Maryam Sanda: Àdájọ́ ní kí wọ́n yẹgi fun títí tí ẹ̀mí yóò fi bọ́ lára rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Others
Maryam Sanda, ìyàwó tó pa ọkọ rẹ, ri ìdájọ ikú he Ileẹjọ giga kan to kalẹ si opopona Aguiyi Ironsi ladugbo Maitama nilu Abuja ti gbe idajọ kalẹ lonii pe iku lo tọ si iyawo kan to sekupa ọkọ rẹ, Maryam Sanda.
Maryam yii ni wọn lo fi ọbẹ gun ọkọ rẹ, Bilyaminu Bello, eyi to ran sọrun ọsan gangan lọdun 2017.
Fidio ree lori bi Maryam Sanda se foju ba ileẹjọ:
Bi o tilẹ jẹ pe Maryam sọ pe oun ko mọwọ mẹsẹ lori ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan oun naa, sibẹ o papa foju ba ileẹjọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ẹ wo bí Amotekun ṣe gba ilẹ̀ Yoruba silẹ̀ lọ́wọ́ agbéṣùnmọ̀ní ní igba ọdún sẹ́yìn
- Ọ̀daràn tó bá ta féle-fèle yóò bọ́ sọ́wọ́ Amọtẹkun - Ìjọ́ba Ekiti
- Agbábọ́ọ́lù alápẹ̀rẹ̀, Kobe Bryant àti ọmọ rẹ̀ dèrò ọ̀run nínú ìjàmbá ọkọ̀ òfurufú
- Àwọn àpọ́n ọmọ Yorùbá olówó Marun tí kò tíì laya
- Kò dín ní ọkùnrin márùndínlógún tó ń bá mi lò lójúmọ́
Maryam ati ibatan rẹ kan, iya ati alabasisẹpọ rẹ kan si ni wọn fi ẹsun kan pe wọn ba ẹri to daju jẹ, eyi to lee fidi rẹ mulẹ pe Maryam jẹbi ẹsun ti wọn fi kan.

Oríṣun àwòrán, Others
Lẹyin atotonu agbẹjọro fun ijọba ati igun olujẹjọ, ni adajọ kede pe Maryam jẹbi ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan, to si ni ki wọn lọ yẹgi fun titi ti ẹmi yoo fi bọ ni ẹnu rẹ.
Maryam, iya rẹ ati awọn ẹbi yoku to wa nile ẹjọ si lo mu igbe bọnu ni kete ti adajọ naa gbe idajọ rẹ kalẹ.










