Cancer center: Ọdún 38 ni ìyá mí fi ṣiṣẹ́ ní UCH, màá kọ́ ibùdó ìtọ́jú àrùn jẹjẹrẹ ní ìrántí rẹ - Ọọ̀ni

ooni ile ife

Oríṣun àwòrán, Ooni

Àkọlé àwòrán, Ọdún 38 ni ìyá mí fi ṣiṣẹ́ ní UCH, màá kọ́ ibùdó ìtọ́jú àrùn jẹjẹrẹ ní ìrántí rẹ - Ọọ̀ni
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Ọọni tilu Ile Ifẹ, ọba Enitan Adeyeye Ogunwusi, Ọjaja keji ti seleri lati kọ ibudo itọju awọn

alarun jẹjẹrẹ sile iwosan nla UCH nilu Ibadan.Ọba Ogunwusi seleri bẹẹ lasiko to n gbalejo awọn ọmọ igbimọ alasẹ ile iwosan naa,

ti onisegun agba, Ọjọgbọn Jesse Abiodun Otegbayo ko sodi wa si aafin rẹ.Ọọni salaye pe ọdun mejidinlogoji ni iya oun, Wuraola Ogunwusi fi ṣiṣẹ nile iwosan UCH,

ti iṣẹ takuntakun to ṣe nibẹ ko si parẹ titi di oni.

"Laipẹ laijinna ni maa kọ ibudo itọju awọn alarun jẹjẹrẹ, ti wọn yoo ti maa gba itọju kímò,

maa si pe orukọ ibudo naa ni Wuraola Chemotherapy Cancer Centre, lati ma ṣe jẹ ki orukọ iya mi parẹ."

Oni Ife

Oríṣun àwòrán, Ooni

Àkọlé àwòrán, Ọdún 38 ni ìyá mí fi ṣiṣẹ́ ní UCH, màá kọ́ ibùdó ìtọ́jú àrùn jẹjẹrẹ ní ìrántí rẹ - Ọọ̀ni

Arole Oodua tun woye pe gẹgẹ bii ojulowo ọmọ Yoruba ọpọ egboogi ibilẹ lo wa fun iwosan arun Coronavirus

atawọn aisan asekupani miran eyi to yẹ ka tẹwọ gba fun itọju awọn alaisan naa pẹlu oogun oyinbo." Awọn Ọjọgbọn lorisirisi ti pejọ si fasiti Afe Babalola nilu Ado Ekiti lati ṣe ẹkunrẹrẹ iwadii lori awọn ewe ati egbo to le wo awọn aisan asekupani

bíi Coronavirus, awọka, aromọleegun, arun jẹjẹrẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ, ti wọn yoo si jẹ kijọba

apapọ ati ajọ Nafdac mọ nipa bi awọn oogun ibilẹ naa yoo ti wulo si ati ipese wọn.

"O wa dupẹ pupọ lọwọ igbimọ alasẹ ile iwosan UCH fun abẹwo wọn, eyi to jọ oun loju lasiko Coronavirus yii.

Ọọni, Aláàfin, Ojisẹ Ọlọ́run àti oniṣẹ ìwádìí fi Ògún gbari pé òògùn ìbílẹ̀ le wo Covid-19

Madagascar herbal cure: Ọọni, Aláàfin, Ojisẹ Ọlọ́run àti oniṣẹ ìwádìí fi Ògún gbari pé òògùn ìbílẹ̀ le wo Covid-19

ooni ile ife

Oríṣun àwòrán, ooni adeyeye ogunwusi

Laipẹ yìí ni Minisita fún ètò ìlera ní Nàìjíríà, Dókítà Osagie Ehanire kéde pé, ìjọba kò tako àmúlò òògùn ìbílẹ̀ fún ìwòsàn àrùn Coronavirus.Arun aṣekú pani ọ̀hún, sì ni abiku rẹ ti sọ àwọn oníṣègùn jákèjádò àgbáyé di èké, tí wọn si ni àwọn ko ri ìwòsàn fún ajakalẹ-arun Covid-19 náà.Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé, àwọn ibi taa fi ojú si lagbaye lórí wíwà ìwòsàn fún àrùn yìí, ọna kò gba ibẹ lọ, lo mú ki awọn ọmọ ilẹ̀ Áfíríkà kan dìde láti wá ìwòsàn pẹ̀lú oògùn ìbílẹ̀.

