Kí ni ìlépa àwọn olùdíje nínú ìdìbò ààrẹ̀ tó ń bọ̀ lọ́nà lórílẹ̀èdè Ghana?

Oríṣun àwòrán, AFP
- Author, Damian Zane
- Role, BBC News
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
Orilẹede Ghana yoo tẹ siwaju lati yan adari tuntun lasiko eto idibo apapọ to n bọ lọna lorilẹede naa loṣu kejila – igbakeji aarẹ orilẹede Ghana, Mahamudu Bawumia, ati aarẹ tẹlẹ, John Mahama, lo n lewaju laarin awọn oludije ti awọn eeyan n tka si o ṣeeṣe ko bori.
Nana Akufo-Addo, ti wọn dibo yan lati ọdun 2016 yoo pari saa keji rẹ bayii.
Nigba wo ni eto ibo apapọ yii yoo waye?
Ni ọjọ Abamẹta, ọjọ keje, nnkan bii miliọnu mejidinlogun ati ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrin awọn oludibo lorilẹede Ghana yoo maa jade lati dibo fun eto idibo apapọ kẹsan an lati igba ti eto oṣelu ọlọpọ-ẹgbẹ oṣelu ti pada de si orilẹede naa.
Nṣe ni ifigagbaga maa n le koko lawọn idibo to ti waye sẹyin laarin ọgbọn ọdun lorilẹede Ghana, amọ aarin alaafia ati ifọkan balẹ leyi ti maa n waye.
Oju rere lawọn orilẹede agbaye fi maa n wo Ghana nitori ọna irọrun ti ijọba si ijọba fi n gbe akoso iṣea fun ara wọn.
Eto idibo wo lo fẹ waye?
Ni ọjọ idibo naa, ipele meji ni idibo yoo ti waye:
Aarẹ - Oludije mejila lo wa fun eyi
Ile igbimọ aṣofin – awọn oludibo kaakiri ẹkun idibo ọrinlelugba o din marun un kaakiri orilẹede naa yoo yan awọn mọ ile igbimọ aṣofin lorilẹede apapọ naa.
Ta ni ipo Aarẹrẹ orilẹede Ghana yoo kan bayii?

Oríṣun àwòrán, AFP
Bi o tilẹ jẹ wi pe awọn oludije mejila lo n lepa ati di aarẹ lorilẹede Ghana, awọn meji lara wọn lawọn onwoye n fi oju wo pe o ṣeeṣe ki afẹfẹ ijaweolubori kan lara ninu wọn.
Lati igba ti eto oṣelu ọlọpọ ẹgbẹ oṣelu ti bẹrẹ lorilẹede Ghana lọdun 1992, awn oludije lati inu ẹgbẹ oṣelu meji kan – National Democratic Congress, (NDC) ati New Patriotic Party, (NPP) nikan lo tii bori ibo aarẹ nibẹ.
Awọn meji ti o n lewaju lati boro idibo naa niwọnyii:
- Mahamudu Bawumia (NPP) – Lẹyin to ti ṣe igbakeji aarẹ fun dun mẹjọ, bi Bawumia, ẹni ọdun mọkanlelọgọta ba le wọle, yoo fi itan lelẹ gẹgẹ bi musulumi akọkọ ti yoo di aarẹ lorilẹede naa. Bawumia ti fi igba kan ri jẹ adari banki apapọ orilẹede Ghana, bẹẹni ọpọfi oju wo o gẹgẹ bi ẹni to dantọ ninu ọrọ okoowo. Amọṣa o, nnkan le nira fun un diẹ pẹlu bi ọpọ ṣe n pariwo pe o wa ni iṣejọba labẹ eyi ti ọrọ aje orilẹede naa fi dẹnukọlẹ kọja sisọ.
- John Mahama (NDC) – bi Mahama ba bori, yoo da bi igba ti o n pada si ile agbara ni o lẹyin to ti ṣe aarẹ orilẹede naa fun saa ọdun mẹrin ati abọ tẹlẹ bẹrẹ lọdun 2012 ki o to fidirẹmi lọdun 2016. Nigba to wa nipo, Ọgbẹni Bumsor ni wọn maa n pe e gẹgẹ bi apejẹ nitori iye ina mọnamọna to n wa larọwọto araalu nigba naa. Mahama si ti ṣe ileri lati mu ayipada ba eto ọrọ aje orilẹede naa.
Awọn oludije miran tawọn eeyan tun n tẹle julọ niwọnyii:
- Nana Kwame Bediako – gbajumọ oniṣowo ni, “Cheddar” ni orukọ apejẹ ti ọpọ n pe e . ko fi bẹẹ ni atimaaṣebọ kankan lagbo oṣelu ṣugbọn ilumọọka ni laarin awọn oniroyin, o si ni atilẹyin awọn ọdọ.
- Alan Kyerematen – Minisita tẹlẹ ni, ẹgbẹ oṣelu NPP lo si wa tẹlẹ ki o to binu fi ẹgbẹ oṣelu naa silẹ lọdun 2023 lẹyin to fi apapjanu pe ojoro wa ninu ibo abẹnu ti ẹgbẹ naa ṣe lati yan oludije rẹ fun idibo aarẹ yii,. Ohun ti ọpọ si maa n pe e ni “Alan Cash”.
Ki lawọn koko ọrọ to wa nilẹ?
Ọrọ nipa eto ọrọ aje lo wa loke ohun to n mu awọn eeyan lọkan bi eto idibo naa ṣe n sun kẹrẹ wọle, paapaajulọ bi ọwọngogo nnkan ṣe n gbowo lori. Ni opin ọdun 2022, ida mẹrinlelaadọta ninu ọgọrun ni iwọn ti nnkan fi n gbowo lori lorilẹede naa. Eyi ti wa silẹ ṣugbọn owo ori awọn ọja ṣi le koko.
Banki agbaye sọ wi pe, nnkan bii ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrin o le aadọta (850,000) lawọn eeyan ti o ti wọ ọgbun iṣẹ ati oṣi lorilẹede Ghana lọdun 2022. Awọn wọnyi dara pọ mọ nnkan bii miliọnu mẹfa eeyan to wa ninu ọgbun iṣẹ nibẹ tẹlẹ.
- Bi Banki apapọ orilẹede Ghana ṣe padanu biliọnu marun un dọla lọdun kan ṣoṣo
Airiṣẹ laarin awọn ọdọ ati bi ọgọọrọ awọn ọmọ orilẹede naa ṣe n wọ jade lọ silẹ okeere lati wa igbe aye to rọrun tun kun ara awọn ohun to n jẹyọ lẹnu lọwọlọlọwọ yii.
Wahala lori ipa ti iwakusa lọna ti ko bofinmu n ko lara ayika -ohun ti wọn n pe e lorilẹede naa ni “galamsey” – eyi pẹlu ti di ohun ti ọpọ n jẹ lẹnu lorilẹede Ghana. Ọpọ iwọde lo ti waye nitori ọwọja iwakusa lọna aibofinmu yii, eyi to ti fa wahala si ayika ati oju ọjọ. Eyi si tun ti ba ọpọ omi jẹ pẹlu awọn kẹmika to n da ilu laamu.
- Lile iwakusa goolu kiri lorilẹede Ghana ti da wahala ọrọ ayika silẹ
Gbogbo awọn ẹgbẹ oṣelu to lorukọ lorilẹede naa ni wọn n sọ pe ọr naa nilo amojuto. Amọ bi ẹgbẹ oṣelu NPP ṣe n sọ pe o ṣe pataki fun ọrọ aje lati gba awọn awakusa alabọde laaye lati maa tẹsiwaju iṣẹ wọn, lẹgbẹ oṣelu NDC ni tirẹ n pe fun agbekalẹ awọn ofin to gbọngbọn sii ki wọn si gbẹsẹ le gbigba iwe aṣẹ tuntun.
Bawo ni ibo yoo ṣe lọ?

