Mount Zion tún pàdánù òṣèré míì nínú fíìmù Abbattoir lẹ́yìn Baba Gbénró

Oríṣun àwòrán, Collage
Àjálù ńlá miran tún ti waye ninu ẹgbẹ́ òṣèré tíátà Kristẹni ti Mount Zion lẹyin oṣù mẹ́ta tí Baba Gbenro kú.
Bẹẹ bá gbàgbé, Korede Are, tí ọ̀pọ̀ mọ si Baba Gbénró nínú sinima Abbattoir tí Ileesẹ Mount Zion gbẹ jáde, lo ku ninu osu kọkànlá ọdún 2024, tí wọn sì sin-in ni ipari oṣù kinni ọdun 2025.
Ìyàlẹ́nu sì lo jẹ fún ọpọlọpọ olólùfẹ́ sinima Abbattoir láti gbọ́ ni ọ̀sàn ọjọ́ Aiku pé gbajumọ osere miran nínú sinima náà, Flora, naa tún ti dagbere fáyé.

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Àlàyé rèé lórí ohun tó pa Flora
Arábìnrin Tolu Adegboyega, tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ sì Flora, lo tí wá nílé ìwòsàn tó ti ń gba itọju láti inú oṣù Kejìlá ọdún 2024.
Ijamba ọkọ ni Flora ni lopopona marosẹ Ibadan si Eko ni ọjọ kejì ọdún Kérésìmesì, èyí tó dá gunlẹ sílè ìwòsàn.
Kódà, obinrin naa pàdánù ọkàn lára àwọn ìbejì tó bí, lásìkò ijamba náà, èyí tó tún mú ẹ̀mí òun gan alára lọ.
Gbogbo aáyán ni àwọn dókítà sá láti dù ẹ̀mí Tolu Adegboyega, tó sì ṣe iṣẹ́ abẹ méjì, àmọ́ àìsàn lo ṣe wo, a ko rí tí ọlọjọ ṣe.
Inú sinima Abbattoir ni ọpọ eeyan ti mọ̀ Flora torí ipa takuntakun to ko nínú sinima náà gẹgẹ bii Asẹwo tó padà yipada, tó sì fi aye rẹ fún Jésù.

Oríṣun àwòrán, Tolu Adegboyega












