Equality; Ẹ wo ọ̀nà márùn ùn tí ọ̀kùnrin ṣì ń jẹ gàba lé obìnrìn lórí

obìnrìn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbayé, UN ti kéde ọ̀nà mọ́rùn ún tí orílẹ̀èdè Naijiria ṣì ń rẹ̀yìn nípa ìdọ́gba láàrín ọkùnrin àti obìnrín.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ajọ Iṣọkan Agbaye, UN ti fi lede pe ida aadọrun iye awọn eniyan lagbaye ni wọn ṣi n ṣe idẹyẹsi fun awọn obinrin lagbaye.

Bio tilẹ jẹpe obinrin ati awọn ọmọdebirnrin lo jẹ apa kan ti a ba da iye awọn eniyan to wa lagbaye si meji, ti wọn si ni awọn ohun ribiribi ti wọn le e gbeṣe naa.

Lorilẹede Naijiria ti awọn obinrin jẹ ida mọkandinlaadọta iye awọn eniyan to wa lorilẹede Naijiria, amọ wọn kọ lati faramọ pipe fun idọgba laarin ọkunrin ati obinrin.

Ẹ wọ ọna marun un ti wọn ṣi n gba lati dẹyẹ si awọn obinrin ni Naijiria

Ẹtọ gẹgẹ bi ọmọ orilẹede Naijiria:

Ẹka iwe ofin Naijiria ti ọdun 1999, ti ẹka Section 26 (2) (a) fi agbara fun obinrin ti o ba fẹ ọmọ Naijiria, amọ ko fun okunrin lati orilẹede miran to ba fẹ ọmọbinrin Naijiria ni ẹto lati jẹ ọmọ bibi orilẹede Naijiria.

Awọn ajafẹtọ ti fi igbe ta pe idẹyẹsi ni lati ma ṣe ofin kan naa to rọmọ igbeyawo fun ọkunrin ati ọbinrin kan naa.

Awọn obinrin ti ofin naa ti dẹyẹ si sọ wi pe ofin orilẹede Naijiria n fi wọn ṣe ẹru lorilẹede wọn.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Amọ, Aṣojusofin, Akin Alabi ti fi abadofin sita ni ile igbimọ asọjusofin lorilẹede Naijiria ti yoo fi opin si ofin naa.

Gbigbe ọmọde ni iyawo:

Ajọ to n risi ọrọ awọn ogo wẹẹrẹ lagbaye, UNICEF ti ni orilẹede Naijiria jẹ kan lara awọn orilẹede to gba laaye ki awọn awọn ọkunrin fi ọmọdebinrin ti ko ba ti i pe ẹni ọdun mejidinlogun ni iyawo.

Ofin orilẹede Naijiria, ẹka Section 29 (4) (b) ti ọdun 1999 fi lede wi pe obinrin ti wọn ba ti gbe ni iyawo ti da agbalagba niyẹn.

An ti wọn buwọlu ofin yii sọ wi pe ẹsin musulumi ko sọ iye ọjọ ori to yẹ ki obinrin jẹ ko to le ṣe igbeyawo.

Eyi tun mọ si wi pe nigba ti awọn ọmọkunrin ba n lọ si ile iwe ti wọn si n ṣe oun ti yoo mu ọjọ iwaju wọn dara, obinrin lo lẹtọ lati ṣe iṣẹ ile tabi ki wọn fi fun ọkọ, ki wọn ba le ri owo fi seun to tọ ni ile.

Ọdun 2003 ni wọn ṣe ofin to kọ ifiyajẹ ọmọde, ninu eyi to tako fi fi ọmọbinrin ti ko ba ti i pe ọdun mejidinlogun fun ọkọ.Amọ, ipinlẹ mọkanla ni iha ariwa orilẹede Niajiria ni ko i tii sọ di ofin.

Ipo opo:

Awọn agbeegbe kan lorilẹede Naijiria ri awọn obinrin gẹgẹ bi ẹru ọkọ rẹ nitori naa ni ọkunrin fi le e ṣe iyawo rẹ bi o ba ti ṣe wu u. Ti ọkọ obinrin ba ku, iyawo rẹ ni wọn ma a kọkọ fun ra si pe o pa ọkọ rẹ, ti yoo si ṣe awọn ibura to fihan wi pe ko ni ọwọ ninu iku ọkọ rẹ.

Ni awọn iha miran, awọn ọkunrin ile naa yoo fi ipa ba opo naa lopo ti yoo si fa irun ori rẹ.

Gbigba ile gbigbe:

A ti gba ile ni orilẹede Naijiria lera fun awọn obinrin ti ko ba ti i lọkọ tabi ni afẹsọna nitori awọn onile a kọ lati fun wọn ni ile gbe nitori wọn ko ni ọkọ.

Ọpọlọpọ awọn onile lori wọn gẹgẹ bi ẹni ti ko nilari nitori wọn ko lade lori, ti o si ṣeeṣe ki wọn ma le e naa owo ile lasiko.

Wọn gbagbọ wi pe ile obi obinrin lo yẹ ki o ma a gbe titi yoo fi fẹ ọkọ. Eleyii yatọ si bi wọn ṣe n ṣe si awọn ọkunrin.

Ifetosọmọbibi:

Idẹyẹ si gẹgẹ bi obinrin ni wọn ti fihan wi pe oun ṣe akoba fun ifeto si ọmọ bibi lorilẹede Naijiria. Eyi ko fun awọn obinrin ni anfaani lati le ṣe oun ti o wu wọn lori ifetosi ọmọ bibi ni ọna igbalode.

Iwadii fihan pe ida mẹtala ninu awọn ọmọbinrin ẹni mẹẹ̀dogun si mọkandinlaatọta ni oun lo ifetosọmọbibi bayii lorilẹede Naijiria.

Alaga Ajọ Isọkan Agbaye (UN), Antonio Guterres ti ni idẹyẹ si awọn obinrin lawujọ gbogbo jẹ ohun itiju fun tọmọde ti agba ni awujọ, ti awọn eniyan si gbọdọ pawọpọ lati fi opin si.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Bakan naa lo fikun pe ọpọlọpọ idanilọyẹ ṣi ku lati ṣe lati gbogun ti idẹyẹsi fun awọn obinrin ni awujọ.