Amotekun: Àwọn gómìnà ìpínlẹ́ ẹkùn ilẹ̀ Yorùbá yoó ṣì ṣèpàdé pẹ̀lúu Ààrẹ Buhari lórí 'Àmọ̀tẹ́kùn'

Oríṣun àwòrán, Tolu ogunlesi
Ọrọ taa ni ki baba o maa gbọ, baba ni yoo pari rẹ ni ọrọ Amọtẹkun tun kan bayii gẹgẹ bii alaga ajọ awọn gomina ẹkun ilẹ Yoruba, Gomina Rotimi Akeredolu ṣe sọ.
Akeredolu ni awọn yoo ṣi ṣe ipade pẹlu Aarẹ Muhammadu Buhari lori awọn awuyewuye to n waye ati agbekalẹ eto ikọ alaabo ilẹ Yoruba ti wọn pe ni 'Amọtẹkun'.
Akeredolu to jẹ gomina ipinlẹ Ondo ṣalaye pe irinajo aarẹ si ilẹ Gẹẹsi lo jẹ ki wọn sun ipade naa, bibẹẹkọ, ọsẹ to kọja lọ ni o yẹ ko ti waye.
- Wo àwọn òṣèré tó bímọ s'Amẹrika lọ́dún 2019 kí Trump tó f'òfin dèé
- Wo iye ibùdó ìtójú ibà Lassa tó wà ní Nàìjíríà
- Oko Oloyun: Ta ló pa Àlhájì Fataì Yusuf?
- Kí ni ètò òfin tó kàn fún Àmọ̀tẹ́kùn láti dúró?
- Ẹyin ni wọ́n fi n gba ìbále ẹlòmiran lára wa ki a to lọ pàde àwọn oníbara
- Ṣé Coronavirus leè tẹ̀lé ọjà Chinco wọ Nàìjíríà? Ìdáhún àtàwọn ìbéèrè míì
O fi kun un pe ipade ti awọn ṣe pẹlu Igbakeji aarẹ, Yẹmi oṣinbajo ko ṣaadede waye o. O ni aarẹ Buhari gan gan lawọn kọwe si lati ri ki aarẹ to wi pe oun n lọ si ilẹ okeere lati ṣe awọn ohun kan tabi meji, ṣugbọn ki oun ma baa fi ti oun da wọn duro lo fi ni ki awọn gomina ilẹ Yoruba ọhun lọ ṣepade pẹlu igbakeji oun.
Gomina Akeredolu ni o da oun loju pe aarẹ yoo tẹti gbọ ero ati ẹhonu awọn gomina ẹkun ilẹ Yoruba naa.
O ni Aarẹ Buhari ko fi igba kankan tako agbekalẹ ikọ alaabo Amọtẹkun, ṣugbọn ariwo tawọn kan pa lẹyin ọrọ ti amofin agba Abubakar Malami sọ lomu ko tara kiji pe bawo lo ṣe jẹ.














