Àìsàn ìtọ̀ ṣúgà burú si ní Naijria, àwọn aláìsàn ń ná ₦100,000 lórí oògùn lóṣù

Aworan oogun lilo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Lonii yii to jẹ ayajọ ọjọ aisan itọ ṣuga lagbaye, ọpọ ọmọ Naijiria lo n ba asisan ọhun finra.

Nilẹ Yoruba, iroyin ni nnkan bii ida marun un si meje eeyan ni aisan naa n ba finra nibẹ.

Ohun to wa buru ju bayii ni pe eeyan yoo nilo owo ti iye rẹ to ₦500,000 si ₦800,000 fun itọju ẹnikan ṣoṣo to ni arun naa, nigba ti oogun to n koju arun ọhun ti to ẹgbẹrun lọna ọgọrun naira bayii.

Awọn olutọju awọn to ni arun naa sọ fun ileeṣẹ iroyin Guardian pe owo oogun arun naa ti le si ni nnkan bii ida 300% si 400%.

Wọn ni yatọ si akitiyan ijọba lati kọ awọn ile iwosan si, o gbọdọ gbe igbesẹ lati gbogun ti awọn nnkan mimu aladun to le ṣokunfa arun naa.

Gẹgẹ bii ohun ti wọn sọ, awọn ohun mimu didun ọhun lo n ṣokunfa aisan itọ ṣuga ati ara sisan julọ lagbaye.

Awọn onimọ sọ pe ọpọ ọmọ Naijiria lo fẹran lati maa mu awọn ohun aladun to n fa aisan yii.

Bo tilẹ jẹ pe iye owo ti wọn n ra awọn ohun ẹlerindodo ni Naijiria ti wọn ju ti atijọ lọ, wọn ko dẹyin, kooda, ṣe ni wọn n ra awọn eyii ti owo rẹ kere si eyii ti wọn n ra tẹlẹ.

Idi eyii lawọn aisan bii ara asanju, aisan itọ ṣuga ati aisan ọkan ṣe gbode kan ni Naijiria.

Diabetes

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lọwọ yii, nnkan bii miliọnu mẹwaa ọmọ Naijiria lo n ba aisan itọ ṣuga finra gẹgẹ bii ohun ti awọn onimọ sọ.

Ohun to ṣeni laanu julọ nibẹ ni iye owo oogun fun itọju awọn aisan naa ti gbowo lori.

Iwadii fi han pe o kere tan, awọn alaisan itọ ṣuga n na nnkan bii ẹgbẹrun lọna ọgọrun naira lori aisa ọhun loṣu.

Lọwọ yii, iye owo abẹrẹ ‘insulin’ wa laarin ₦18,000 si ₦21,000, amọ ₦3,500 ni wọn n ta abẹrẹ naa tẹlẹ.

Awọn oogun mii bii ‘flexpen’ ti wọn n ta ni ₦6,500 tẹlẹ ti di ₦20,000 lonii