Lagos Budget Downward review: Ṣé àdínkù yóò ba owó oṣù òṣìṣẹ́ ìpínlẹ̀ Eko lásìkò yìí?

Gomina ati igbimo alase

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán, Lagos Budget Downward review: Ṣé àdínkù yóò ba owó oṣù òṣìṣẹ́ ìpínlẹ̀ Eko lásìkò yìí
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Àwọn aláṣẹ ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ti buwọ́lu mímú àdínkù bá ìṣúná owó oní tírílọ́ọ̀nù kan lé díẹ̀ ti ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Eko ti búwọ́lu tẹ̀lè fún ọdún 2020.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ kọmísọ́nà fún ìṣúnà àti ètò ìlú Sam Egube ní lẹ́yìn tí ilé ìgbìmọ̀ ti buwọ́lu àdínkù yìí ni gómínà Babajide Sanwo-Olu náà tún jàn-án lóntẹ̀.

Egube ní kò sí ǹkan tó fá èyí ju pé owó epo rọ̀ọ̀bì to ti já wálẹ̀ kúrò ní bó ṣe wà tẹ́lẹ̀ lágbàyé, tí èyí sì ti mú àdínkù bá owó tó ń wọlé láti ọ̀dọ̀ ìjọbá àpapọ, nítorí náà ìṣùná tó wà nílẹ̀ kò lé bá ìpinu ìjọba mu mọ́.

Awọn ǹkan míràn tún ni pé àwọn ọja tí gbówó lórí sí i tí ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ajé sì ti dẹnu kọlẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ilé iṣẹ́ o le pèsè ǹkan ti wọ́n ń pèsè mọ, gbogbo ẹ̀ka tí tí n ri owó wọle tí ń dínkù lójoojúmọ́.

Kíní ìtumọ̀ èyí fún àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ìpínlẹ̀ Eko.

Ọ̀pọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ló ti wà ní inú fu, àyà fu nítori ìgbésẹ̀ ìjọba yìí, ti ìbéèrè sì gbòde pé ṣé owó oṣu òṣìṣẹ́ kò ni faragbá nínú ọ̀rọ̀ yìí báyìí?

Sùgbọ́n gẹ́gẹ́ bi kọmísọ́nà fún ètò ìròyìn Gbenga Omotosho ṣe sọ lásìkò tó n bá BBC Yoruba sọ̀rọ̀, ó ní ọ̀rọ̀ náà kò kan àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba tábi ohunkóhun to ba níṣe pẹ̀lú owó ìná gbogbo ìgbà.

Ó ní àwọn owó àwọn iṣẹ́ àkànṣe tí ìjọba nílọ́kàn láti ṣe ni yóò faragbá nínú ọ̀rọ̀ náà àti pé lábẹ́ àkóso bótiwù kórí, àwọn iṣẹ́ àkànṣe to níṣe pẹ̀lú ètò ìlera tàbi ètò ẹ̀kọ́ gan-an yóò ṣì wà bóṣe wà tẹ́lẹ̀.

Omotosho ní, owó òṣìṣẹ́ ìjọba wà lára àwọn owó ìná gbogbo igba, àwọn olóṣèlú àti àwọn owó míràn to ṣe pàtàkì fún ará ilú yóò ṣì wà bóṣe wà tẹ́lẹ̀.

" Ọ̀rọ̀ náà dàbí ti ènìyàn bá fẹ́ kọ́ ilé alájà mẹ́rìn tẹ́lẹ̀, to wá padà dinkù sí ilé alájà mẹ́jì ni. Kò sí ǹkan ti yóò yàtọ̀ nínú ìṣùná owó, kò kàn ni fẹ́jú tó bó ṣe yẹ kó wà tẹ́lẹ̀ ni.

Kíni àwọn onímọ̀ ètò ọ̀rọ̀ ajé sọ lórí ikékúrú owó ìṣúná ìpínlẹ̀ Eko

Àlàyé onímọ nípa ìtúpalẹ̀ ètò ọ̀rọ̀ ajé àwùjọ Muda Yusuf sàlàyé pé, ìjọba to bá gbé irú ìgbésẹ̀ tí ìjọba ìpínlẹ̀ Eko gbé yìí túmọ̀ si pé, ó ni ìwòye ọjọ́ iwájú.

Yusuf ní tí ìjọba bá ṣetan láti ṣiṣẹ́, ó ṣeẹṣe láti gé àwọn ǹkan ti kò wúlò kúrò nínú ètò ìṣúná owó láti jẹ́ ki àwọn ará ilú jànfàní ètò ìjọba àwa ara wa.

Ó ní àlébù kan ṣoṣo to wà nínú ọ̀rọ̀ náà ni pé, o ṣeéṣe ki ìjọba máa ṣe iṣẹ́ àkànṣe kankan to mányán lórí fún ọdún 2020.

O ní tí ọ̀rọ̀ bá ri báyìí kò dẹrùn láti fọ́wọ́ kan àwọn ètò ìṣùnà owó tó n wáye nígbà gbogbo bí owó oṣù òṣìṣẹ́ tábi èyí ti wọ́n ń lò láti tẹ iṣẹ́ ìjọba síwájú.

Lánà'òde yìí ní ìjọba ìpínlẹ̀ Eko kéde pé àwọn yóò mú adínkù bá ìṣúna owó ọdún 2020 nítori àjálù ààrùn Coronavirus

Ìpínlẹ̀ Kano náà ti ṣe irú ikéde yìí ni ńkan bi oṣẹ̀ méji sẹ́yìn, ti ìjọba apapọ náà sì ti gbé igbésẹ̀ yìí sáájú àkókò yìí.

Okada Ban: Wo àwọn àdugbò tí òfin tuntun náà to yọ silẹ̀

Okada
Àkọlé àwòrán, Okada Ban: ọjọ kini oṣù keji ni òfin tuńtun yóò bẹ̀rẹ̀

Ní ọsàn ni ni ìjọba ìpínlẹ Eko kéde pé òun ti ṣetan láti ko gbogbo àwọn ọkada ati kẹkẹ Maruwa ní àwọn ìjọba ìbilẹ kọkàn ni ìpínlẹ̀ Eko.

Ijọba ni awọn opópóna máròsẹ, awọn afára àti àdúgbò kan nilu Eko ni àwọn ti i fi òfin de ọkada, kẹké Napep, to fi mọ Gokada àti Opay.

Ìjọba ni òfin náà yóò bẹrẹ ni pẹrẹwu ni ọjọ kíní oṣù keji ọdun yìí.

Èyí wáye nínú àtẹjade ti akọwe ipolong fun Gomina ìpínlẹ Eko Babajide Sanwo-Olu lori itàkun ayelujara Goyega Akosile loni ọjọ aje

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Lara awọn ìjọba ìbilẹ mẹẹdogun àti ẹka ijọba ibilẹ ti ọ̀rọ̀ náà kan ni

oruko awon adugbo

Oríṣun àwòrán, Gawati/twitter

Àkọlé àwòrán, Okada Ban: Wo àwọn àdugbò tí òfin tuntun náà to yọ silẹ̀
oruko awon adugbo

Oríṣun àwòrán, Gawati/twitter

Àkọlé àwòrán, Okada Ban: Wo àwọn àdugbò tí òfin tuntun náà to yọ silẹ̀
Oruko adugbo

Oríṣun àwòrán, Gawati/twitter

Àkọlé àwòrán, Okada Ban: Wo àwọn àdugbò tí òfin tuntun náà to yọ silẹ̀