Generator Ban: Àbá ọ̀hún wá yọ àwọn ilé ìwòsàn, pápákọ̀ òfurufú àti àkànṣe iṣẹ́ míì sílẹ̀

Oríṣun àwòrán, Others
Ile asofin agba ilẹ wa ti n se agbeyẹwo aba kan, ti yoo fofin de lilo ẹrọ amunawa jẹnẹratọ lorilẹede Naijiria.
Aba naa, ti Sẹnatọ Bima Enagi to n soju ẹkun idibo guusu ipinlẹ Niger gbe wa siwaju ile, ti wọn si ti ka fun igba akọkọ, lo tun n daba ijiya ẹwọn ọdun mẹwa fun ẹni to ba gbe jẹnẹratọ wọ Naijiria wa tabi to ba n ta a.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Agbófinró, tó bá wa ọkada àbí kẹkẹ maruwa l'Eko, o rugi oyin - Sanwo-Olu
- Ará Yúróòpù ẹ fìdí mọ́lé yín, mo ti gbé ìlẹ̀kùn Amẹ́ríkà tìpa torí Coronavirus - Trump
- Ìjọba ń ṣe afárá Eko Bridge l'Eko, àwọn ọ̀nà àbùdá tí ẹ lèè gbà nìyí
- Gómìnà ìpínlẹ̀ Kaduna, El-Rufai fi ipò míì dá Sanusi lọ́lá
- Ganduje fún Aminu Ado Bayero ní ìwé ìyannisípò gẹ́gẹ́ bí Emir ìlú Kano
Bakan naa ni aba ọhun n kesi awọn araalu pe ki wọn dẹkun lilo ẹrọ amunawa naa eyi to n lo epo disu, pẹtiro abi ebo eebo karosini lọgan lorilẹede Naijiria.
Amọ aba naa wa yọ igbesẹ lilo ẹrọ amunawa fun awọn akanse isẹ to se koko silẹ, ninu eyi ta ti ri ipese iwosan isegun lawọn ile iwosan, papakọ ofurufu ati awọn oju irin reluwe.

Oríṣun àwòrán, Others
Lara awọn akanse isẹ to tun se koko ti wọn daba pe a le lo ẹrọ amunawa fun ni ẹrọ to n gbe ni lọ soke, wa si isalẹ taa mọ si ẹlifetọ, awọn ileesẹ iwadi ati awọn ipese isẹ miran to n waye nisẹ-isẹju lai dawọ duro.
Amọ sa, aba naa ni awọn eeyan to n se akansẹ isẹ pataki wọnyi gbọdọ gba asẹ lọdọ minisita fọrọ ohun amusagbara, ki wọn to lee lo ẹrọ amunawa naa.
Lọwọ lowọ bayii, ipese ina ọba lorilẹede Naijiria lo n se segesege, ti awọn ọmọ Naijiria si n gbara le ipese ina ọba lati ara awọn ẹrọ amunawa, eyi ti wọn n na owo gege le lori lati fi ra epo sinu wọn.









