Mọ̀ nípa ohun tó ṣokùnfà ikú gbajúmọ̀ òṣèré tíátà krìstẹ́nì Korede Are ‘Baba Gbenro’

Oríṣun àwòrán, Moses Korede Are/Instagram
Iku o dọjọ, arun o doṣu, ọpọ eeyan lo ti n ṣedaro gbajumọ oṣere tiata kristẹni, Ọgbẹni Moses Korede Are ti ọpọ mọ si Baba Gbenro to doloogbe lana Ọjọru, ọjọ kẹrinla oṣu Kọkanla ọdun 2024 yii.
Iyalẹnu nla ni iku Baba Gbenro jẹ fun ọpọlọpọ eeyan nigba ti iroyin iku rẹ jade l’Ọjọbọ.
Amọ, ohun ti ọpọ eeyan ti n beere ni pe ko lo ṣokunfa iku Baba Gbenro gan an gan an bi ọpọ ko ti gbọ aisan rẹ.
Ni ile ẹkọṣẹ iṣẹgun fasiti LAUTECH niluu Ogbomoso ni Baba Gbenro dakẹ si ni aarọ Ọjọru.
Ki lo ṣokunfa iku Baba Gbenro?
Alufaa Niyi Adebayo ti ijọ True Worshippers Church niluu Ogbomoso wa lara awọn eeyan to wa nile iwosan pẹlu Baba Gbenro ki Ẹlẹmii to gba a.
Alufaa Adebayo ni awọn dokita fidi rẹ mulẹ pe arun inu ẹdọ ti oloyinbo n pe ni liver cirrhosis lo ṣokunfa iku oloogbe naa.
Ojiṣẹ Ọlọrun naa ṣalaye wi pe awọn to n tọju rẹ sọ pe arun jẹjẹrẹ ti wọ inu ẹdọ oloogbe naa.
‘’Ni nnkan bii ago mẹjọ kọja iṣẹju mẹẹdogun laarọ Ọjọru ni Ọgbẹni Are jade laye.
Arun inu ẹdọ yii lo ba a finra fun igba diẹ ti o si lọ fun itọju nile iwosan kan niluu Eko.
Lẹyin naa ni wọn tun gbe Ọgbẹni Are to jẹ dokita nipa itọju ẹranko lọ si fasiti ẹkọṣẹ iṣegun UNILORIN ki wọn to gbe e wa si ile iwosan ẹkọṣẹ iṣegun LAUTECH nibi ti o pada ku si,’’ Alufaa Adebayo ṣalaye.
Ojiṣẹ Ọlọrun naa fikun ọrọ rẹ pe awọn tiẹ gbero lati gbe Baba Gbenro lọ si India tabi Dubai fun itọju ṣugbọn awọn dokita sọ pe ko si nnkan ti wọn le ṣe si tori arun jẹjẹrẹ ti wọ inu ẹdọ rẹ.
O ni ọrọ ti oloogbe naa sọ kẹyin ni pe ‘’Ọlọrun si maa jẹ Ọlọrun, ohunkohun to wu ko ṣẹlẹ.
Alufaa Adebayo sọ pe lẹyin lo ni ‘’buọda Niyi mo fẹ sinmi,’’ o ni ko ju iṣẹju marun un lọ sigba naa lo mi kanlẹ ti o si dagbere faye.















