Saraki Ile Arugbo: Ipò àpọ́nlé ni mo fi Gómìnà Abdulrahman sí ṣugbọn kò hùwa àpọ́nlé

Aworan Gbemi Saraki ati Gomina Kwara

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK/GBEMI SARAKI/ABDULRAHAMAN ABDULRAZAQ

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Sẹnẹtọ Gbemisola Saraki ti tutọ soke foju gba a lori bi ijọba ipinlẹ Kwara ṣe wo ile Arugbo eleyi ti Baba rẹ Dokita Olusola Saraki kọ nigba aye rẹ.

Ninu atẹjade kan ti o fi sita loju opo ayelujara, Saraki ni iwa aibọwọ fun eeyan ni ijọba hu pẹlu bi wọn ti ṣe ko awọn agbofinro lọ gba ilẹ naa lagidi.

O ṣalaye pe oun ko ba ma sọrọ lori iṣẹlẹ yii ki o ma baa dabi ẹni pe oun n wọ iya ija pẹlu Gomina ṣugbọn bi awọn agbofinro ṣe fi agidi gba ilẹ naa lo mu oun wa sọrọ.

Gbemi Saraki ni toun ti pe oun jẹ ọmọ ẹgbẹ APC nipinlẹ Kwara ti oun si gba awọn miran wọ inu ẹgbẹ tọwọ tẹsẹ to fi mọ Gomina Abdulrazaq o yẹ ki Gomina bun oun gbọ ki wọn to yabo ile Arugbo.

''Oju ẹgbọn ni mo fi n wo Gomina Abdulrazaq ti a si ti mọra tipe. Mi o si fi igba kan ma ṣe apọnle fun un ṣugbọn ko fi ọwọ mi wọ mi ''

Gbemi Saraki ti o jẹ Minisita abẹle feto irina lorileede Naijiria labẹ ẹgbẹ oṣelu APC bẹnu atẹ lu bi awọn agbofinro ti ṣe yabo ile Arugbo laago mẹta oru ti wọn si yin afẹfẹ tajutaju lu awọn iya arugbo nibẹ.

O wa kesi ọga ọlọpaa patapata lati fa Kọmisan ọlọpaa leti pe ki o ti ọwọ ọmọ rẹ baṣọ ki o si ma jẹ ki awọnm oloṣelu lo lati tẹ ifẹ inu wọn.

Saraki pari ọrọ rẹ pe ki awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ma ṣe fa wahala koda bi wọn ba n ti ika bọ wọn lẹnu.

Ninu atẹjade ti Gbemi Saraki fi sita yi,ko sọ boya Baba oun niiwe aṣẹ lori ilẹ naa tabi boya mọlẹbi yoo gbe ijọba lọ ile ẹjọ

Àkọlé fídíò, Ṣé ẹ ti rí kí èèyàn ní àwọ̀ ara tó ń ṣí bíi ìpẹ́pẹ́ ẹja rí?