Baba mí fí ọwọ́ sí Folarin gẹ́gẹ́ bíi Gómìnà, ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ àwọn méjèèjì- Ọmọ Alao Akala 

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Olamijuwonlo, ọmọ gomina ana nipinlẹ Oyo, Adebayo Alao Akala, ní irọ nla ni Muftau Open Salawu pa lori ibaṣepọ oloogbe ati oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, Teslim Folarin.

Ninu atẹjade to fi tako ọrọ ti Open Salawu sọ nípa ibaṣepọ wọn, Olamijuwonlo ni oun ko nilo lati tako ọrọ to sọ sugbọn ki ẹnikẹni maa lo orúkọ Baba oun fi tan awọn araalu.

O ni ko ba irọnu fun Folarin lati di Gomina lọdun to ba jẹ pe a baba oun wa laye nitori oun ni yoo saaju awọn iponlogo ibo 

"Onimọ ẹrọ Muftau Open Salawu jẹ enikan ti mo mọ daada sugbọn ko si lara awọn ti baba mi maa n ba sọ ọrọ oṣelu, fun idi eyi o ya mi lẹnu ni bi tí wọn gbọ iroyin ti wọn fi sita pe Baba mi ati Folarin n ja.

"To ba jẹ awada ni, kí wọn janu nibẹ. Baba mi fẹran alaafia tí ko si ni erongba burú ru sí gomina Seyi Makinde. Otunba ko le sọ irufẹ ọrọ yẹn síta. Open Salawu sọ ọrọ yẹn fun anfani tiwọn ni.

"Ti a ba sọrọ pe tani oludije tí baba mi ṣumọ, Teslim Folarin ni. Gbogbo àwọn nkan wọnyi lo so okunkun sì Open Salawu. "

Makinde ni Akala ń ṣé àtìlẹyìn fún kó tó kú, kì ì ṣé Folarin rárá- Open Salawu

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Agbaoye ninu ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Oyo, Muftau Open Salawu ni Gomina ana nipinlẹ Oyo, Oloye Adebayo Alao Akala ko ṣe atilẹyin fun oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, Teslim Folarin nigba ti o waye laye.

O ni pe Akala duro sì ẹyin gomina Seyi Makinde tí ẹgbẹ oṣelu PDP.

Salawu sọ eleyi ninu atẹjade to fi ransẹ si awọn akọroyin lọjọ Aiku ọsẹ yii.

O ní Akala ko fọwọ si erongba Teslim Folarin lati di Gomina Ipinlẹ Oyo labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC.

O ni oun beere lọwọ gomina ana naa pe tani o fẹ ko di gomina lọdun 2023, to si sọ fun un pe ko ki n ṣe Teslim Folarin lo oun fẹ ko di gomina ipinlẹ Oyo.

Aworan

Oríṣun àwòrán, @Others

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Salawu tẹsiwaju pe Seyi Makinde lẹtọ sì saa kejì gẹgẹ bii gomina ati pe tí gomina Alao Akala ba wa laye, yoo ṣe atilẹyin fun Makinde lati di Gomina fun saa kejì.

"Eto ìdibo lọdun 2023 yoo wa pẹlu ọpọlọpọ oun iyalẹnu fun awọn ẹgbẹ oṣelu.

Paapaa julo ninu ẹgbẹ oṣelu APC nítorí ni bẹrẹ oṣesẹ kí Aarẹ Muhammadu Buhari ni erongba to da ni bẹrẹ sugbọn wọn sọ gbogbo ẹnu nigba to yaa.

"Gomina Seyi Makinde lẹtọ sì saa keji lati fi tẹsiwaju gbogbo àwọn ohun meremere to tí gbe ṣe nipinlẹ yii.

Ninu gbogbo awọn to n díje dupo gomina nipinlẹ Oyo, Makinde nìkan lo ni oye to peye lati ti fi tukọ ipinlẹ Oyo.

"Ti Akala ba wa laye ni, ó han gbangba pe yoo ṣe atilẹyin fun Makinde fun saa kejì. Ibaṣepọ gigi wa laarin gomina Seyi Makinde àti Gomina ana Alao Akala.

"Titi to fi jade laye, Akala ko to si ẹyin Folarin lati di Gomina Ipinlẹ Oyo.

Mo bẹrẹ lọwọ gomina ana nigba to wa laye pe tani yoo ṣe atilẹyin fun ninu idibo gomina lọdun 2023, o ni ko ki n ṣe Teslim Folarin rara."