Irọ́ ńlá ni pe Ilé-ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn fagilé Olusola Ebiseni gẹ́gẹ́ bíi olùdíje ẹgbẹ́ wa - Alaga LP l'Ondo

Oríṣun àwòrán, Olusola Ebiseni
Alaga ẹgbẹ Oṣelu LP l'Ondo, Họnọrebu Remilekun Ojo, ti sọ pe idajọ Ileẹjọ kotemilọrun eyi to kede pe Sola Ebiseni ko lẹtọọ lati dije dupo gomina ninu eto idibo gomina lọjọ Abamẹta jẹ iyalẹnu nla fun ẹgbẹ naa.
Arabinrin Ojo sọ fun BBC Yoruba n'ilu Akure pe Ọgbẹni Ebiseni ni ojulowo oludije ẹgbẹ naa ti yoo si gbe asia ẹgbẹ ohun ninu eto idibo sipo Gomina lọjọ Satide ọsẹ yi.
Ninu ọrọ rẹ ni o ti sọ pe Ọgbẹni Ebiseni ṣe ohun gbogbo ni ilana pẹlu ofin ẹgbẹ naa to si san ogun milionu naira lati gba fọọmu ti alaga egbe naa lorileede Naijiria si bọwọlu fọọmu naa.
Ki lo fa awuyewuye to ti ń jẹ yọ nínú ẹgbẹ náà nípa ẹni tó jẹ́ ojúlówó Olùdíje?
Alaga ẹgbẹ́ naa ṣalaye pe "ko to di pe a ṣe idibo abẹle, ẹni tó jẹ igbakeji alaga ẹgbẹ wa lorileede yi Ayo Festus Olorunfemi fi ara rẹ ji lati se Adele oludije, ó sì sọ fun mi pe ni kete ti a ba ti rí ojulowo oludije ohun yo yẹ ba fun ẹni naa nitoripe ohun ko lowo lati du ipo Gomina.
"Igba to to akoko Ọlọ́run dari Sola Ebiseni si wa, ó si lọ si ilu Abuja lati gba fọọmu ogun Millionu naira ti Alaga egbe wá lorileede yii si bọwọlu fọọmu naa ti wọn si kede Sola Ebiseni gẹgẹ bi ọmọ oye ninu eto idibo to n bọ."
"Ẹni to jẹ Adele tẹlẹ Ayọ Olorunfemi lọ Ileẹjọ to si kọwe pe ohun yẹ ba fun ojulowo oludije ti n se Sola Ebiseni, Oludije naa si fun Olorunfemi ni Millionu marun-un naira, bẹẹni Alaga ẹgbẹ wa lorileede yi tun fun ni Millionu meji naira.
" Ni kete ti a se gbogbo igbese yii, Ajọ INEC kọ lati fi orukọ Ebiseni lede gẹgẹ bi ojulowo oludije, eyi to mu ki O gba Ileẹjọ lọ, Ileẹjọ giga si pasẹ fun INEC lati fi orukọ Ebiseni lede ti wọn si ni Olorunfemi ko lẹtọ lati dije labẹ ẹgbẹ LP nitoripe o ti bọwọ luwe saaju.
Alaga naa sọ siwaju si pe " iyalẹnu nla lo jẹ fun wa ni owurọ oni nigbati a gbọ pe Olorunfemi lọ Ileẹjọ kotemilọrun lati sọ pe Sola Ebiseni kọ ni oludije ẹgbẹ wa."
Arabinrin Ojo sọ pe irọ nla ni pe Ileẹjọ kede pe Sola Ebiseni ko lẹtọ lati dije labẹ ẹgbẹ naa, O sọ pe Ebiseni ni gbogbo ẹgbẹ mọ gẹgẹ bi oludije ohun ni yoo si gbe asia ẹgbẹ lọjọ Satide.
Olusola Ebiseni sọ̀rọ̀ lórí ìdájọ́ iléẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tó fagilé orúkọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi olùdíje ẹgbẹ́ LP fún ìbò gómìnà Ondo

Oríṣun àwòrán, Olusola Ebiseni/X
Awuyewuye si n tẹsiwaju lori ẹni to jẹ ojulowo oludije sipo gomina fẹgbẹ oṣelu Labour Party ninu eto idibo ọjọ ti yoo waye lọtunla ọjọ Abamẹta ti i ṣe ọjọ kẹrindinlogun oṣu Kọkanla nipinlẹ Ondo.
Ni irọlẹ ana ni ile ẹjọ kotẹmilọrun niluu Abuja wọgile, Amofin Olusola Ebiseni, gẹgẹ bii oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu LP.
Igbimọ onidajọọ mẹta eyi ti Adajọ Adebukola Banjoko ka idajọ wọn fontẹ lu ẹjọ kotẹmilọrun ti ẹgbẹ LP pe tako Amofin Egbeseni atawọn meji mii.
Adajọ Banjoko sọ pe ileẹjọ yoo fi ẹda iwe idajọ naa ṣọwọ si gbogbo awọn ti ọrọ naa kan.
Ṣaaju ni adajọ Emeka Nwite ti ile ẹjọ giga ilu Abuja ti paṣẹ pe ki ajọ eleto idibo INEC ri Amofin Ebisei ati Ọgbẹni Ezekiel Awude gẹgẹ bi oludije sipo gomina ati igbakeji rẹ fun eto idibo gomina ipinlẹ Ondo ọjọ Abamẹta.
Adajọ ni Ebiseni ati Awude lo jawe olubori ninu eto idibo abẹnu ti ẹgbẹ oṣelu LP ṣe.
Ebiseni sọ pe oun si ni oludije sipo gomina fẹgbẹ LP
Amọ, nigba to n ba BBC Yoruba lori idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun l’Abuja, Ebiseni, sọ pe oun si ni oludije ẹgbẹ oṣelu LP ninu eto idibo ọjọ Abamẹta.
‘’Ko si nnkan to n jẹ bẹẹ, ẹ ba ni ki ẹni to sọ bẹẹ mu iwe idajọ naa wa.
Gẹgẹ bi amofin, o yẹ ki ẹnikẹni to ba sọ pe wọn da oun lare fi iwe idajọ naa han yin gẹgẹ bi ẹri.
Emi ni ile ẹjọ kọkọ da lare bi oludije fẹgbẹ oṣelu LP, lẹyin iyẹn lawọn kan sọ pe idajọ ileẹjọ naa ko tẹ awọn lọrun.
Nigba to di ana Ọjọru ni wọn tun sọ pe ile ẹjọ kotẹmilọrun ti da awọn lare.
Amọ, ibeere to yẹ ki awọn eeyan beere ni iwe idajọ naa,’’ Ebiseni lo sọ bẹẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post















