Àlàyé rèé lórí bí ATM yóò ṣe máà já àlékún owó tí oníbàárà bá gbà èyí tí CBN ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé jáde

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ilé ìfowópamọ́ àpapọ̀ ní Nàìjíríà ìyẹn Central Bank of Nigeria, CBN ti mú àlékún bá iye owó táwọn ilé ìfowópamọ́ yóò máa já nígbà tí èèyàn bá gba owó lẹ́nu ATM.
Ọgọ́rùn-ún kan náírà (₦100) ni wọ́n yóò máa jà báyìí lòdì sí náírà márùndínlógójì (₦35) tí wọ́n ń jà tẹ́lẹ̀.
CBN kéde ìdarí yìí nínú ìròyìn abẹ́lé kan tí wọ́n pe àkọ́lé rẹ̀ ní 'Review Of Automated Machine Transaction Fees'.
Ní ọjọ́ Kìíní, oṣù Kẹta, ọdún 2025 ni jíjà owó náà yóò bẹ̀rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìròyìn náà ṣe sọ.
Gẹ́gẹ́ bí ìkéde náà ṣe sọ, tí èèyàn bá lo ATM ni ilé ìfowópamọ́ ti kii se tiẹ, ilé ìfowópamọ́ naa máa já ọgọ́rùn-ún kan náírà.
Bakan naa, ile ifowopamọ yoo ja owó tí iye rẹ̀ kò ní ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta náírà (₦500) tí èèyàn bá gba ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún náírà (₦20,000).
Nígbà tí èèyàn bá fẹ́ gba owó náà lẹnu ẹrọ, ATM yóò sọ iye tí wọ́n máa jà yàtọ̀ sí ọgọ́rùn-ún náírà náà.
Wo iye igba ti CBN ti fi ele kun owo ti ATM n ja lori owo onibara
CBN ní àlékún yìí ń wáyé nitori bí gbogbo nǹkan ṣe ń gbówó lórí àti láti mú àlékún bá bí àwọn maṣíìnì náà ṣe ń ṣiṣẹ́ sí.
Ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyí tí CBN yóò ṣe àtúnṣe sí owó tí ilé ìfowópamọ́ máa já fún ATM.
Ní ọdún 2014, CBN mú àlékún bá iye owó tí wọ́n ń jà lórí ATM di náírà márùndínláàádọ́rin (₦65) láti àádọ́ta náírà (₦50) tí wọ́n ń jà tẹ́lẹ̀.
Ọdún 2019 ni wọ́n mú àdínkù bá owó náà di náírà márùndínlógójì náírà (₦35) tí èèyàn bá gba owó ní ATM tí kìí ṣe ti báǹkì rẹ̀ ju ẹ̀ẹmẹta lọ láàárín oṣù kan.
Ìgbésẹ̀ CBN yìí ti ń fa awuyewuye lórí ayélujára báwọn èèyàn ṣe ń fi ẹ̀sùn kàn wọ́n pé wọ́n kàn fẹ́ máa fi ara ni àwọn ará ìlú ni.
Ìkéde CBN yìí túmọ̀ si pé kìí ṣe ìgbà tí èèyàn bá gba owó ní ẹ̀ẹmẹta ní ATM tí kìí ṣe ti ilé ìfowópamọ́ èèyàn, bó ṣe wà tẹ́lẹ̀, ni wọ́n tó máa já owó èèyàn.
Gbogbo ìgbà tí èèyàn bá ti lo ATM tí kìí ṣe ti ilé ìfowópamọ́ rẹ̀ ni wọ́n máa já ọgọ́rùn-ún náírà, tí èèyàn bá tún lo irú ATM míì, tí kò sì tún sí ní ilé ìfowópamọ́, àlékún owó míì yóò tún lé ọgọ́rùn-ún náírà náà.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Fún àwọn oníbàárà tó bá ń lo ATM tó wà ní ilé ìfowópamọ́, tó sì jẹ́ ATM ilé ìfowópamọ́ èèyàn ni, wọn kò ní já owó kankan.
Àmọ́ tí èèyàn bá lo ATM ilé ìfowópamọ́ mìíràn láti fi gba owó, ọgọ́rùn-ún náírà ni wọ́n máa jà fún iye owó tó bá ti wọ ẹgbẹ̀rún ogún náírà.
Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n máa jà ọgọ́rùn-ún náírà àti iye mìíràn fún ẹgbẹ̀rún ogún náírà nígbà tí èèyàn bá lo ATM tí kò sí nílé ìfowópamọ́.











