Yemi Ayebo, Yemi My Lover: Ìdí rèé tí orin kíkọ fi máa ń pò nínú sinimá mi...

Bi ẹ ba jẹ ẹni to n fi ọkan ba ere sinima lorileede Naijiria bọ daadaa, kete ti wọn ba ti darukọ Yemi My Lover, ko ni ṣe yin ni kayeefi.
Gbajugbaja elere sinima yii, Yemi Ayebo ni BBC Yoruba gba lalejo lori eto wa loju opo Facebook.
Ninu ifọrọwero naa ti pupọ awọn ololufẹ rẹ ti darapọ mọ wa Yemi My Lover tu kẹkẹ ọrọ silẹ nipa awọn nkankan.
- Ọ̀rọ̀ Japa dé Ekiti; 'Iléeṣẹ́ tó ní àwọn fẹ́ ran wá lọ́wọ́ lọ ìlú Òyìnbó ti -scam' wa, àìsàn déé!
- Bàbá mi Alafin Oyo fẹ́ràn ipa tí mo kó nínú Sinimá Anikulapo, wọ́n sì fẹ́ wò ó àmọ́... - Adedoja Alaafin
- Ṣé lóòtọ́- Bóo bá ń mu Garri jù tí wọ́n tàn ẹ́ pé ojú dídùn ni yóò gbẹ̀yìn rẹ; gbọ́ òótọ́ lẹ́nu onímọ̀
- Ilé ẹjọ́ rán igbákejì Ààrẹ Argentina lẹ́wọ̀n ọdún mẹ́fà lórí ẹ̀sùn àjẹbánu
- Odunlade àti Femi Adebayọ: Wo ohun tó yà wá sọ́tọ̀ nínú àwọn arẹwà ọkùnrin
- Ijó tí mo jó níwájú Ooni Ife ti ayé ń pariwo ẹ̀ kiri, N250,000 ni mo fi pa– Nkechi Blessing Sunday
Lara ohun to sọ fawọn ololufẹ rẹ ni ipa to ko ninu ere sinima Naijiria paapaa julọ nipa ṣiṣe atọna fawọn elere sinima to ti wa gun oke agba loni.
O sọ pe Afees Ọwọ ti o wa di ilumọọka loni jẹ ọkan lara awọn to kọṣẹ sinima lọdọ ohun.
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post
Koda o ni orukọ inagijẹ rẹ''Ọwọ'' to n jẹ ''emi ni mo fun un.''

Sinima nipa igbe aye Yemi My Lover n bọ
Ọmọ bibi ikarẹ ni Ilu Ondo,Yemi Ayebo wa lara awọn to kọkọ tan irawọ ere sinima agbelewo lede Yoruba pèlu awọn sinima bi Yemi My Lover, Joke Onibudo ati Ọdẹ Aperin.
Nigba ti BBC Yoruba beere lọwọ rẹ boya o ṣi n ṣe ere sinima,Yemi Ayebọ sọ pe ''oun ko fi igba kan fi sinima lọrun silẹ'

Oríṣun àwòrán, Yemi Ajebo
''Ninu igbagbọ temi,ki eeyan ma han ninu sinima ni gbogbo igba ko tumọ si pe ere to n gbe jade ni ẹkọ tawn eeyan le kọ''
O tẹsiwaju pe ''bi eniyan ba ni sinima kan laarin ọdun mẹta awọn eeyan ko ni gbagbe rẹ''

O tun ṣalaye idi ti orin fi maa n pọ ninu awọn ere sinima rẹ nipe oun feran orin kiko gan an ni.
''Ẹni ti o ba ṣe fiimu ti ko fi orin sinu rẹ, ko ti ṣisẹ ere sinima.
Eyi ni ẹkọ taa kọ lati ọdọ Ade Love ati Hubert Ogunde''
O ni sọ nipa pataki orin kikọ ninu aṣa ati igbelarugẹ ede Yoruba
- CBN kéde gbèdéke 100,000 owo tí o le gbà ní ATM, POS àti bánkì lọ́sẹ̀
- Ọwọ́ tẹ afurasí méjì tó lá inú aláboyún, tó tún jí ọmọ inú rẹ̀ gbé lọ
- World AIDS Day- Ọmọ Nàìjíríà 1.8m ló ń gbé pẹ̀lú ààrùn HIV
- Mo ra epo bẹntiró ní N250, N300 ní ilé epo nítorí ọ̀wọ́ngógó bẹ́ntiró - Aráàlú fárígá!
- Ọwọ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun tẹ ọmọ ‘Yahoo’ tó lu ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ pa nítorí owó ‘maga’
- Wo àwọn òṣìṣẹ̀ ìjọba tó ń gba owó ju ààrẹ lọ lórílẹ̀èdè Nàìjíríà












