Àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò kún àwọn ìjọba ìbílẹ̀ fọ́fọ́ ní Osun, ìbẹ̀rù bojo gbọkàn àwọn òsìṣẹ́

'Inu fu aya fu ni a fi wa si bi isẹ loni, latari rogbodiyan awọn alaga ijọba Ibilẹ ti ile ẹjọ Kotẹmilọrun ni ki wọn ko pada si ofiisi' - ọkan lara awọn osisẹ ijọba ibilẹ Osogbo.
Niṣe ni ọkan awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ ni ipinlẹ Osun n ru soke latari idajọ ile ẹjọ Kotẹmilọrun to ni kawọn alaja ibilẹ ti ilẹ ẹjọ giga yọ nipo lọdun 2022 pada sipo wọn.
Ọpọ awọn oṣiṣẹ ni ko mọ odo ti wọn maa da ọrunla si, ti ibẹrubojo si gba ọkan wọn nitori wọn ko mọ eyi to maa jẹ ṣiṣe paapaa bawọn alaga naa ṣe ni awọn ti ṣetan lati gba ipo awọn pada.
Ọkan lara awọn alaga ti wọn fi ọwọ osi juwe ile fun lọdun 2022 naa, amọ ti ile ẹjọ ti da pada sipo bayii, Abiodun Idowu, sọ fun BBC News Yoruba pe awọn ti ṣetan lati pada si ọfiisi.
BBC News Yoruba ṣabẹwo si diẹ ninu awọn ọfiisi ijọba ibilẹ to wa nipinlẹ Osun lati wo ohun n to sẹlẹ nibẹ.
Lara awọn ileeṣẹ ijọba ibilẹ ti a de ni ijọba ibilẹ Osogbo, Olorunda àti Ede South.
Wamuwamu ni awọn agbofinro duro si ẹnu ọna abawọle awọn ileeṣẹ ijọba ibilẹ yii.


Arabinrin kan, ti ko fẹ ki a darukọ oun, ti o jẹ ọkan lara awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ Osogbo, sọ fun BBC pe niṣe ni ọkan awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ naa ṣe ko soke, pe awọn ko mọ nnkan ti yoo ṣẹlẹ lẹyin ti ile ẹjọ gbe are fawọn alaga naa ati eto idibo ti ijọba n palẹmọ fun.
Arabinrin naa sọ pe inu fu aya fu ni ọpọ awọn oṣiṣẹ fi lọ sibi iṣẹ wọn nitori awọn ko mọ ohun ti yoo ṣẹlẹ si awọn.
Ẹwẹ, Olawale Rasheed, agbẹnusọ fun gomina Adeleke ninu atẹjade kan to fi sita lọjọru, ọjọ Kọkanla, oṣu Keji ni gomina Ademola Adeleke dupẹ lọwọ awọn ẹgbẹ oṣelu to fẹ kopa ninu eto idibo ijọba ibilẹ to yoo waye ni ọjọ Kejilelogun, oṣu Keji, ọdun yii fun bi wọn ṣe gba alaafia laaye lati maa ṣe ìpolongo idibo wọn pẹlu alaafia.
Adeleke ni, gẹgẹ bii ijọba oun ṣe jẹ ijọba alaafia, bẹẹ ni eto idibo ijọba ibilẹ naa yoo ṣe lọ pẹlu ibẹru Ọlọrun ati alaafia.
"Gẹgẹ bi ẹ ṣe mọ wi pe, ọmọwe ni wa ni ipinlẹ Osun, a ko le maa fi ẹkọ tana fun yin lori ohun ti ile ẹjọ Kotẹmilọrun sọ nipa awọn alaga ijọba Ibilẹ ti ile ẹjọ giga ti fi ọwọ osi juwe ile fun.
"A fẹ ki gbogbo olugbe ipinlẹ Osun ati awọn to wa lẹyin odi maa mura silẹ fun idibo ijọba ibilẹ koowa wọn ni ọjọ Kejilelogun, oṣu Keji, ọdun yii.
"A jẹ orilẹ-ede ti wọn dari pẹlu ofin. Gẹgẹ bii ile ẹjọ Kotẹmilọrun ṣe sọ ni ọjọ Isẹgun, ọjọ Kẹwaa, oṣu Keji. Ẹ ma ṣe jẹ ki awọn ẹgbẹ oṣelu alatako ṣi wa lọna lori ohun ti ile ẹjọ Kotẹmilọrun ko sọ.
O tun fi kun ọrọ rẹ pe, kii ṣe ibọn tabi ada ni ohun elo idibo rara, bi ko ṣe iwe idibo ati ohun elo miran ti awọn eleto idibo ti ya silẹ fun idibo.















