Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ NLC ní k'áráàlú dáwọ́ ríra dátà tàbí pípè lórí MTN, AIRTEL àti GLO dúró fún wákàtí mẹ́ta lójúmọ́

Aworan Joe Ajaero

Oríṣun àwòrán, Joe Ajaero/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC ti rọ awọn oṣiṣẹ at'awọn ọmọ Naijiria yooku lati ma pe lori foonu tabi ra data MTN, AIRTEL tabi GLO fun wakati mẹta lojumọ bẹrẹ lati oni Ọjọbọ ọjọ kẹtala oṣu Kejì.

Lẹyin ipade igbimọ aláṣẹ NLC to waye niluu Lokoja nipinlẹ Kogi ni ẹgbẹ naa ti kede igbesẹ yii lati fẹhonu wọn han lori afikun ida aadọta owo tariifu ori ipe ati data.

NLC fi aidunnu rẹ han lori bi awọn ileeṣẹ ibanisọrọ kan bii MTN ti ṣe afikun owo data t'awọn onibaara won n ra, bo tilẹ jẹ pe igbimọ ti ijọba gbe dide lati jiroro lori afikun owo tariifu naa ko tii pari isẹ rẹ, bẹẹ si ni ko tii jabọ.

NLC fi aidunnu rẹ han lori bi awọn ileeṣẹ ibanisọrọ kan bii MTN ti ṣe afikun owo data t'awọn onibaara won n ra, bo tilẹ jẹ pe igbimọ ti ijọba gbe dide lati jiroro lori afikun owo tariifu naa ko tii pari isẹ rẹ, bẹẹ si ni ko tii jabọ.

Ọsẹ meji ni igbimọ ẹlẹni mẹwaa eyi ti awọn aṣojú ẹgbẹ oṣiṣẹ ati ti ijọba wa níbẹ ni lati jiroro lori ọrọ naa ki wọn to dabaa igbesẹ to kan.

Ẹgbẹ NLC sọ lẹyin ipade rẹ nipinlẹ Kogi pe awọn ko ni jẹ k'awọn ileeṣẹ ibanisọrọ ṣiṣẹ kankan mọ ni Naijiria lati ọjọ kinni oṣu kẹta to n bọ, ti wọn ba kọ lati pada si iye ti araalu n ra data tẹlẹ.

Nibi Ipade ti wọn ṣe ọhun ni NLC ti sọ fun gbogbo oṣiṣẹ lati ma lo MTN, AIRTEL tabi GLO fun wakati mẹta lojumọ laarin aago mọkanla si aago meji ọsan lati oni Ọjọbọ titi di ipari oṣu Kejì yii.

Aarẹ ẹgbẹ NLC, Joe Ajaero ati akọwe agba ẹgbẹ naa, Emma Ugboaja, ni wọn jọ buwọlu atẹjade ti ẹgbẹ oṣiṣẹ fi sita lẹyin ipade wọn ni Lokoja.

"Kii ṣe asiko ti ijọba gbe owo gun ina mọnamọna ati epo bẹntiroolu, lo tun yẹ ko se afikun owo ipe ori foonu ati data"

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Saaju ni ajọ NLC ti bu ẹnu ẹtẹ igbesẹ ajọ NCC lori bi o ti buwọlu afikun owo tariifu lori ipe ati data.

NLC paṣẹ ninu atẹjadekan to fi sita wi pe ki gbogbo oṣiṣẹ dẹyẹ si lilo foonu tabi rira data lati ọjọ kẹrin oṣu Keji ti ijọba ba kọ lati ṣe idaduro afikun owo tariifu naa.

Ẹgbẹ oṣiṣẹ ni igbesẹ ajọ NCC yii buru jai, o si le ṣakoba fawọn oṣiṣẹ atawọn araalu lapapọ papaa julọ lasiko yii ti ọpọ ti ilu le koko latari awọn eto ti ijọba to wa lode n ṣe ti ko tii kẹsẹjari.

NLC ni awọn oṣiṣẹ yoo fẹhonu wọn han lori igbesẹ ajọ NCC yii nipa siṣe kaakiri orilẹede Naijiria.

Ajọ NCL sọ ninu atẹjade naa wi pe fifi ehonu han awon yoo jẹ ikilọ fun ijọba lati jẹ ki wọn mọ akoba ti afikun owo tariifu yii le ṣe fawọn oṣiṣẹ to n gba N70,000 gẹgẹ bii owo oṣu to kere julọ.

Ẹgbẹ oṣiṣẹ tun fikun ọrọ rẹ pe kii ṣe lasiko ti ijọba gbe owo ina mọnamọna ati epo bẹntiroolu lọ soke ti ọwọngogo nnkan gbode lo tun yẹ ki afikun tun ba owo tariifu fun ipe ori foonu ati data.

Gbogbo ẹka awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ lawọn ipinlẹ kaakiri Naijiria atawọn ẹgbẹ mii ni ajọ NLC ti rọ lati deye si ileese MTN, AIRTEL ati GLO.

NLC ko ṣai kepe ijọba apapọ, ajọ NCC ati ile aṣofin agba l'Abuja lati ṣepade pọ pẹlu awọn tọrọ kan lẹka eto ibaraẹnisọrọ, ki wọn da afikun owo tariifu naa duro.

Ajọ NLC ni ti ijọba ba kọ lati ṣe eleyii, ẹgbẹ oṣiṣẹ yoo tẹsiwaju pẹlu ifẹhonuhan to fẹ ṣe, ati pe awọn tun le dẹyẹ si ileeṣẹ ẹrọ ibaraẹnisọrọ kaakiri orilẹede Naijiria.