Coronavirus: Dókítà òyìnbó sọ ọ̀nà ta le gbà láti bọ́ lọ́wọ́ àrùn aṣekúpani náà

Ile iwosan ti wọn ti n tọju alarun Corona Virus

Oríṣun àwòrán, Others

Onimọ nipa ajakalẹ aarun, Ọjọgbọn Akin Osibogun ti ni oun ti orilẹede Naijiria nilo ni adari to yanju, lati kapa aarun Corona virus to ba wọ orilẹede Naijiria.

Ọjọgbọn Osibogun lo salaye bẹẹ lasiko to n ba BBC News Yoruba sọrọ lori igbaradi awọn eleto ilera lati kapa aarun Corona Virus to n ja rain nilẹ China, ti o si ti tan de orilẹede Ivory Coast ni ilẹ Afrika, ilẹ Yuroopu, Amẹrika ati Canada to fi mọ Ilẹ Gẹẹsi.

Baalu to balẹ si Abidjan, Ivory Coast

Oríṣun àwòrán, EPA

Osibogun ni ijọba Naijiria ti bẹrẹ si ni ṣe igbaradi fun ọna lati gbogun ti aarun naa, aibaamọ ẹnikẹni lee gbe e wọ orilẹede Naijiria.

Lara awọn amin ti a fi lee tete se idamọ aarun naa ni ikọ, ki eniyan ba sin ati inira lati mi jalẹ.

Kini igbaradi orilẹede Naijiria lati koju arun Corona Virus?

  • Ọjọgbọn Akin Osibogun salaye awọn eto ti ijọba ti pese sile lati koju aarun Corona Virus ti o ba wọ Naijiria. Lara rẹ ni:
  • Sisẹ pọ pẹlu Ajọ eleto Ilẹra Lagbaye, WHO lati mọ ibi ti aisan naa de duro ati wi pe ṣe o le de orilẹẹde Naijiria
  • Ijọba ti pese awọn gbọngan to n ṣe ayẹwọ ara fun ẹnikẹni to ba fi ami han bi ẹni pe o ni arun Corona virus naa.
  • Wọn ti pese awọn oṣisẹ si papakọ ofurufu, ibudokọ oju omi ati awọn ibode Naijiria lati le ma a ṣe akiyesi awọn eniyan to ba n wole tabi jade ni Naijiria.
  • Ayẹwo finifini n lọ lọwọ fun ọkọ ofurufu ti o ba n bọ lati ẹkun Ila Oorun ilẹ Asia.
  • Ẹni ti wọn ba ṣe akiyesi rẹ, wọn yoo mu u lọ si ile ibi ti wọn n fi awn aniyan si fun ayẹwo pipe fun ọsẹ bi meji si mẹta.

Ọna wo ni awọn eniyan le fi gbogun ti ajakalẹ aarun Coronavirus fun ra wọn?

Ọjọgbọn Osibogun ti ni inu afẹfẹ ni aisan Corona Virus n gba lati tan kalẹ nitori naa lo ṣe parọwa si awọn eniyan lati ri pe wọn ṣe awọn akiyesi wọn yii:

  • Ẹ ṣọra fun agbeegbe ti awọn eniyan ba pọsi julọ
  • Ti ẹ ba n wukọ, e bo ẹnu yin
  • Ti ẹ ba n sin, ẹ ma jẹ ki omi ara yin kan si ori ibi ti ẹlomiran ti le fi ara ko.
  • Ẹ fọwọ bo ẹnu lati igba de igba.
  • Ẹ ma a san ọwọ yin lati igba de igba lati dena aarun.
  • Ti o ba ri ẹni to n fi awọn amin wọn yii han ni agbeegbe rẹ, yara lọ si ile iwosan tabi ijọba ibilẹ ti o sun mọ ọ lati filọ.

Ọjọgbọn Ọsibogun ti ni bi o tilẹ jẹ pe awọn eleto iwosan wa ni sẹpẹ lati dena arun yii, o pọn dandan lati la awọn eniyan lọyẹ lati mọ ọna lati dena arun yii ati awọn ami ti o ma n ṣe afihan rẹ.

Bakan naa ni o parọwa wi pe ki awọn eniyan laju silẹ daadaa, ki wọn ṣe akiyesi eniyan to wa ni ẹgbẹ wọn, amọ ki wọn ma ṣe sa fun ara wọn, nitori o le wu, ti ko ba si itọju lasiko.

Bawo ni ile China ṣe n koju aarun Corona Virus?

Orílẹ̀èdè China ni àrùn Corona virus ti bẹ̀rẹ̀, tí ó sí ti pa ẹ̀nìyàn mọ́kànlélọ́gọ́rín láti bí oṣù kan tí ó ti bẹ̀rẹ̀ sí ní jà.

Map of coronavirus cases in China

Agbeegbe Wuhan ti iṣẹlẹ naa ti bẹrẹ, ki o to tan ka lọ si agbeegbe Hubei ti wa ni titi pa lọwọlọwọ bayii, ti o le ni eniyan ẹgbẹ̀run mẹta ti o ti bẹrẹ aisan latari aarun naa.

Ijọba ilẹ naa si ti polongo ọjọ̀ meta kun asiko isinmi ti wọn wa ki aisan naa ma ba tan kalẹ ju bo ṣe wa lọ.

Lorilẹede Shangai bakan naa, ijọba ti kọ fun awn oṣiṣẹ lati ma ṣe pada lọ si ẹnu iṣẹ tit di Ọjọ Kẹwa, Osu Keji, ọdun yii.

Wuhan

Oríṣun àwòrán, Gov.cn

Amọ Ajọ WHO ko i tii kede aisan naa gẹgẹ bi ajakalẹ aarun kaakiri agbaye.

Bawo ni aisan naa ṣe ri ni awọn ilẹ Okeere?

A map showing the spread of disease worldwide, as of 27/01/2019
  • Eniyan mẹjọ ni Thailand
  • Eniyan marun un ni orilẹede Amerika ati Australia
  • Awọn mẹrin ni Singapore, Taiwan, Malaysia ati South Korea
  • Eniyan mẹta ni ilẹ Faranse ati ilẹ Japan
  • Eniyan meji ni Vietnam
  • Eniyan kan ni Nepal ati Canada