Ohun tóo ní láti mọ̀ nípa àwọn olùdíje Gomina Ondo

Aworan awon oludije sipo Gomina ipinlẹ Ondo

Oríṣun àwòrán, @LuckyAiyedatiwa, @Iwillvote Sola Ebiseni, @A_AgboolaAjayi, @Abbas Mimiko/Facebook/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Awọn araalu ati olugbe ipinlẹ Ondo ti n gbaradi fun eto idibo gomina ti yoo waye lọjọ Ṣatide.

Eto idibo yii lo n waye lẹyin oṣu mẹjọ ti Gomina tẹlẹ Rotimi Akeredolu jade laye, ti awọn araalu yoo si yan gomina mii lọjọ kẹrindinlogun oṣu kọkanla.

Ajọ eleto idibo ni eeyan 2.053,061 lo ti forukọsilẹ fun eto idibo, ti ọkunrin jẹ 1,1034,006, ti obinrin naa jẹ 1,034,964.

Awọn ọdọ jẹ 726, 944 ti wọn forukọsilẹ.

Lucky Aiyedatiwa- Ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress

Aworan Lucky Aiyedatiwa

Oríṣun àwòrán, @LuckyAiyedatiwa/X

Lucky Orimisan Aiyedatiwa ni gomina lọwọ yii. O di gomina lẹyin iku gomina Rotimi Akeredolu ni ọdun 2023.

Lucky wa lati ilu Obe-Nla ni ijọba ibilẹ Ilaje nipinlẹ Ondo. Wọn bi ni ọjọ kejila oṣu kinni ọdun 1965 ni idile Titus Akande ati iyafin Rosanah Moyebi Aiyedatiwa .

Laarin ọdun 1070 si 1976, Aiyedatiwa lọ si ile ẹkọ Sanits Pater niluu Obe-Nla/Obe Adun niluu Ilaje fun ile alakọbẹrẹ .

Bakan naa lo lọ ile ẹkọ giga Ikosi ni Ketu nipinlẹ Eko fun ile ẹkọ girama.

Aiyedatiwa tun morile ile ẹkọ giga Adeniran Ogunsanya Ijanikin ni ọdun 1986 nibi to gba oye ninu imọ iṣiro ati ijọba.

Nigba ti ija oṣelu bẹ silẹ laarin Akeredolu ati Alfred Agboola Ajayi ni ọdun 2020, Aiyedatiwa ati Akerdolu ni wọn bura wọle fun un gẹgẹ bii gomina ati igbakeji ni ọdun 202 lẹyin ti wọn bori eto idibo.

Lasiko ti Akeredolu n se aisan, Aiyedatiwa lo wa ni ipo Gomina sugbọn wọn bura fun gẹgẹ bii gomina ni oṣu kejila lẹyin iku Akeredolu.

Ninu ọrọ rẹ si awọn araalu, Aiyedatiwa ni oun yoo wa ojutu si iṣoro aabo to n ba ipinlẹ naa, ti wọn mu ilọsiwaju ba ipinlẹ nigbogbo ọna.

Agboola Ajayi- Ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratics Party

Aworan Agboola Ajayi

Oríṣun àwòrán, @A_AgboolaAjayi/x

Agboola Alfred Ajayi ni igbakeji gomina ana nipinlẹ Ondo lasiko saa akọkọ oloogbe Rotimi Akeredolu. O pada lọ darapọ mọ Zenith Labour Party lati dije ninu eto idibo gomina to kọja sugbọn o lulẹ.

Ẹni ọdun mẹrinlelaadọta ni oludije fun ẹgbẹ oṣelu PDP fun eto idibo 2024 nipinlẹ Ondo.

Wọn bi Agboola ni ọjọ kerinlelogun oṣu kẹsan an ọdun 1968 niluu Ondo, to si jẹ pe ibẹ lo ti lọ si ile ẹkọ alakọbẹrẹ ati girama.

Ni ọdun 1988, Agboola ni alaga ẹgbẹ oṣelu SDP, to si wa ninu ẹgbẹ oṣelu naa fun ogun ọdun.

Ni ọdun 2004, o wọle alaga ijọba ibilẹ Esa Odo.

Sola Ebisenu- Ẹgbẹ oṣelu Labour Party

Aworan Sola Ebiseun

Oríṣun àwòrán, @Iwillvote Sola Ebiseni/facebook

Sola Ebiseni ni oludije fun ipo Gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour Party, o sisẹ gẹgẹ bii kọmisana lasiko ijọba Gomina Olusegun Mimiko, to si wa ninu ẹgbẹ oṣelu PDP ko to morile LP

Ọjọ kinni oṣu kẹwaa ọdun 1960 ni Ebiseni nipinlẹ Ogun sugbọn Ilu Ilaje ni awọn rẹ ti wa.

Ni asiko to lo ni fasiti Naijiria niluu Nsukka, o jẹ ọkan gbogi ninu iṣejọba awọn akẹkọọ.

Ebiseni se ifẹhonuhan lori bi ileeṣẹ Channels ko ṣe gba laye lati sọrọ nibi ifọrọwerọ ti wọn se fun APC ati PDP.

Abbas Mimiko- Ẹgbẹ oṣelu Zenith Labour Party

Aworan Abbas Mimiko

Oríṣun àwòrán, @Abbas Mimiko/Facebook

Abbas Mimiko ni aburo fun gomina tẹlẹri nipinlẹ Ondo, Olusegun Mimiko.

Onimọ iṣegun naa lo bori eto idibo abẹle ninu ẹgbẹ oṣelu ZLP fun eto idibo gomina.

O ni oun ni awọn nnkan meje kan ti oun fẹ se fun ipinlẹ Ondo; Karijẹ, Karimu, Karika, Konile-lon, Kanilera ati Kalalaafia

Eyi ni gbogbo orukọ awọn oludije Gomina nipinlẹ Ondo

  • Falaiye Abraham Ajibola - A
  • Akinuli Fred Omolere - AA
  • Ajayi Adekunle Oluwaseyi - AAC
  • Nejo Adeyemi - ADC
  • Akinnodi Ayodeji Emmanuel - ADP
  • Aiyedatiwa Lucky Orimisan - APC
  • Popoolqa Olatunji Tunde - APGA
  • Ogunfeyimi Isaac Kolawole - APM
  • Fadoju Amos Babatunde - APP
  • Ebiseni Olusola Nehemiah - LP
  • Olugbemiga Omogbemi Edema - NNPP
  • Ajaunoko Funmilayo Jenyo - NRM
  • Ajayi Alfred Agboola - PDP
  • Alli Babatunde Francis - PRP
  • Akingboye Benson Bamidele - SDP
  • Adegoke Kehinde Paul - YP
  • Akinmurele John Otitoloju - YPP
  • Mimiko Olubansile Abbas - ZLP