Ile Arugbo: Ìdíle Saraki àti ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara dájọ́ ìpàdé

Aworan Bukola Saraki ati Abdulrahman Abdulrazaq

Lẹyin ti ijọba ipinlẹ Kwara ti tẹle ofin ti wọn wo ohun ini idile Saraki eyi ti wn n pe ibẹ ni Ile Arugbo ni ilu Ilorin, ipinlẹ Kwara, gbogbo awọn tọrọ kan ninu rẹ ti wa gba lati yanju aawọ lai ti ọwọ ile ẹjọ bọ ọ mọ.

Lasiko igbẹjọ naa ni ile ẹjọ giga ti ipinlẹ Kwara lọjọ ẹti ọsẹ yii, awọn agbẹjọro fun awọn ọlọrọ mejeeji sọ fun adajọ Abiodun Adewara pe awọn ti jọ gba lati yanju ọrọ lai wa si ile ẹjọ.

Bakan naa ni wọn fi ipade si ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kinni ọdun yii lori ọna ati wa ojutuu si ohun to wa nilẹ.

Àkọlé fídíò, Ìjọba AbdulRazaq ti wólé aláànúú wa ní Ilorin

Eyi lo mu ki Adajọ Adewara gboriyin fun igun mejeji to si ki wọn fun akitiyan wọn lati pinnu pe awọn fẹ yanju aawọ lai wo ohun to ti ṣẹlẹ tẹlẹ.

Nitori naa, adajọ sun ijoko siwaju di ọjọ keji oṣu kẹta ọdun 2020 lati gbọ abọ iyanju aawọ naa.

Bi ẹ ko ba gbagbe, jọ keji oṣu kinni ọdun yii ni ijọba ipinlẹ Kwara fi awọn ọkọ katakata wo ile Arugbo eyi ti wọn ni oloogbe Oluṣola Saraki to jẹ baba Sẹnetọ Bukola Saraki kọ sori ilẹ ti wọn ni o yẹ ki ijọba ipinlẹ Kwara lasiko rẹ fi kọ ileeṣẹ ijọba.

Àkọlé fídíò, Mercy Aigbe, Lateef Adedimeji, Ayoola Ayolola kó sọ́wọ́ ìbéèrè kàbìtì, ó di gbọin!!!

Lori eyi, idile Saraki gbe ijọba ipinlẹ Kwara labẹ akoso gomina AbdulRahman AbdulRazaq lọ sile ẹjọ lẹyin ti wọn wo ile naa palẹ.

Ẹwẹ, adajọ Adewara gba wọn niyanju lati gba alafia laye ki wọn si jiroro lati pẹtu si aawn to n suyọ lori ile ti wọn wo.

Eyi si lo mu ki idile Saraki pe fun ipade lati yanju rẹ pẹlu ijọba ipinlẹ Kwara lai ti ọwọ ofin bọ ọrọ naa mọ.