Orílẹ̀ èdè Áfíríkà bíi Madagascar Cameroon àti Nàìjíríà sì ti ń fi ogun rẹ gbari pé, àwọn òògùn ìbílẹ̀ kan leè wo àrùn Coronavirus, tí Madagascar sì ti ń lo òògùn ìbílẹ̀ tiẹ̀ fún ìwòsàn àrùn náà.

Ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, àwọn ọba alaye bíi Ọọni tilu Ilé-Ifẹ̀, Ọba Adeyeye Enitan Ogunwusi, Ọjaja Kejì àti Aláàfin tilu Ọ̀yọ́, Ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi Kẹta, to fi mọ ojisẹ Ọlọ́run bíi Fada Anselm Adodo àti oniṣẹ ìwádìí Isegun bíi Ọjọgbọn Maurice Iwu, lo fi ọwọ gba àyà pé, òògùn ìbílẹ̀ yóò ṣe ìwòsàn àrùn Coronavirus.

line

Ọọni ti Ilé-Ifẹ̀, ọba Adeyeye Ogunwusi

Àkọlé fídíò, Wo bí o ṣe leè ṣe ìjìnàsíraẹni ní ibiṣẹ́ lásìkò Coronavirus yìí

Arole Oodua, ọba Ogunwusi kéde síta Laipẹ yìí pé òun ti ṣe àwárí ìwòsàn fún àrùn Coronavirus.

Bẹẹ si ni ninu fídíò kan tó gbé sójú òpó Facebook rẹ, ní ọba Ogunwusi tí ń ṣe àfihàn àwọn egboogi ìbílẹ̀ kan tó lè wo àrùn Coronavirus san, àti bí àwọn èèyàn ṣe leè lo.

Fídíò náà sì ni àwọn ènìyàn tó lè ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta wò, tí àwọn bíi ẹgbẹjọ si ṣe alábàápín rẹ.

Skip Facebook post, 1

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post, 1

Ọọni ni "Mo ti dán àwọn òògùn ìbílẹ̀ náà wò, mo ti lo fún alárùn Coronavirus kan, tí wọn sì ni ajẹbiidan ni òògùn ìbílẹ̀ náà."

Ọba alaye náà wá ń rọ àwọn oniṣẹ ìwádìí ni Nàìjíríà àti ní àgbáyé, láti fi àmúlò oogun ìbílẹ̀ yìí mọ Isegun òyìnbó.

line

Aláàfin ti Ọ̀yọ́, Ọba Lamidi Adeyemi

Ọba Adeyemi, lásìkò to ń ṣe ifilọlẹ ìwé kan tí ẹnikan kọ nípa Ayinla Ọmọwúrà, kéde pé òògùn ìbílẹ̀ wa dáadáa tó lè wo ajakalẹ-arun Coronavirus, èyí tó ti sẹ orunkun àwùjọ àgbáyé.

Alaafin ni àwọn òògùn ìbílẹ̀ wà dáadáa láyé àtijọ́, tó ń wo àwọn àrùn bíi ìgbóná tàbí Sanponna àti atọgbẹ, tí àwọn oníṣègùn ìbílẹ̀ náà sì ní agbára láti fi ohùn lásán ransẹ sì ẹni tó wà nílẹ òkèèrè, tí ohun tí wọn ba sọ, yóò sì máa ṣẹ lójú ẹsẹ.

Àkọlé fídíò, Niyi Akinmolayan tó ṣe fíìmu àwòrán-dèèyàn Cartoon nípa COVID-19 tó la ayé já ní N

"Kò sí àìsàn tàbí àrùn ni orílẹ̀ ayé tí àwọn baba wa kò leè wòsàn, mo sì mọ pe àwọn agbára náà sì wà síbẹ̀ títí di òní."

Fadá Anselm Adodo

Ojisẹ Ọlọ́run kan nínú ìjọ Kátólíìkì, tíì tún ṣe olùdarí fún ilé ìwòsàn ìbílẹ̀ nipinlẹ Edo, Fadá Anselm Adodo tí fi ìkéde kan síta lójú òpó Facebook rẹ, ní Ọjọ́bọ, ọjọ́ Kokandinlogbon oṣù kẹrin ọdún 2020 pé, ibùdó ayẹwo òun ti gbé òògùn ìbílẹ̀ kan jáde, tó le wo àrùn Covid-19.

Fada Anselm ni òògùn ìbílẹ̀ náà lo dára julọ fún ìwòsàn àrùn Coronavirus, tá sì tún leè pèsè òògùn naa ni irọrun ni abẹle, ká sì pín kàkàkí.

