Wo iye tí aráàlù yóò máa ra epo bẹntiróòlù táwọn alágbàtà ń rà ní iléeṣẹ́ ìfọpo Dangote

Aworan ile epo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ẹgbẹ awọn alagbata epo bẹntiroolu ni Naijiria, IPMAN ti kede pe adinkun aadọta naira ni yoo baa iye ti araalu yoo maa ra epo bẹntiroolu tawọn alagbata n ra lati ileeṣẹ ifọpo rọbi Dangote to wa ni ipinlẹ Eko.

Aarẹ IPMAN, Ọgbẹni Abubabakar Maigandi lo fidi ọrọ yii mulẹ ninu ifọrọwerọ kan to ṣe lori ẹrọ amohunmaworan Channels TV.

Ọgbẹni Maigandi ṣalaye pe ileeṣẹ ifọporọbi Dangote ti gba lati maa ta jala epo bẹntirolu kan ni N940 fawọn alagbata lawọn ibudo igbepo nigba tawọn ọkọ tirela yoo maa ra a ni N990.

Aarẹ IPMAN ṣalaye pe ohun ti eleyii tumọ si ni pe awọn araalu yoo maa ri lita epo bẹntiroolu kan ra ni N1,150 lawọn ile epo ti wọn ti n ra a ni N1,200 bayii pẹlu adinku aadọta naira to maa ba iye tawọn alagbata n ta epo bẹntiroolu.

Ọgbẹni Maigandi ṣalaye pe ‘’adehun meji ni a ṣe pẹlu ileeṣẹ ifọporọbi Dangote, akọkọ ni pe a le ri epo bẹntiroolu lita kan ra ni N940 ni ibudo idọpo, ekeji si ni pe a tun le ri i ra ni N990.

Fun apẹẹrẹ, N1,200 lawọn eeyan n ra lita epo bẹntiroolu kan bayii ni Maiduguri, amọ, wọn gbọdọ maa ri i ra ni N1,15o pẹlu adinku N50 to ti ba a bayii.’’

Ṣé ìfẹnukò Dangote àti IPMAN yóò mú àdínkù bá owó bẹntiró?

Ọkọ̀ agbépo Dangote

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ẹgbẹ́ alágbàtà epo bẹntiróòlù ní Nàìjíríà ìyẹn Independent Petroleum Marketers Association of Nigeria (IPMAN) ti kéde pé àwọn ti fẹnukò pẹ̀lú iléeṣẹ́ Dangote láti máa ra epo látọ̀dọ̀ wọn taara.

Ṣaájú kí wọ́n tó fẹnukò yìí, ọwọ́ iléeṣẹ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ epo ní Nààijíríà, NNPCL ni àwọn alágbàtà epo náà ti ń ra epo Dangote.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Àmọ́ nínú oṣù Kẹwàá ni èyí wá sópin nígbà tí NNPCL ní àwọn kò ní lè tẹ̀síwájú láti máa jẹ́ alárinà láàárín ẹgbẹ́ alágbàtà epo àti Dangote.

Àtẹ̀jáde kan tí alága àwọn alágbàtà epo, Abubakar Maigandi fi síta lọ́jọ́ Ajé ní àwọn kò ní pẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí ní ra epo lọ́dọ̀ Dangote taara láì sí alárinà àti pé kí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àwọn máa múra sílẹ̀ láti ra epo náà.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí iye tí jálá epo bẹntiróòlù yoò jẹ́ nígbà tí wọ́n bá ti ń ra epo lọ́dọ̀ Dangote taara, Maigandi sọ pé kò sí pé ẹ̀ka kan ló ń sọ iye epo bẹntiróòlù mọ́ bíkòṣe bí títà àti rírà rẹ̀ bá ṣe lọ.

Ó ní òun yóò ní àjọsọ pẹ̀lú iléeṣẹ́ Dangote lórí iye tí yóò ta epo náà fún àwọn láìpẹ́ àti pé ní kété tí àwọn bá ti mọ̀ ni àwọn yóò fi tó ara ìlú létí.

“Mo ní ìgbàgbọ́ pé iye tí a máa fẹnukò sí máa dínwó sí iye tí epo bẹntiróòlù wà báyìí àti pé bẹntiróòlù yóò máa wà káàkiri, kò ní sí ọ̀wọ́n gógó epo mọ́.”

