'Omi nìkan la mu fún ọjọ́ márùn-ún gbáko lákàtà àwọn Ajínigbé'

Ẹṣọ aabo Amọtẹkun tẹka ipinlẹ Ondo ti gba itusilẹ awọn arin-rin-ajo marun-un silẹ kuro ni akata awọn ajinigbe.
Awọn marun-un yii ni wọn jẹ arinrinajo ti wọn ko sọwọ awọn ajinigbe ni opopona Ifon-Ipele-Owo nipinlẹ Ondo lopin ọsẹ to kọja.
Ọmọbinrin kekere, ọmọ ọdun meji wa lara awọn ti wọn jigbe naa.
Amọtẹkun Ipinlẹ Ondo tun fi panpe ọba mu awọn afurasi ọdaran ogun, to fi mọ awọn ajinigbe ati awọn darandaran ti wọn fi ipa ba iya agba ẹni ọdun mẹrindinlọgọrin lopọ lasiko to n lọ oko niluu Ifira Akoko.
Ọga agba ajọ naa, Akogun Adetunji Adeleye lo sọ ọrọ yii di mimọ lasiko ti wọn n foju awọn afurasi ọdaran naa lede.

Lasiko to n ṣalaye awọn aṣeyọri ajọ naa, Adeleye sọ pe wọn doola ẹmi awọn eniyan marun-un lọwọ awọn ajinigbe lẹyin ọjọ marun-un ti wọn ti wa wọn ninu Igbo.
"Lara awọn ti a gba ni ọwọ awọn Ajinigbe yii ni ọmọ ọdun meji yii wa, ti awọn ajinigbe naa si ti lu wọn kọja ala. Sugbọn a dupẹ lọwọ Ọlọrun pe a de oriko naa ni kiakia. Awọn marun-un ti wọn jigbe naa wa ni agọ wa nibi, tí a si ko wọn jade lakata awọn ajinigbe lai si wahala kan."
Ọkan lara awọn ti wọn jigbe naa, lasiko to n ba awọn akoroyin sọrọ salaye pe, wọn ko jẹ ohunkohun fun ọjọ marun-un ti wọn fi wa lakata awọn ajinigbe naa. O sọ pe omi nikan ni awọn mu pẹlu ọmọdebinrin ọmọ ọdun meji to wa lara wọn.
O gboriyin fun Amọtẹkun fun iṣẹ takuntakun ti wọn ṣe lati ri daju pe wọn doola ẹmi wọn lọwọ awọn ajinigbe naa.
Adeleye sọ pe Gomina Lucky Aiyedatiwa ati awọn ẹṣọ aabo to ku nipinlẹ Ondo n ṣiṣẹ takuntakun lati ri daju pe awọn afunrasi ọdaran ko raye wọ awọn igbo ọba nipinlẹ Ondo.
O sọ pe bi awọn kan lara wọn ṣe rapala wọ Igbo ọba lo mu ki iṣẹlẹ ijinigbe fi n pọsi nipinlẹ Ondo.
Lara awọn ti ajọ Amọtẹkun fi oju wọn lede ni wọn jẹ afurasi ajinigbe, afurasi ole ati awọn ẹsun miiran.
Àwọn ajínigbé jí akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́ta gbé l'Ondo, bèèrè fún ₦15m

Oríṣun àwòrán, Others
Awọn Ajinigbe to ji awọn Akẹkọọ mẹta ati gbe niluu Akure ti n ṣe olu-ilu Ipinlẹ Ondo ti n beere fun millionu marundinlogun naira latọwọ awọn mọlẹbi awọn ti wọn jigbe naa.
Alukoro ileeṣẹ Ọlọpaa Ipinlẹ Ondo Funmilayo Odunlami-Omisanya lasiko ifọrọwerọ pẹlu BBC News Yoruba fidi iṣẹlẹ naa mulẹ.
Odunlami-Omisanya sọpe awọn Ajinigbe naa ti kan si mọlẹbi awọn ti wọn jigbe naa.
Alukoro naa sọ pe awọn Akẹkọọ yii lo n ṣiṣẹ ni oko to wa ni agbegbe papakọ ofurufu ilu Akure lasiko ti iṣẹlẹ naa waye.