Ijó tí mo jó níwájú Ooni Ife ti ayé ń pariwo ẹ̀ kiri, N250,000 ni mo fi pa– Nkechi Blessing Sunday

Nkechi Blessing nibi to ti n jo niwaju Ooni

Oríṣun àwòrán, Nkechi Blessing/Instagram

Gbajumọ osere tiata, Nkechi Blessing Sunday ti bu ẹnu atẹ lu awọn to n sọrọ odi nipa rẹ lẹyin ti fidio kan lu ayelujara pa nibi to ti n jo ruku idi fun Ọọni Ile Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi Ọjaja keji.

Nigba to n sọrọ lori oju opo ayelujara instagram rẹ gbajumọ osere Nkechi Blessing Sunday ni ohun to ba wu ẹlẹnu ni ko maa fi ẹnu rẹ sọ o

Ohun ti pa ẹgbẹrun lọna ọtalelugba o din mẹwaa naira, (N250, 000) si apo nitoun

“Lori ọrọ idije ijo laarin awọn Onidajọ to waye, ọga mi @fagbotobamidele ti ṣe n ta mi yọ ni mo fi sare sọ pe ki n da a bi ọgbọn,

amọṣa lẹyin o rẹyin mo ṣe ipo keji mo si ẹgbẹrun lọna ọtalelugba o din mẹwaa naira, (N250, 000) si apo lari ọwọ Ooni Adimula Ifẹ.”

Fidio kan gbode kan nibi ti gbajumọ osere naa ti n tadireke niwaju Ọọni lẹyin ọsẹ diẹ ti iroyin gbe e pe o fi ọrọ didarapọ mọ awọn olori laafin Ọọni Ogunwusi ṣe awada loju opo ayelujara rẹ.

Nkechi Blessing Sunday wa lara awọn Onidajọ fun idije arẹwa Queen Moremi pageantry ti Ọọniriṣa gbe kalẹ