Lassa fever outbreak: Ìpínlẹ̀ Ondo, Edo àti Ebonyi ni ibà Lassa ti ń ṣọṣẹ́ jùlọ

Oríṣun àwòrán, @NCDCgov
Ajọ to n mojuto ajakalẹ arun lorilẹede Naijiria, NCDC ti kede pe eeyan mọkandinlogun lo ti di alaisi lori ajakalẹ arun iba Lassa to tun ṣẹṣẹ gbilẹ lawọn ipinlẹ kan lorilẹede Naijiria.
Ipinlẹ mọkanla lo ni arun iba Lassa ti tan kalẹ de lorilẹede Naijiria ti wọn si ti ri igba o din marun un eeyan ti ọwọ aarun naa si ti ba.
Ninu atẹjade kan, ti ọga agba ajọ naa, Dokita Chikwe Ihekweazu fi sita, ipinlẹ Ondo, Edo ati Ebonyi ni ọwọja arun yii pọ si julọ.
- 'Ẹ yé mu gaàrí mọ́, tẹ́ẹ̀ bá fẹ́ lùgbàdì ibà Lassa'
- Mọ̀ síi nípa ǹkan tí o lè ṣe láti dènà ibà Lassa
- Ààrùn ‘Coronavirus’: Ẹ yé rìnrìn àjò lọ sí ìlú Wuhan mọ́
- Yaba Left: Àṣírí tú! #7000 sí #10000 ni owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ fún bẹẹdi ní ilé àwọn aláìsàn ọpọlọ
- Ìjọba Ondo ṣetán láti san #30,000 gẹ́gẹ́ bí owó oṣù òṣìṣẹ́ tó kéré jùlọ
- Oko Oloyun: Ta ló pa Àlhájì Fataì Yusuf?
- Fífẹ́ ju ìyàwó kan lọ ló mú ìṣẹ́ àti ìfàsẹ́yìn ba àpá àríwá Nàìjíríà- Lamido Sanusi
- Ṣé Coronavirus leè tẹ̀lé ọjà Chinco wọ Nàìjíríà? Ìdáhún àtàwọn ìbéèrè míì
- Ile Arugbo: A ò yánjú ọ̀rọ̀ láàrin ara wa, a ò fẹ́ ilé ẹjọ́ mọ́. - Ìdíle Saraki, ìjọba Kwara
O ni ida mọkandinlaadọrun iye awọn ti o ti ko aarun naa ni wọn wa lati ipinlẹ mẹta yii.
Ẹ lee maa wo pe ki lo n fa a ti arun yii tun fi pada wa ni iru akoko bayii? Ajọ NCDC ni bi oju ọjọ ati ayika ṣe ri lasiko yii lo faa ati pe ajs naa n sa gbogbo ipa to yẹ lati kapa rẹ.
Ajọ naa ṣalaye pe ọpọ awọn oṣiṣẹ ni wọn ti fi ṣọwọ sawọn ipinlẹ marun un to n fara ko arun ọhun ni lọwọlọwọ.
Amọṣa, ajọ naa ni adinku ti ba iye ẹmi to ba aisan yii lọ bi a ba wo o ni ifẹgbẹ kẹgbẹ pẹlu ọwọja rẹ lasiko yii kan naa ni ọdun 2019.
Ida mẹtalelogun awọn eeyan to ko aisan iba Lassa lọdun 2019 lo baa lọ sọrun alakeji, ṣugbọn lọdun yii nkọ, ida mẹrinla awọn to ko aisan naa ni wọn jade laye.
Oludari agba Ajọ to n mojuto ajakalẹ arun lorilẹede Naijiria, naa ni ibudo ayẹwo marun ọtọọtọ lo wa lorilẹede Naijiria nibiti wọn ti lee ṣayẹwo iba Lassa.













