#MeToo movement: Harvey Weinstein tó fi ipá bá àwọn ènìyàn lòpò ti rí ẹ̀wọ̀n ọdún 23 he!

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gbajugbaja oṣere ti wọn ti dojuti fun iwa ibajẹ, Harvey Weinstein ti ri ẹwọn ọdun mẹtalelogun he fun ẹsun ifipabanilopọ ati wi wu iwa aitọ si obinrin.
Ile ejọ giga ni ilu New York ni adajọ ti ni Harvey Weinstein jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an, eleyii to jẹ ki idojutini rẹ peleke si.Eré bọ́ọ̀lù, ìpàdé ìta gbangba àtàwọn nǹkan míì tó di àpatì torí Coronavirus
Ori aga ti awọn ti wọn ba n ṣe aisan ma n joko si ni Weinstein ẹni ọdun mẹtalelaadọrin ọun lo wa si ile ẹjọ naa.
Awọn agbẹjọro Weinstein ti tọrọ aforiji fun, to bẹ ti wọn fi sọ wi pe ẹwọn ọdun marun un fun un dabi ẹwọn gbere ni.
Amọ awọn agbẹjọrọ to fi ẹsun kan an sọ wi pe ẹwọn gbere lo tọ si i fun iya ati gbogbo iwa aitọ to wu si awọn obinrin, ti ko si ronupiwaa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọjọru ni Weistein fun igba akọkọ ba awọn oniroyin sọrọ, to si ni inu oun bajẹ fun gbogbo aṣiṣe ti oun ṣe, amọ ko i tii ye oun gbogbo bi iṣẹlẹ naa ṣe ṣẹlẹ.
Ọpọlọpọ obinrin lo ti wa si gbagba ǹi awọn oju opo ikansiraẹni pẹlu #MeToo movement lati ọdun 2017, lati tu asiri gbogbo bi Harvey Weinstein ṣe n fipa ba awọn obinrin lopọ.
Ọpọ igba lo ti sọ wi pe oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun,amọ ẹsun naa gbe de ilẹ ẹjọ ni ibi to ti ri ẹwọn he.