Ṣùgbọ́n kò ì tíì sí gbèdéke ọjọ́ kan báyìí táwọn alágbàtà epo náà yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní gbé epo láti iléeṣẹ́ ìfọpo Dangote.

Iléeṣẹ́ ìfọpo Dangote tó jẹ́ ti Aliko Dangote, ẹni tó lówó jùlọ nílẹ̀ Áfíríkà, nìkan ni iléeṣẹ́ tí wọ́n ti ń fọ epo rọ̀bì tó ń ṣiṣẹ́ ní Nàìjíríà lọ́wọ́ yìí.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Nàìjíríà wà lára àwọn orílẹ̀ èdè tó ń pèsè epo rọ̀bì jùlọ nílẹ̀ Áfíríkà, kò sí iléeṣẹ́ ìfọpo kankana nínú àwọn iléeṣẹ́ ìfọpo rọ̀bì mẹ́rin tí ìjọba Nàìjíríà dá sílẹ̀ tó ń ṣiṣẹ́, tó sì jẹ́ pé ilẹ̀ òkèrè ni Nàìjíríà ti máa ń kó bẹntiróòlù wọlé ṣáájú kí Dangote tó dá iléeṣẹ́ tirẹ̀ kalẹ̀.

Èyí máa ń fa ọ̀wọ́n gógó epo lọ́pọ̀ ìgbà tí iye rẹ̀ náà sì máa ń gbé ẹnu sókè nítorí owó epo rọ̀bì tó máa ń lọ sókè sódò lọ́jà àgbáyé.

Nínú oṣù Kẹwàá ni Dangote sọ̀rọ̀ pé ìjọba àpapọ̀ nílò láti dènà NNPCL àtàwọn alágbàtà epo láti dènà kíkó epo bẹntiróòlù wọlé láti òkè òkun nítorí iléeṣẹ́ ní ìkápá lái pèsè iye epo bẹntiróòlù tí Nàìjíríà nílò.

NNPCL ṣì ń jẹ wá lówó púpọ̀ – IPMAN

Alhaji Yahaya Yashima tó jẹ́ alága IPMAN ní ẹ̀ka Abuja àti Suleja sọ fún BBC Pidgin pé ìpèníjà ńlá ni owó tí àjọ Nigerian Midstream and Downstream Petroleum Regulatory Authority (NMDPRA) ń jẹ àwọn.

NMDPRA jẹ́ ẹ̀ka NNPCL, àwọn sì ni alárinà láàárín iléeṣẹ́ Dangote àtàwọn alágbàtà epo.

Yashim sọ fún BBC pé àádọ́ta sí ọgọ́ta bílíọ̀nù náírà ni NMDPRA jẹ àwọn.

Wọ́n ní owó yìí ló jẹ́ owó táwọn alágbàtà epo kan san fún NNPCL láti fi gbé epo bẹntiróòlù lásìkò tó jẹ́ wí pé NNPCL nìkan ló ní àǹfàní láti máa gbé epo láti iléeṣẹ́ Dangote.

“Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wa tó ti san owó láti fi gbé epo ni wọ́n kò ì tíì rí owó tàbí ọjà wọn gbà padà.

“A ti gbé ọ̀rọ̀ náà lọ sí ọ̀dọ̀ National Security Adviser, NSA àti DSS àmọ́ bílíọ̀nù mẹ́wàá náírà ni wọ́n buwọ́lù láti san padà fún wa, wọ́n ti san lára rẹ̀, wọn kò ì tíì san ìyókù.”

Ọmọ ẹgbẹ́ IPMAN mìíràn tó bá BBC Pidgin sọ̀rọ̀, Alhaji Yakubu Puka sọ pé èyí tí ṣàkóbá fáwọn alágbàtà epo kan.

Puka ní ọ̀pọ̀ àwọn ló jẹ́ pé wọ́n yá owó láti ilé ìfowópamọ́ lái fi ra epo lọ́dọ̀ NNPCL ni, tó sì jẹ́ pé ọ̀pọ̀ wọn ló ti ń ta dúkìá wọn láti fi san owó padà fún ilé ìfowópamọ́ nígbà tí wọn kò rí epo tí wọ́n san owó rẹ̀ gbà.”

Ó ní ó bá ń lọ báyìí ó ṣeéṣe kí ọ̀wọ́n gógó epo wà nítorí àwọn kò ní rí owó láti san owó àwọn òṣìṣẹ́ pàápàá àwọn to ń wa ọkọ̀ ńlá agbépo.