O ni èròjà CVD PLUS tó wà nínú rẹ lo ń gbógun ti àwọn kòkòrò àrùn tí a kò leè fojú rí, tó sì tún ń mú agbega bá àwọn ọlọ́pàá tó ń dáàbò bo ara, èyí tó lè ṣe iranwọ láti bá àwọn àrùn to jọ mọ Coronavirus ja.

"Mo ti gbé oogun náà fún àjọ Nafdac, tí wọn si ni àwọn yóò ṣe ìwádìí oogun náà bo ṣe pegede si."

Ọjọgbọn Maurice Iwu

Ọjọgbọn kan nilẹ Nàìjíríà, Maurice Iwu tí kéde ni osu kejì ọdún pé òun ti ṣe àwárí òògùn tó lè wo àrùn Coronavirus.

ooni pẹlu awọn eekan ijọba

Oríṣun àwòrán, ooni adeyeye ogunwusi

Iwu ni òun ti sepade pẹ̀lú Minisita fún imọ ṣayẹnsi àti iṣẹ ẹ̀rọ pẹ̀lú Minisita feto ìlera láti sọ fún wọn pé, òun ti rí àwọn egbògi kan tó leè ṣe ìwòsàn fún arun Coronavirus tàbí arun-karun tó bá ń ṣe idiwọ fún mimi jalẹ.

"Méjì nínú èròjà mẹta tí mo rí náà, wá lara awon èròjà tí àjọ Nafdac tí fi ọwọ si ṣáájú, pé ó dára fún lilo àwọn èèyàn."

Maurice Iwu ni àwọn ewéko náà tí òun ṣe àwárí wọn náà, ní àwọn ọmọ ilẹ̀ China tí lo fún ìwòsàn àrùn Coronavirus yìí kan náà.

Coronavirus in Lagos: Ayẹwò kò dáwọ́ dúro botílẹ̀ jẹ́ pé èròjà ayẹwò (Reagents) kò si mọ́- Kọmísọ́nà ìròyìn

èròjà ayewo

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán, Ayẹwò kò dáwọ́ dúro botílẹ̀ jẹ́ pé èròjà ayẹwò (Reagents) kò si mọ́

Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ni ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ènìyàn ni àwọn n ṣe àyẹ̀wò coronavirus fún lójoojúmọ lójúnà àti mú àdínkù bá ìtànkálẹ̀ ààrùn coronavirus.

Kọmísọ́nà fún ètò ìròyìn ni ìpínlẹ̀ Eko Gbenga Omotsho ló sọ eyí lásìkò to n ba BBC News Yoruba sọ̀rọ̀.

Sáájú ní ọjọ́ ajé ni gómìnà ìpínlẹ̀ Eko Babajide Sawnwo-Olu ti kéde pé èròjà èlò ti wọ́n fi n ṣe àyẹwò ààrùn Coronavirus ko si ni ìkáwọ́ àwọn mọ́ àti pé, o tó ènìyàn ẹgbẹ̀run mẹ́ta tó wà nilẹ̀ bayìí ti kò si bi wọ́n a ṣe ṣe àyẹ̀wò fún wọ́n

Àkọlé fídíò, Wo bí o ṣe leè ṣe ìjìnàsíraẹni ní ibiṣẹ́ lásìkò Coronavirus yìí

Ìdí nìyí ti BBC ṣe wádìí lọ́wọ́ kọmísọna, lórí ìgbésẹ̀ ti ìjọba n gbé ti ọ̀rọ̀ ààrùn Coronavirus kò ṣe ni bẹ́yìn yọ ni ìpínlẹ̀ Eko.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ Gbenga Omotosho ní, báyìí ìpínlẹ̀ Eko ti ranṣẹ́ si gbogbo àwọn to n tàá èròjà àyẹ̀wò náà tàbi to lé rìí, láti kan si ijọba, o ní gbogbo àwọn orilẹ̀-èdè ti o ṣeese ki wọ́n ni náà ni ìjọba ti kan si.

O rọ gbogbo àwọn ti wọ́n n ta àwọn ǹkan wọ́n yìí láti maa rò pé àsìkò láti pawó rẹpẹtẹ rèé.

"Ọdún yìí kii ṣe ọdun ti ènìyàn n wá èrèọjà rẹpẹtẹ bíko ṣe, asíkò láti wà láàlafíà." kọmísọ́nà lo sọ bẹ́ẹ̀

O ní bi kò ṣe si èròjà àyẹwò yìí, eyi ko dá àyẹwò dúró, sùgbọ́n ka ni a wà lọ́pọ̀ ni ayẹwò ko ba jù bẹ́ẹ̀ lọ.

