Ogun Politics: Ṣẹ́ lóòótọ́ ni Rufai n gba ẹgbẹ̀rún lọnà àádọta dọ́là lọ́wọ́ ìjọba ìpínlẹ̀ Ògùn?

Dapo Abiodun ati Rufai

Oríṣun àwòrán, @Others

Gomina Dapo Abiodun ti sọró lori ohun to jade lori ayelujara pe amugbalẹgbẹ rẹ n gba owo o kare lọwọ ijọba ipinlẹ naa.

Gomina Dapọ Abiọdun ti ipinlẹ Ogun ti sọ pe ko si otitọ kankan ninu iroyin to jade sita lori ikanni ayelujara laipẹ yii wi pe oun n san ẹgbẹrun lọna aadọta owo dọla fun amugbalẹgbẹẹ rẹ tẹlẹ, Bidemi Rufai lori bo ṣe ko awọn oludasilẹ ileeṣẹ wọle s'ipinlẹ naa.

Abiọdun sọ ọrọ naa lonii, ọjọ Aiku, Sannde ninu atẹjade ti akọwe iroyin gomina, Kunle Ṣomọrin gbe jade, eyi to fi ranṣẹ si BBC Yoruba.

Àkọlé fídíò, Sikirulai Ogundele, alága PDP Ogun: ibi tí ọ̀rs dé dúró lórí olùdíje gomina PDP Ogun rèé

O ni Rufai, ẹni ti wọn fi ẹsun jibiti kan nilẹ Amẹrika ko figba kankan mu ileeṣẹ kankan wọle s'ipinlẹ Ogun laaarin akoko to fi wa pẹlu ijọba oun.

Laipẹ yii ni iwe iroyin ori ayelujara kan gbe iroyin jade wi pe Bidemi Rufai n gba ẹgbẹrun lọna aadọta dọla lọwọ ijọba Ogun lori ileeṣẹ kọọkan to mu wọle lati ilẹ Amẹrika.

Nigba to n sọrọ, Gomina Abiọdun sọ pe iroyin ẹlẹjẹ to jinna si otitọ ọrọ patapata ni iwe iroyin naa jade lọjọ Satide, Abamẹta to kọja.

Bakan naa iroyin ni ṣaaju akoko ti Gomina Abiọdun yan Bidemi Rufai gẹgẹ bi amugbalẹgbẹẹ pataki lori ọrọ ile kikọ, awọn mejeeji ko ni ibaṣepọ kankan, bi ko ṣe pe awọn eeyan lo fa a silẹ fun ipo ti wọn yan an fun.

"Gẹgẹ bii awọn alabaṣiṣẹpọ yooku fun gomina, awọn eeyan lati wọọdu ni wọn fa Rufai kalẹ fun gomina, kii ṣe nipa iranlọwọ to ṣe lakoko ipolongo idibo lọdun 2019."

Àkọlé fídíò, Festus Keyamo: E fìka rẹ́ mi nímú tí Tinubu bá ṣe ìkà fún Kristeni ní 2027

"Wọn yan Bidemi Rufai gẹgẹ bii amugbalẹgbẹẹ agba fun gomina lori ọrọ ile kikọ, ati pe oṣu mẹta ṣaaju asiko ti ọwọ tẹ ẹ ni wọn fi orukọ rẹ ranṣẹ.

"Ko tii bẹrẹ iṣẹ labẹ ofin, bẹẹ si ni ko nii bẹrẹ sii jokoo si ọfiisi. Ko si lara awọn igbimọ to n mojuto eto ọrọ aje, ko si tii ni ipa to n ko ninu eto ijọba.

Yiyan ti wọn yan niiṣe pẹlu ipa to ti ko ni wọọdu ẹ. Ko tii jokoo ri laaarin ipade igbimọ amuṣẹṣe, State Executive Council, ko si ni ipa kankan to ti ko ninu eyo ati ilana ijọba.

"Gomina ko ni ibaṣepọ kankan pẹlu Rufai, bẹẹ ni okoowo kankan ko da wọn pọ ri. Ko mu nnkankan wa. Wọn le lọ ṣe agbeyẹwo rẹ ni papakọ ofurufu tilẹ Amẹrika."

Àkọlé fídíò, WORLD AIDS DAY 2018: HIV/ AIDS kìí ṣe ìdájọ́ ikú mọ́

O wa tun fi kun ọrọ rẹ wi pe gẹgẹ Gomina Abiọdun to jẹ ẹnikan to n bọwọ fun ofin, o da iyansipo Rufai duro lai fi akoko ṣofo, ni kete ti ijọba ilẹ Amẹrika mu fun ẹsun jibiti, koda, ṣaaju bi wọn ṣe juu sẹwọn.

Bẹẹ lo tẹsiwaju pe asiko oṣelu la wa yii, eyi ti awọn alatako ri gẹgẹ bi anfaani lati tako ijọba, eyi to lo ṣe dandan lati tete sọrọ sita tako ayederu iroyin ko to pẹ ju.