Algon Oyo: Àwọn ọlọ́pàá ẹnu ọ̀nà káńṣù náà ṣetán láti wọ́n eṣinṣin tó bá ta fírí

Ijọba ibilẹ

Oríṣun àwòrán, Others

Olu ileeṣẹ ijọba ibilẹ Ariwa Ibadan, Ibadan North, to n bẹ ni agbegbe Agodi-Gate n'Ibadan, naa jẹ ọkan lara awọn ijọba ibilẹ ti awọn oṣiṣẹ ko ti ni anfani lati wa si ẹnu iṣẹ lonii.

Gboin-gboin ni ẹnu iloro ijọba ibilẹ naa wa ni titi pa lasiko ti ikọ BBC Yoruba se abẹwo sibẹ.

Wamu-wamu si ni awọn agbofinro duro sibẹ, ti esinsin ba si ta firi nibẹ, wọn yoo wọn ni.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọkan lara awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ naa, to ni ki a fi orukọ bo oun laṣiri ṣalaye wi pe, lati opin ọṣẹ ti o kọja ni awọn alakoso ijọba ibilẹ naa ti ranṣẹ si awọn oṣiṣẹ wọn.

Ẹnu ọna abawọle sijọba ibilẹ Ariwa Ibadan to wa ni titipa

Awọn lo si wi pe ki onikaluku osisẹ joko sile lonii titi di ọjọ miran, jọ re, nipasẹ iroyin to n ja rainrain wi pe awọn alaga ibilẹ tẹlẹri ninu ẹgbẹ oṣelu APC ipinlẹ Ọyọ, ti n gbero lati pada sẹnu iṣẹ wọn lonii.

Saaju ni agbẹjọro agba lorilẹede yii, Abubakar Malami ranṣẹ si gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Ṣeyi Makinde lati da awọn alaga ibilẹ tẹlẹri naa pada sẹnu iṣẹ wọn, ti Makinde si fesi wi pe agbẹjọro agba orilẹede yii ko lẹtọ lati fi ọwọ lalẹ nipinlẹ Ọyọ.

Tẹ bá da omi àlááfíà ìpínlẹ̀ Ọyọ rú, ẹ rugi oyin - Ìjọba Ọyọ sọ fáwọn alaga àná

Ijọba ipinlẹ Ọyọ ti fesi si awuyewuye ọrọ to n ja rain-rain nilẹ pe o seese ki alaafia ma jọba lawọn ibujoko ijọba ibilẹ to wa jake jado ipinlẹ naa loni ọjọ Aje.

Ijọba ibilẹ

Oríṣun àwòrán, Others

Atẹjade kan ti akọwe iroyin fun gomina Seyi Makinde, Taiwo Adisa fisita kede pe eyikeyi alaga ibilẹ ana labẹ ijọ ẹgbẹ oselu APC, ti ọwọ ba tẹ pe o n da omi alaafia ilu ru, ni yoo jo palongo labẹ ofin.

Bakan naa ni atẹjade naa fikun pe, ijọba Ọyọ yoo se agbeyẹwo ofin ọdun 1999, ti yoo si mu lo gẹgẹ bo se kan awọn alaga ijọba ibilẹ mejidinlaadọrin ti wọn juwe ọna ile fun nijooni.

Atẹjade naa ni eyi se pataki nitori bi awọn alaga ijọba ibilẹ naa se n dunkooko kiri pe awọn yoo gba akoso awọn kansu lonii ati bi ẹgbẹ awọn osisẹ ijọba ibilẹ Nulge se ni kawọn ọmọ ẹgbẹ rẹ joko sile.

Àkọlé fídíò, Imoyosola Adetoro: Àwọn èèyàn sọ fún ìyàwó mi pé mo ti jẹ́ẹ̀jẹ́ nínú awo pé ń kò ní bímọ

Adisa ni bi o tilẹ jẹ pe ijọba ko ni foju laifi wo ẹgbẹ Nulge pe o niu kawọn osisẹ rẹ joko sile nitori ibẹru ohun to lee sẹlẹ, amọ o rọ awọn osisẹ ijọba nipinlẹ Ọyọ lati kẹyin si idunkooko lati ibikibi pẹlu erongba lati da eto isejọba ru nipinlẹ naa.

A ti gbé ìlẹ̀kùn ìjọba ìbílẹ̀ tìpa láti dẹ́kun wàhálà l'Ọyọ - Àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ìbílẹ̀

Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde

O ti n rugbo bọ lori awuyewuye to n waye nipa ta lo tọ lati dari awọn ijọba ibilẹ nipinlẹ Ọyọ, ti ko si sẹni to mọ ibi ti igi ọrọ yoo wo si loni ọjọ Aje.

Oniruuru awọn iroyin ti ko fẹsẹ mulẹ lo ti n gba ori awọn ikanni ayelujara kan pe o seese ki awọn ijọba ibilẹ tijọba ana bura fun wọle pada sẹnu isẹ lonii.

Bẹẹba gbagbe, ni kete ti ijọba gomina Seyi Makinde gba ijọba lo pasẹ pe ki awọn alaga ijọba ibilẹ naa, ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ oselu alatako APC, lọ rọọkun nile na, to si yan awọn alaga afunsọ rọpo wọn.

Ami idamọ ẹgbẹ osisẹ nijọba ibilẹ

Oríṣun àwòrán, Nulge

Lọsẹ to kọja la gbọ pe Agbẹjọro agba ni Naijiria, Abubakar Malami fiwe ransẹ si ijọba ipinlẹ Ọyọ pe ko fawọn alaga ijọba ibilẹ latinu ẹgbẹ APC ọhun laaye lati maa ba isẹ wọn lọ, eyi ti iroyin gbalẹ kan pe wọn yoo wọ isẹ lonii.

Sugbọn lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ, akọwe iroyin si gomina Seyi Makinde, Taiwo Adisa ni ko si ohun to jẹ otitọ ninu iroyin naa nitori ijọba Ọyọ ko ri iwe kankan gba lati ọdọ Malami.

Abiola Ajimobi

Oríṣun àwòrán, Abiola Ajimobi

Lọwọ-lọwọ bayii, nitori wahala to seese ko bẹ silẹ loni nidi emi ni adari ijọba ibilẹ, iwọ kọ,laarin awọn alaga afunsọ ati alaga latinu ẹgbẹ APC, ẹgbẹ awọn osisẹ si ti faake kọri pe wọn yoo gbe ẹnu ọna awọn ileesẹ ijọba ibilẹ jakejado ipinlẹ Ọyọ tipa.

Atẹjade ti ẹgbẹ Nulge fisita

Oríṣun àwòrán, Nulge

Ninu atẹjade kan ti wọn fisita lọjọ Ẹti, ẹgbẹ awọn osisẹ nijọba ibilẹ, NULGE, ẹka tipinlẹ Ọyọ salaye pe lẹyin ipade igbimọ alasẹ ẹgbẹ naa ni awọn fẹnuko lati gbe ilẹkun awsn ijọba ibilẹ ti pa bẹrẹ lati sjọ Aje, titi di ọjọ miran, ọjọ ree.

Ẹgbẹ Nulge ni erongba awọn lati gbe igbesẹ yii ni lati ri pe alaafia jọba lawọn ijọba ibilẹ to wa nipinlẹ Ọyọ, ti ko si si rogbodiyan kankan rara.