Wo àwọn ohun tó yẹ kí o máa jẹ tí o bá fẹ́ kí ara rẹ máa dán

SKin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ti o ba fẹ ki ara rẹ maa jọlọ lọjọ ogbo, o ni lati mọ irufẹ ohun ti yoo maa wọ ẹnu rẹ lọ.

Awọn kan gbabọ pe ohun ti o ba n jẹ ni yoo ṣapejuwe bi ara rẹ yoo ṣe ri.

Eredi ree ti a fi kan si onimọ nipa ounjẹ, lati ṣe itọni nipa awọn ounjẹ ti yoo mu ara eeyan jọlọ.

Kini awọ ara?

Awọ ara ni ẹya ti o tobi julọ ninu ara ẹda.

Awọ ara yii lo maa n daabo bo gbogbo ara, oun naa lo maa n ṣodiwọn bi ara ṣe n gbona tabi tutu si.

Lara awọn nnkan to maa n sọ bi awọ ara yoo ṣe ri ni ọjọ ori, idile ti eeyan ti jade, awọn nnkan mii bii aisan itọ ṣuga ati ounjẹ ti eeyan n jẹ.

Bawo ni awọ ara rẹ ṣe le maa dan?

Ọpọ eeyan lo ni ipara to n lo amọ awọn onimọ ti sọ pe ipara to dara ju ni eyii to n wa lati inu ara nipa ounjẹ ti eeyan n jẹ.

Gbogbo igba ni awọ ara atijọ maa n bo kuro ti tuntun mii yoo si jade sita, eredi ree to fi dara lati maa jẹ awọn ounjẹ aṣara lore ti yoo maa mu awọ ara dan.

Ti eeyan ba ti n dagba, ko si ki ara rẹ ma run jọ nitori ọjọ ori amọ jijẹ ounjẹ gidi, awọn eso ati mimu omi loorekoore yoo ṣe iranlọwọ fun irufẹ ẹni bẹẹ.

Iwọnyi ni awọn ọna lati jẹ ki ara rẹ maa jọlọ

1. Maa jẹ oniruru eso lojojumọ

fruits

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn onimọ sọ pe eso jijẹ le daabo bo awọ ara lọwọ oniruru arun.

Lara awọn eso ti wọn ni ki eeyan maa jẹ lojumọ ni ọsan, ibẹpe ati bẹẹ lọ.

2. Maṣe jina si fitamin c

Orange

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Fitamin C ti a le ri lara eso ọsan wulo fun agọ ara ẹda pupọ latari bo ṣe maa n gbogun ti oniruru aisn lagọ ara wa.

3. Maa lo Fitani E ni gbogbo igba

Nuts

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Fitamin E ma n daabo bo awọ ara eeyan lọwọ awọn ohun to maa n ba a jẹ to si maa n jẹ ko tete gbo.

Lara eroja fitamin E ni eso almondi, avokado, ati eso pine.

4. Eroja Selenium

Selenium

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gẹgẹ bii ohun ti awọn ti onimọ sọ, Selenium maa n daabo bo ara lọwọ arun jẹjerẹ to n gbogun ti awọ ara.

Ibi ti o ti le ri eroja yii ni ara ẹja, tomato, ẹyin ati broccoli.

5. Maa mu omi daadaa

Water

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gẹgẹ bii ohun ti awọn onimọ sọ, mimu ife omi mẹfa si mẹjọ loojọ dara fun awọ ara ẹda.

Ti o ba n ṣiṣẹ ni ọọfisi, ri daju pe igo omi ko jina si tabili rẹ loorekoore.