Ìdásílẹ̀ ìpínlẹ̀ Ijebu ni àwa ń fẹ́, Yorùbá Nation kò ì tíì kàn wá - Ọba Adenugba

Àkọlé fídíò, À ń fẹ́ àtìlẹyìn àwọn ọmọ Yorùbá láti rí ìpínlẹ̀ gbà
Ìdásílẹ̀ ìpínlẹ̀ Ijebu ni àwa ń fẹ́, Yorùbá Nation kò ì tíì kàn wá - Ọba Adenugba

Yorùbá bọ̀ wọ́n ní ohun tó bá ń dun ni ló ń pọ̀ lọ́rọ̀ ẹni, ìyá ń ronú ọmọ rẹ̀ ń rokà.

Ebumawe tí ìlú Ago Iwoye, Ọba Adulrasaq Adenugba bá BBC Yorùbá sọ̀rọ̀ lórí ohun tí ó ń dùn wọ́n lọ́kàn lórí bí àpapọ̀ Ijebu kò ì tíì dá ní ìpínlẹ̀.

Ọba Adenugba ní bí àpapọ̀ Ijebu yóò ṣe di ìpínlẹ̀ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni àwọn ń wá, wí pé pípè fún ìdásílẹ̀ Yorùbá nation kò ì tíì kàn àwọn.

“Àwọn ìlú kan ti di ìpínlẹ̀ mẹ́ta ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ṣùgbọ́n àwa kò ì tíì ní nǹkankan, ohun tí àwa náà ń fẹ́ ni bí àpapọ̀ Ijebu náà ṣe máa rí ìpínlẹ̀ gbà ló jẹ́ èmi lógún.”

“À ń fẹ́ àtìlẹyìn àwọn ọmọ Yorùbá láti rí ìpínlẹ̀ gbà nígbà náà ni a ó máa wá sọ̀rọ̀ nípa Yorùbá nation.”

Ìjọba nílò láti pèsè iṣẹ́ kí ìpèníjà ètò ààbò le dínkù

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ètò ààbò, Ọba alayé náà ní ó jẹ́ ohun tó ń kọ èèyàn lóminú wí pé ètò ààbò mẹ́hẹ gidi gan ní orílẹ̀ èdè yìí àmọ́ tó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ipá ni àwọn ń sà láti pèsè àyíká àláfíà fún àwọn ará ìlú.

“A ò lè máa sọ àwọn ìgbésẹ̀ tí à ń gbé láti mú kí àláfíà jọba ní agbègbè wa síta àmọ́ àwọn tí ẹ bá mọ ohun tí àwọn mìíràn ń ṣe láti pèsè ààbò àmọ́ omi pọ̀ ju ọkà lọ.”

Ọba Adenugba rọ ìjọba láti pèsè iṣẹ́ fún àwọn ọ̀dọ́ pé tí wọ́n bá ń rí ibi gbà lọ ìwà ọ̀daràn yóò dínkù ní àárín ìlú.

Ọba kìí ṣe òṣèlú, gbogbo àwọn ọmọ ìlú ni tọba

 Bí ètò ìdìbò ọdún 2023 ṣe ń súnmọ́ etílé ni ọba náà tún rọ àwọn olóṣèlú láti má ṣe òṣèlú bó o ba o pá bá ò ba o bù ú lẹ́sẹ̀.

Ó ní ohun tí oníkálùkù bá fẹ́ ṣe fún ìlú ni kí wọ́n fi polongo ara wọn fún àwọn ọmọ Nàìjíríà dípò dída omi àláfíà ìlú rú.

Bákan náà ló ní gbogbo tí kò bá yẹ láti fi sínú ọ̀rọ̀ òṣèlú kí wọ́n jìnà si nítorí ọjọ́ iwájú.

Ó fi kun pé kí àwọn olóṣèlú ṣọ́ra pẹ̀lú àwọn ẹ̀jẹ́ àti àwọn ìlérí tí wọ́n ń ṣe lásìkò nítorí bí wọ́n bá padà dépò, àbùkù ló máa kó báwọn bí wọn kò bá fi lè mú ìlérí wọn ṣẹ.