede yii, fi atẹjade kan sita lẹyin ipade oniroyin ti wọn ṣe ni Mosalaṣi Arisekola to wa n'Ibadan, lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kọkanla, oṣu Keji, ọdun 2025.

Wọ́n ti sọ àwa Mùsùlùmí ilẹ̀ Yorùbá di ẹni ẹ̀yìn, wọ́n kò fún wa nípò agbára

Ninu atẹjade naa ti wọn ti sọ pe ohun to n ṣẹlẹ nipa pinpin ipo agbara ninu ijọba Tinubu ko ṣee dakẹ si.

Awọn ẹgbẹ mejeeji yii sọ pe latigba ti Tinubu ati Shettima ti fẹẹ dije, ti wọn si jẹ Musulumi ni atako ti wa kaakiri lati ọdọ awọn Kristẹni.

Wọn ni iyalẹnu lo waa jẹ, pe pẹlu gbogbo iya ti awọn Musulumi ilẹẹ Yoruba jẹ ti awọn mejeeji yii fi wọle ibo, awọn Kristẹni ni wọn tun ko ipo agbara gbogbo le lọwọ ninu iṣejọba wọn.

''Ki gbogbo aye maa ranti pe lati igba ti Naijiria ti gba ominira ni wọn ti n ditẹ mọ awọn Yoruba ti wọn jẹ Musulumi, Oloogbe MKO Abiola to tun fẹẹ ṣẹgun ọtẹ naa, niṣe ni wọn tu fagile ibo rẹ.

''Awọn Oloye ERNEST Shonekan ati Olusegun Obasanjo ti won je Kristẹni ni won gbe e fun.

''Nigba ti Aarẹ Bola Tinubu naa tun gba ijọba ni 2023, awọn Kristẹni lo tun pọ ju nipo agbara ninu ijọba rẹ, ìyà ti àwọn Yoruba ti wọn jẹ Musulumi jẹ ko ja mọ nnkan kan.

''Ida ọgọrin (80%) ni awọn Kristẹni to wa ninu ijọba yii, titi kan awọn ti wọn tako o nibẹrẹ nitori pe Musulumi ni Aarẹ ati Igbakeji rẹ.

''Ọjọgbọn Ishaq Oloyede ti sọ ninu ọrọ rẹ, pe ''bi awa Musulumi ba wa nijọba, a ko lagbara, bi a ko ba si si nijọba, a ko lagbara kankan rara''

A fẹ́ kí wọ́n dá Kóòtù Sharia sílẹ̀ ní àwọn ìpínlẹ́ Yorùbá mẹ́fẹ̀ẹ̀fà, nítorí---

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

''Mọṣalaṣi nla to wa nilẹẹ Yoruba ju ẹgbẹrun mẹrindinlogun (16,000) lọ, awọn mọṣalaaṣi agboole si le ni ẹgbẹrun lọna ọọdunrun (300,000).

'' Ofin ominira ọdun 1960 ati ti 1963, fi aaye gba kootu Shariah ti yoo jẹ ile ẹjọ Ko-tẹ-mi-lọrun.

Bẹẹ naa si ni ofin 1979 fọwọ si i.

'' Lati 1894 ni awọn Musulumi ti n beere ofin Shariah l'Ekoo. Wọn tun beere ni 1923, nigba ti wọn o fun wỌn lakọọkọ.

''Ọba Timi Ede, Habeeb Olagunju (1900) ati Oluwoo Muhammad Lamuye (1906), lo ofin Sharia lati fi dajọ nigba aye e wọn.

'' Awọn Yoruba to jẹ Musulumi ko ba ẹnikẹni ja, wọn si fi aaye gba ẹsin tabi iṣe awọn eeyan yooku. Fun idi eyi, wọn lẹtọọ lati beere ohun to tọ si wọn.''

Wọnyi ati awọn koko mi-in ni ẹgbẹ Musulumi mejeeji yii la kalẹ, gẹgẹ bi idi ti wọn fi n beere fun idasilẹ Kootu Sharia, wọn si ni ireti awọn ni lati ri i pe o wa si imuṣẹ.

Sheikh AbdurRasheed Hadiyatullahi ni Aarẹ ẹgbẹ 'Supreme Council for Shari'ah in Nigeria', nigba ti Sheikh Abdurrasheed Mayaleeke, jẹ Alaga 'Concerned Yoruba Muslim Scholars in Nigeria'

Awọn mejeeji ni wọn buwọ lu atẹjade yii.