Ààrẹ Tinubu fi àmì ẹ̀yẹ tó ga dá Olóògbé Ọ̀gágun Lagbaja lọ́lá

Aworan bi won se n gbe Lagbaja wọ kalẹ

Oríṣun àwòrán, X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Aarẹ Bola Tinubu ti fi ami ẹyẹ to ga julọ lorilẹede Naijiria da Ọga ileeṣẹ ologun to di oloogbe, Lt Gen Taoreed Lagbaja.

Tinubu kede eyi fifi ami ẹyẹ CFR da Lagbaja lọla lasiko ti eto isinku rẹ to waye niluu Abuja.

Aarẹ ni ọkan ninu igbesẹ ti oun gbe to o dun mọ oun ninu ju ni yiyan Lagbaja gẹgẹ Ọga ologun.

Bakan naa ni aarẹ awọn ọmọ ologun lati ma jẹ ki iku Ọga wọn fa irẹwẹsi ọkan fun wọn.

“Ẹ jọwọ, ẹ ma jẹ ki iku bori wa, gẹgẹ bii olori yin, mo n fi n da yin loju lonii pe orilẹede Naijiria too tunbọ ma ṣe atilẹyin fun yin.

Eto isinku naa waye ni itẹ oku orilẹede Naijiria, to si jẹ pe oun kasẹ eto isinku ọlọjọ meji to bẹrẹ niluu Eko.

Deede ago mẹrin kọja iṣeju mọkanlelogoji ni wọn gbe Lagbaja wọ kalẹ.

Poosi oloogbe naa ni wọn we pẹlu aisa orilẹede Naijiria de si itẹ oku na ni ago mẹta.

Ọpọ awọnjh eekan lorilẹede Naijiria ati ileeṣẹ ologun lo peju sibi eto isinku naa bii Aarẹ Bola Tinubu, Igbakeji Aarẹ Kashim Shettima, Adele ọga fun ileeṣẹ ologun, Olufemi Oluyede , Minisita fun eto aabo, Abubakar Badaru ai awọn eeyan jakanjakan.

Lónìí ni Ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ ológun Nàìjíríà Taoreed Lagbaja yóò wọ káà ilẹ̀ sùn nílùú Abuja

Aworan Taoreed Lagbaja

Oríṣun àwòrán, Nigerian Army/X

Ọjọ ti a ba ku laa dere, eeyan o ṣunwọn laaye; lonii ni Ọga agba fun ileesẹ ologun Naijiria, Taoreed Lagbaja, to doloogbe yoo wọ kaa ilẹ sun.

Gbogbo eto lo ti to bayii fun isin idagbere ni gbọngan National Christian Centre niluu Abuja fun Ọgagun Lagbaja.

Oludamọran Aarẹ Bola Tinubu lori eto iroyin, Bayo Onanuga lo kede iku ọgagun naa naa ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ kẹfa oṣu Kọkanla ọdun yii.

Ọdun merindinlọgọta ni Lagbaja lo loke eepẹ, ko to jade laye.

Ọjọ kejidinlọgbọn osu Keji ọdun 1968 ni wọn bi Taoreed Lagbaja, ti aarẹ Bola Tinubu si yan sipo ọga ologun agba fun apapọ ileesẹ ologun ilẹ wa ni ọjọ kkandinlogun osu Kẹfa ọdun 2023.

Iyawo rẹ, Mariya ati ọmọ meji lo gbẹyin ọgagun Abiodun Lagbaja.