Oríṣun àwòrán, AFP
Lati le bori ipele akọkọ idibo aarẹ yii, oludije gbọdọ gba ju ilaji ibo ti awọn oludibo di. Bi ko ba si oludije kankan to ṣe eyi, atundi ibo yoo waye laarin awọn oludije meji ti ibo wọn pọ julọ ni opin oṣu kejila.
Ni ti ibo si ile igbimọ aṣofin apapọ, ẹni to ba gba ibo to pọ julọ naa ni yoojawe olubori.
Ni ọjọ idibo, ọkọọkan awọn oludibo ni yoo lọ si ibudo idibo ti orukọ wọn ba wa nibẹ ni wọn yoo ti ṣe ayẹwo wọn pẹlu ẹrọ idibo.
Lẹyin eyi wọn yoo gba kaadi idibo meji. Ni kete ti wọn ba si ti dibo tan ni wọn yoo tọ aro kiun si ọwọ wọn lati dena didibo ju igba kan ṣoṣo lọ.
Ki lo ṣẹlẹ lawọn idibo to waye sẹyin?
Lati ọdun 1992, oniruuru eto idibo aarẹ to waye lorilẹede Ghana lo jẹ wi pe tipẹtipẹ lawọn oludije gbe ẹnu le ara wọn ninu esi.
Lọdun 2008, o din ni ilaji to la awọn oludije meji laarin ni ipele keji.
Ni eto idibo eyi to waye lọdun mẹrin lẹyin rẹ,Mahama to bori ibo naa lọra kọja ida aadọta ninu ọgọrun ni ipele akọkọ idibo naa pẹlu ibo to din ni ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrin (800, 000)
Esi ibo naa fa ipẹjọ lati ẹgbẹ oṣelu NPP, to ni awọn kan ti tọwọ bọ iwe esi ibo lawọn ẹkun idibo kan. Ipẹjọ wọn fidirẹmi, amọṣa o mu ki ajọ eleto idibo lorilẹede naa gbe awọn igbesẹ tuntun jade lati mu ki ilana to mọ bi omi afowurọ pọn wọ eto idibo ilẹ naa.
Ọpọ igba lawọn alamojuto ibo lati okeere ti kan sara si bi ilana ibo ṣe n lọ nibẹ.
Nigba wo ni esi idibo yoo jade?
Pẹlu bi ọrọ ṣe lọ si lawọn idibo to ti waye sẹyin, ajọ eleto idibo yoo kede esi idibo naa titi ọjọ kẹwaa oṣu kejila ọdun 2024.
Alekun iroyin lati ọwọ Favour Nunoo ati Komla Adom ni ilu Accra