Kọmísọ́nà túnn rọ gbogbo ará ilú láti móju to àwọn àfin ti ìjọba là silẹ̀, kí àwọn ènìyàn maa lo ìbomu wọ́n , ki wọ́n máa fọ́wọ́ déédé àti pé o ṣe pàtàkì ki wọ́n sa fun ìpéjọpọ̀ àwọn ènìuyàn tó pọ̀.

Agbófinró, tó bá wa ọkada àbí kẹkẹ maruwa l'Eko, o rugi oyin - Sanwo-Olu

Lagos Okada ban: Ìjọba Eko ní òun yóò pèsè ọkọ ti yoo rọpo ọkada ati kẹkẹ láìpẹ́

Agbofinro to n gun ọkada

Oríṣun àwòrán, Others

Ijọba ipinlẹ Eko ti sọ pe agbofinro kankan ti ọwọ ba tẹ pe o n ṣe ọkada tabi wa kẹkẹ maruwa yoo foju wina ofin.

Ikilọ yii lo waye nibi ipade to waye nile ijọba ipinlẹ naa ni Marina, leyi ti Gomina Babajide Sanwo-Olu sẹ alaga rẹ.

Ijọba naa ni o lodi si ofin fun ẹnikẹni to jẹ agbofinro, yala ọlọpaa ni tabi ọmọ ologun lati maa ṣe iṣẹ okada tabi wa kẹkẹ ẹlẹsẹ mẹta lawọn agbegbe ti ijọba ti fofin de.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Kọmiṣọna fun ọrọ to n lọ, Gbenga Omotoso sọ fun awọnn oniroyin lẹyin ipade naa pe, ijọba Eko ko ni fọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ naa lọna ati le ọkada ati kẹkẹ maruwa jinna rere si awọn agbegbe ti wọn ti fofin de wọn.

O ni, o jẹ ohun to ba ijọba ninu jẹ pe awọn agbofinro lo n ru ofin ti ijọba gbe kalẹ lori ọkada ati kẹkẹ maruwa nipinlẹ ọhun.

Okada ti Sanwo-Olu gbẹsẹ le

Oríṣun àwòrán, Others

Omotoso ṣalaye pe, awọn eleto abo lee wa alupupu wọn lawọn ibi ti wọn ti fofin de ti wọn ba wa ninu aṣọ iṣẹ nikan, kii ṣe ki wọn maa lo aṣọ ara lati gbe ero nitori wọn jẹ ọlọpaa tabi ọmọ ologun.

O ni "A ti ṣagbeyẹwo ofin to de kẹkẹ maruwa ati ọkada, agbofinro to ba wọ aṣọ iṣẹ to si n wa alupupu rẹ nikan la gba laaye lati lo lawọn ibi ti a fofin de."

Omotoso tẹ siwaju pe "Agbofinro ti ọwọ ba tẹ pe o n ṣe iṣẹ ọkada tabi wa kẹkẹ ẹlẹsẹ mẹta lawọn ibi ti a ti fofin de, yoo foju wina ofin."

Kọmiṣọna naa ni ijọba ipinlẹ Eko ko ni yi ipinnu rẹ pada lori bo ṣe fofin de ọkada ati kẹkẹ maruwa ni ipinlẹ ọhun, ṣugbọn o sọ pe "Titi Oṣu Kẹrin ọdun, ijọba yoo pese awọn ọkọ ti yoo rọpo ọkada ati kẹkẹ ẹlẹsẹ mẹta."

Nipa afara Eko to di titi pa, o ni igbesẹ naa ṣe pataki nitori ọna ati daabo bo ẹmi awọn to n gba ori afara naa, ati pe, ijọba n ṣeṣẹ takuntakun lati mu aye dẹrun fun awọn eeyan ipinlẹ naa.

Ọjọ kinni, Oṣu Keji ọdun 2020 ni ijọba ipinlẹ Eko labẹ iṣakoso Gomina Babajide Sanwo-Olu gbẹsẹle ọkada ati kẹkẹ maruwa lawọn ijọba ibilẹ kan, leyi ti inu ọpọ awọn olugbe ipinlẹ naa ko dun si.

Àkọlé fídíò, Stolen phone: Fóònù mi ni mo lọ́ tún ṣe lọlọ́pàá bá he mí pé mo jí fóònù